Bola Tinubu: Mo dúpẹ́ pé mo padà délé láyọ̀

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu
Asaaju ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Tinubu ti n dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o da oun pada si orilẹede Naijiria ni alaafia.
Tinubu, ẹni to ti kuro lorilẹede yii lati osu mẹta sẹyin lati lọ se isẹ abẹ nilu London lo n dupẹ bẹẹ nile ijọba ni Marina nibi apejẹ ikinni kaabọ ti ijọba ipinlẹ Eko se fun.
Tinubu ni "Ori mi wu amọ inu mi dun pe mo pada sile. Ọlọrun lo n fun ni ni iye, oun naa si lo le gba a.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Buhari, ìwé òfin 1999 ni ìparun Naijiria, tètè fà á ya - Tunde Bakare
- Gómìnà Yoruba, ẹ dúró lé ìjọba àpapọ̀ lọ́rùn pé kó fi Sunday Igboho sílẹ̀ - Gani Adams
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara dá ọ̀gá ilé Keu tí wọ́n ti lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí i bàrà dúró
- Ìdí rèé tí mo fi gbà kí ọkọ mi má a ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìyá àti àbúrò mi
- Ohun tí ojú mi rí rèé lọ́wọ́ àwọn amojúẹ̀rọ lásíkò yíya sinimá - Adunni Ade
- "Ó ṣeéṣe ká ta gáàsì 12.5kg ní ₦10,000 kó tó di December ọdún yìí"
- Wo ìtàn ayé Sunday Igboho, gbajúmọ̀ ajìjàgbara fún ilẹ̀ Yorùbá
- Ìgbagbọ́ mi nínú Nàíjíríà kò yinjẹ, ìrètí mi nípa ọjọ́ ọ́la wa sì le koko - Obasanjo
- N kò lẹ́bọ lẹ́rù lórí ilé Tinubu ní London tí ìwé Pandora gbé jáde pé mo ba rà á - Oyetola
Ọlọrun nikan lo le gba ẹmi mi tabi fun mi ni iye, ara mi si ti le koko pada, mo si dupẹ pe mo pada sile pẹlu alaafia pipe.
Tinubu wa dupẹ lọwọ awọn eeyan to seto ikinni kaabọ naa fun to si gbadura fun wọn pe Ọlọrun yoo dahun gbogbo ohun to n wu wọn lọkan.

'Bola Tinubu ńbọ̀ ní Nàìjíríà láìpẹ́, àmọ́ kò tíì dé'

Oríṣun àwòrán, other
Bola Tinubu ko tii kuro lorilẹede Gẹẹsi nibi to wa to ti n fun ara ni isinmi.
Ọrọ yii ni agbẹnusọ rẹ, Tunde Rahman fi dahun ibeere ti BBC News Yoruba taare sii lori aworan ati fidio to n ja rainrain lori ayelujara pe eekan ẹgbẹ oṣelu APC naa ti wa sile tabi gbera lọ si orilẹede miran fun iwosan.
Ọgbẹni Tunde Rahman ni laipẹ laijina ni Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu yoo de si Naijiria ṣugbọn lọwọ yii Jagaban ko tii pada si Naijiria.
- 'Eniola Badmus wọ pátá lọ sí ààfin Oba Elegushi, "ọ̀ín" kí ló burú níbẹ̀?'
- Agbẹjọ́rò méjì yọ ẹ̀sẹ́ síra wọn níwájú adájọ ó ku ẹni tí yóò yanjú ọ̀rọ̀
- Ǹjẹ́ Bobrisky àti Mompha ń gbée síi fúnra wọn lóòtọ́? Ohun táa mọ̀ nìyí
- Ẹ̀rù ò b'odò! Mo ṣetán láti dojú ìjà kọ Tyson Fury báyìí- Anthony Joshua
- Ọbẹ̀ sọ̀ọ̀! Mọ síi nípa ìwé ìrìnà Visa f'áwọn awakọ̀ tírélà àti òṣìṣẹ́ ilé adìyẹ tí UK ń gbèrò
"Aworan fidio ti wọn n gbe kiri yẹn kii ṣe tii isinyi o. Ti igba pipẹ sẹyin ni ti a n lọ si orilẹede Saudi Arabia ni oṣeeṣe ko jẹ".
O fi kun un pe ariwo ti awọn eeyan n pa nipa ilera Aṣiwaju Bọla Tinubu ko n ṣe ara rẹ nitori pe ohun kan ṣoṣo to ṣee naa ni ipenija orokun rẹ; orokun yii lo si lọ ṣe iṣẹ abẹ le lori lẹyin eyi ko si nnkankan to ṣee.
Akoko iwosan iṣẹ abẹ naa lo n la kọja, to si ti gbadun bayii.
"Fun bii nnkan bi ọsẹ mẹrin si marun sẹyin ko lo igi gan lati fi rin mọ."

Oríṣun àwòrán, other
Sẹnetọ ana, Shehu Sani wa lara awọn eekan to gbe iroyin naa si ori ikanni ayelujara wọn pe agba oṣelu naa ti pada to si kii ku oriire araya.
O ti le ni nnkan bii oṣu meji bayii ti Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti fi orilẹede Naijiria silẹ fun itọju ara rẹ loke okun.
Lati igba yii wa si ni ọpọlọpọ awọn oloṣelu ninu eyi ti ko yọ aarẹ orilẹede Naijiria, Mohammadu Buhari gan silẹ atawọn gomina kaakiri orilẹede Naijiria pẹlu to rinrinajo lọ oke oku si lọ n bẹẹ wo.


















