Pandora Papers: Oyetola ní òun kọ́ ló bá Tinubu ra ile Diezani tó wà ní London

Buhari ati Tinubu ni London

Oríṣun àwòrán, Nigerian Government

Orin ọwọ mi ma re funfun nẹnẹ ni Gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola n kọ lori iroyin to gbode pe o wa lara awọn ti wọn fẹsun kan ninu iwe Pandora Papers to jade.

Ninu iwe yii lawọn akọroyin oniwadii ijinlẹ ti tu aṣiri ọna alumọkọrọyi tawọn olori ijọba ati awọn mii fi n ko owo ati ọrọ ilu pamọ lọna aitọ.

Eyi to kan Oyetola ni pe wọn lo ileeṣẹ rẹ kan lati fi ra ile ti ijọba Naijiria fẹ gbẹsẹ le lara dukia Minisita fepo rọbi Naijiria tẹlẹ Diezani Madueke.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ile ta n wi yii ni agba ọjẹ oṣelu ẹgbẹ APC, Bola Ahmed Tinubu ti n gba alejo awọn eeyan, to fi mọ aarẹ Buhari nilu London.

Ninu atẹjade kan to fi sita lati ọwọ agbẹnusọ rẹ, Ismail Omipidan, Oyetola ni oun ko ṣe aburu kankan tabi ra dukia lorukọ ileeṣẹ kan, ti wọn n pe orukọ rẹ ni Aranda Overseas Corporation.

Tinubu n jade sita ninu mọto niwaju ile rẹ ni London

Oríṣun àwòrán, NAtional Assembly

''A ti ri awọn iroyin to jade lẹnu ọjọ mẹta yii lori iwe Pandora to jade eyi to mu ki a fẹ sọ oju abẹ niko''

O ṣe lalaye pe, lọdun 2011 ti oun lọ darapọ mọ oṣelu loun ti fi ipo oludari ileeṣẹ naa silẹ to fi mọ ipin idokowo ti oun ni ninu rẹ.

Omipidan ni ''Oyetola ko ni nkankan ṣe pẹlu ile ti wọn ni o ra yii tabi arakunrin Aluko to ni debi pe yoo tiẹ ni ajọṣepọ kankan pẹlu rẹ''

''Lati 2011 titi di wakati yii ti Oyetola ti n ba ijọba ṣiṣẹ gẹgẹ bi olori oṣiṣẹ ijọba ni o ti lajọṣepọ pẹlu ileeṣẹ Global Investment Offshore, ko si le ra ile taa n wi yi tabi ko ni ki eeyan ba oun ra gẹgẹ bi ẹsun ti wọn fi kan an''

Omipidan tẹsiwaju pe Ọlọrun to gbe awọn de ibi tawọn de yii, ko ni da awọn da bukata awọn.

Ile ti ọrọ da lori yii ni iwe Pandora tọka si pe agba ọjẹ oloṣelu ẹgbẹ APC nni, Bola Ahmed Tinubu ra lọwọ Aluko, tii se alabaṣe minisita feto ọrọ epo rọbi tẹlẹ, Diezani Madueke.

Atẹjade ti Oyetola fisita

Oríṣun àwòrán, Ismail Omipidan Facebook