Yoruba VOR: A kò fẹ́ ìwé òfin ọdún 1999 mọ́, òhun ló fi àwọn èèyàn wa sínú ìṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Ilana Omo Oodua Worldwide TV
Ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba kan, Voice of Reason Advocacy for Social Development Foundation, VOR, ti bẹrẹ itaniji lawọn igberiko lọna ati mu ki awọn ọmọ Yoruba ṣatilẹyin fun bi ijọba apapọ yoo ṣe pa iwe ofin ọdun 1999 ti, ti yoo si pe fun idibo lati mọ ero araalu lori ọjọ ọla Naijiria.
Lara awọn eeyan jankan to wa ninu ẹgbẹ naa ni awọn ọmọwe, awọn agbagba, onimọ eto ilera, onimọ nipa eto iṣiro, awọn akọroyin, awọn onimọ ẹrọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ẹgbẹ naa ni afojusun awọn ni lati jẹ ki araalu mọ ewu to wa ninu ofin ọdun 1999 naa, ati pe iwe ofin ọhun lo fa bi idagbasoke ṣe ku diẹ kaato nilẹ kaarọ oojire.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ìtàn ayé Sunday Igboho, gbajúmọ̀ ajìjàgbara fún ilẹ̀ Yorùbá
- Àwàdà lásán ní Adeleke ṣe nípa ọ̀rọ̀ bàálù, kò sí òótọ́ níbẹ̀ - Ooni Ife
- Wàládè dé! Àwọn obìnrin aṣaralóge wọ gàù ikọ̀ Taliban ní Afghanistan
- Ojú òpó MTN dẹnukọlẹ̀ ní Nigeria, àwọn oníbàárà fárígá
- Nkan mẹ́sàn-án tí o le ṣe láti dènà ìkú ọmọ tuntun
- Okùnrin yìí ra àpò ìrẹsì mẹjì, ó fi ọmọ méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi owó
- Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ń se ọbẹ̀ tó máa ń fún wọn ní ìbejì ní Igbo-Ora
Lara awọn ọna lati jẹ ki awọn eeyan mọ afojusun wọn, ẹgbẹ naa ti bẹrẹ ipolongo lawọn ori redio kan niluu Ibadan.
Ninu atẹjade ti aṣoju ẹgbẹ ọhun, Dokita Seyi Roberts fi lede, o ni ẹgbẹ naa ti fi ara wọn jin lati ri daju pe awọn eeyan ilu mọ bo ṣe n lọ ninu igbiyanju awọn lati gba ẹtọ ilẹ Yoruba pada.
O ni "A oo bẹrẹ pẹlu fifa iwe ofin magomago ti ọdun 1999 ti awọn ologun gbe le wa lọwọ ya, eyii to fi awọn eeyan wa sinu oṣi, iya ati iyanjẹ."
Yatọ si awọn ipolongo ori redio ti wọn n ṣe, VOR tun sọ pe awọn ti ri awọn patako ajuwe si awọn agbegbe kan to ṣe pataki niluu Ibadan, eyii ti wọn fi n ke si awọn araau lati ṣagbatẹru bi wọn yoo ṣe fa iwe ofin naa ya.
Ọkan lara awọn patako ajuwe naa ni wọn ri mọ opopona Eko si Ibadan lagbegbe Guru Maraji.
Bẹẹ naa ni wọn ri awọn mii si ọna Iwo Road niwaju ile ẹkọ giga Premier University niluu Ibadan yii kan naa.
Ẹwẹ, VOR kọ ni ẹgbẹ akọkọ ti yoo sọ pe ayederu ni iwe ofin ọdun 1999, ti wọn si sọ pe ki ijọba fa iwe ofin naa ya ko si pe ipade apero laarin awọn ẹya ni Naijiria tabi ki olukuluku maa lọ nilọ tirẹ.

















