Yoruba Nation: Ẹgbẹ́ Ajìjàgbara lérí-léka fún Buhari tó bá fi gbé Banji Akitoye

Oríṣun àwòrán, Akintoye
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ajìjàgbara Yorùba jákèjádò tí pe ààrẹ Muhammadu Buhari níja láti mú àwọn Fulani darandaran to n dàlú rú náá.
Ẹgbẹ́ kan nilẹ Yoruba tó n pètè láti gba òmìnira ara wọn (Yoruba Self Determination Group) lo gba aarẹ Buhari nimọran bẹẹ, to si tun sekìlọ̀ pe ko dẹ̀yìn lórí ìpinu rẹ̀ láti mú ọjọ̀gbọ́n Banji Akintoye, to n ṣagbátẹ̀ru awọn ajìjàgbara Yorùbá.
Wọ́n ni ti ààrẹ bá dán èyí wò, yóò túbọ̀ da omi àlááfìa Nàìjíríà, tí kò tòrò tẹ́lẹ̀, rú ni.
- Buhari kò jẹ́ kí Yoruba àtàwọn ẹ̀yà míràn gbérí ní Naijiria - Ẹgbẹ́ Yoruba VOR
- To bá fẹ́ dara pọ̀ mọ́ Yoruba Nation, ìgbésẹ́ tó gbé rèé - Ilana Oodua
- A gbọ́dọ̀ fi àwọn olùwọ́de Yorùbá Nation sí àhámọ́ fún ọjọ́ 21, bí bẹ́ẹ̀ kọ́.....- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko
- Mọ̀ si nípa agbẹjọ́rò Yoruba Nation tó gbé Buhari lọ sílé ẹjọ́ àgbáyé ICC
- "Sunday Igboho, Banji Akitoye, ẹ rìn jìnnà sójú pópó Eko fún ìwọ́de Yoruba Nation"
- Ẹ̀rú Fulani ni Aregbesola, ara sì ló ń ta á torí àṣeyọrí ìjìjàgbara Yoruba nation - Ilana Omo Oodua
Ìròyìn tí n tàn kálẹ̀ pé ìjọba àpapọ̀ ń gbìyànjú láti fi ọwọ́ ofin mú Akintoye fún ipa tí ò ń kó nínú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ Yorùbá tó n pinu láti dá dúró.
Nínú àtẹ̀jáde tí akọ̀wé gbogboogbo ẹgbẹ́ náà fi sita láti ọwọ́ Dókíta Steven Abioye, ló ti ṣàlàyé pé mímú Akintoye yóò túbọ̀ mú wàhálà bá orilẹ̀-èdè yìí si ni.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ṣe sọ, kí ní nǹkan tó n bá Buhari lẹ́rù gan? Kí ni ko fii lọ́kàn balẹ̀, ààrẹ Buhari naa lo sọ pé àwọn tó n sọ̀rọ̀ nípa àtúntò Nàìjíríà kò mọ nǹkan ti wọ́n ń sọ"
" Òótọ́ ọ̀rọ̀ tọ wà níbẹ̀ ní pe o kò le maa ṣe ìjọba apapọ lọ́nà tó jẹ́ pé àwọn ìhà àti ẹ̀yà tí kò ní nǹkan kan, ti wọ́n fi ń ran orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ ni yóò wá maa jọ̀bá lórí àwọn tó kù tí wọ́n ń ṣe làálàá, àwọn ẹ̀yà tí ìjọba ń fìyà jẹ kò lé dúrò bẹ́ẹ̀ láì."
" Nítorí náà Buhari àti àwọn ìsọ̀mọ̀gbè rẹ̀ le máa lo ògbójú nínú mímú ọ̀rọ̀ àwọn tó n pè fún ìyàpa ẹ̀yà wọn sùgbọ́n kí o ri dájú pé òun kò dákún wàhálà tó wà nílẹ̀."
Abioye fi kun pé ti ìjọba tẹ̀síwájú láti máa mú àwọn tó n pè fún orílẹ̀-èdè túntun, àwọn ènìyàn mííran bí Igboho, Akintoye, Dokubo yóò tun dìdè nítorí ọ̀rọ̀ yìí.
" Ṣe ìjọba àpapọ̀ ti mú olórí àwọn Fulani daranran tó n pa àwọn ènìyàn tí wọ́n sì ti ràn ọ̀pọ̀ lọ sí sàáré láì tọ́jọ́, síbẹ̀ wọ́n ń lé àwọn to fẹ́ gba ara wọn sílẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ náà ṣe sọ " Bi wọ́n bá ṣe ń tẹ̀síwáju nínú ìwà náà lati maa mú àwọn ajìjàgbara, bẹ́ẹ̀ ni orílẹ̀-èdè yóò se má a dójúbolẹ̀.
"Bí ìjọba bá gbìyàjú láti mú ọ̀jọ̀gbọ́n Akintoye, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba ń mú kí ìjìjàgbara di ìlúmọ̀ọ̀ká si ni.



















