Yoruba Nation: Ilana Omo Oodua ní pàbó ní aáyan Aregbesola láti tako ìyapa Nàíjíríà yóò já sí

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1/nstagram
Awọn ọmọ ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, to jẹ ọkan pataki lara awọn ẹgbẹ to n pe fun iyapa ilẹ Yoruba kuro lara orilẹ-ede Naijiria ti fun minisita fun ọrọ abẹle, ọgbẹni Rauf Aregbesola lesi, lẹyin to sọrọ abuku saaju si awọn ọmọ ẹgbẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ẹgbẹ ọhun, Maxwell Adeleye buwọlu, wọn ni Aregbesola kii ṣe ọmọluabi, lo jẹ ko ri adari ẹgbẹ naa fin, iyẹn Ọjọgbọn Banji Akintoye.
Atẹjade naa ni "Awa ọmọ ẹgbẹ Ilana Omo Oodua labẹ akoso Ọjọgbọn Banji Akintoye fẹ sọ ni gbangba pe, Aregbesola kii ṣe ọmọlubai lo jẹ ko gboju-gboya lati pe ẹgbẹ baba rẹ ni omugọ."
- Sunday Igboho ní December lòpin ìrìn àrè, Yorùbá ń lọ kúrò ní Nàíjíríà
- Ó ń rúgbó bọ̀ o! Àwọn ajìjàngbara Yorùbá Nation fipá ṣí bọ́dà Idiroko, àmọ́...
- Ẹ̀yin ọdọ́, ẹ sọ́ra fún ìtànjẹ láti darapọ̀ mọ́ ìyapa Naijiria - YAF
- Ẹ̀yìn tí ẹ̀ ń pè fún Yoruba Nation, òpè ní yín, ẹ kò ní ìmọ̀- Ladoja
- Sunday Igboho lọ sọ́dọ̀ Guru Maharaji lórí ìdásílẹ̀ Yoruba Nation
- Àwọn olùwọ̀de Yoruba Nation mú afurasí òṣìṣẹ́ DSS níbi ìwọ́de l‘Osogbo
Wọn ni gẹgẹ bii minisitia lori ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ abẹle, o yẹ ki Aregbesola le e bojuto awọn ẹnubode Naijiria, ti awọn atọhunnrinwa darandaran to n da Naijiria laamu, n gba wọle.
Atẹjade ọhun tẹsiwaju pe "Lẹyin wakati diẹ ti Aregbesola dunkoko mọ ẹya Yoruba tan, ni awọn ọdaran daradaran kọlu Igangan, lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo.
Nibẹ lo ni wọn ti gba ọpọ ẹmi, ti wọn si tun ba ọpọ dukia olowo iyebiye jẹ."
"Titi di akoko yii Aregbesola ko tii fi atẹjade kankan sita lati bu ẹnu ẹtẹ lu ikọlu ọhun."
- Gbajúmọ̀ òjíṣẹ́ Ọlọ́run míràn tún jáde láyé tẹ̀lé TB Joshua
- Ẹ wo àwọn Pásítọ̀ jàǹkàn-jànkàn tí ikú wọn tí mí orílẹ̀èdè Naijiria
- Wo ojú táwọn Pásítọ̀ fi wo T.B Joshua nígbà ayé rẹ̀, tó fa awuyewuye
- Ẹ̀mí mẹ́sàn-án tún ṣòfò ní Igangan, agbébọn jo ilè, ọkọ àti ààfin Ọba
- Ìjọba, ẹ bá mi wá ẹni tó pa ọmọ mi jáde - Ẹ̀bí olóògbé gbarata
- Ọmọbakùnrin Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí, Harry àti ìyàwó rẹ̀ bímọ tuntun
Ilana Omo Oodua wa n beere lọwọ minsita naa boya oponu ni gbogbo awọn ogunlọgọ eeyan to n darapọ mọ ijijagbara Yoruba Nation lojojumọ.
Wọn ni "Ṣe nnkan ti Aregbosola n sọ ni pe oponu ni nnkan bii ẹgbẹrun lọna ogoji eeyan to darapọ mọ iwọde wa niluu Ado Ekiti?
Abi awọn ogunlọgọ to darapọ mọ wa nipinlẹ Osun, to jẹ ipinlẹ ti oun funra rẹ ti ṣe ijọba le lori tẹlẹ?"
Atẹjade naa sọ siwaju si pe, olori pipe ni awọn ọmọ Ilana Omo Oodua, ko si omugọ kankan laarin wọn.
Alukoro ẹgbẹ ọhun ni ẹru Fulani ni Aregbesola, ara lo si n ta a nitori itẹsiwaju to n waye ninu ijijagbara ti awọn n ṣe.
Maxwell pari atẹjade ọhun pe, pabo ni gbogbo akitiyan Aregbesola atawọn to n ṣiṣẹ fun yoo ja si lẹyin o rẹyin nitori ipinnu awọn araaalu lo maa n pada ṣẹ ninu ijọba awarawa.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni Aregbesola ti kọkọ ṣapejuwe awọn to n pe fun idasilẹ orilẹ-ede Yoruba ati Biafra, gẹgẹ bii alamọkan ati omugọ eeyan.
O ni idasilẹ awọn orilẹ-ede ti wọn n pe fun, le yọri si ogun abẹle, eyii ti ko ni tan nilẹ fun nnkan bii aadọta ọdun si asiko yii.

Aláìmọ̀kan àti òmùgọ̀ ló ń pè fún ìdásílẹ̀ Yorùbá Nation - Aregbesola

Oríṣun àwòrán, @Gidi_Traffic
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, Minisita feto abẹle ni Naijiria, Rauf Aregbesola ti bẹnu atẹ lu awọn to n beere fun idasilẹ orilẹede Yoruba ati Biafra ni Naijiria.
Aregbesola wa ṣe apejuwe awọn ajijagbara yii gẹgẹ bi ''alaimọkan ati omugọ eeyan''
Minisita fọrọ abẹle naa woye ọrọ yii lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ to waye ni Ijebu-jẹsa.
Aregbesola kilọ pe wahala ti wọn n da silẹ yii le yi gbogbo Naijiria ka, to si le da ogun ti yoo ja fun aadọta ọdun silẹ.
O ni ''ikilọ pataki mi fun ẹyin tẹ wa nibi ni ki ẹ mọ pe, omugọ ati alaimọkan lawọn to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba ati Biafra, ti wọn o si mọ nkan ti ipe naa le bi.
Idi ni pe ọla Naijiria lawọn orileede ilẹ okere n wo, ti wọn fi n gboṣuba fun awa alawọdudu lagbaye.
Boya awọn ajijagbara ko mọ pe bi ogun ba fi bẹ silẹ, aadọta ọdun loni, o le ma pari.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Gbogbo ǹkan tí à ń ṣe láti jà fún ''Yoruba Nation'', ìjà àwọn bàbá wa là ń gbé - Sunday Igboho
- Àgbẹ̀ míì tún fara gbọgbẹ́ ìbọn ní Igangan láti ọwọ́ afurasí darandaran
- Ìjọba ẹ ṣọ́ra! gbígbégilé ojú òpó Twitter tako ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ Naijiria - Gómínà Ṣeyi Makinde
- Ìwádìí tí bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí Olùkọ́ lu akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn án pa
- Ìjọba àpapọ̀ kéde ìjìyà fún àwọn tó ṣì n lo Twitter ní Naijiria
- Mọ̀ si i nípa ìtàn eégún Gelede àti pàtàkì eégún náà sí àwọn obìnrin nílẹ̀ Yoruba
- Wo àwọn nkán tó ṣẹlẹ̀ níbi ìwọ́de Yoruba Nation tó ti wáyé sẹ́yìn
Nitori naa o yẹ ki a fi tọkan tọkan daabo bo isọkan wa, lootọ nkan ko ri bo se yẹ amọ mo lero pe iṣejọba bo ti ṣe yẹ lo tọ ki a maa beere dipo ijagbara ki a tu Naijiria ka''
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Osun naa fi kun ọrọ rẹ pe, awọn ọmọde ati arugbo ni wahala ogun yoo ṣakoba fun ju lọ, nitori naa, o yẹ ki wọn ro ọrọ yii daada ki wọn to maa lulu ogun ati ọtẹ.
O tẹnumọ pe ki ẹnikẹni to ba fẹ ogun abẹle silẹ ni Naijiria pa ara rẹ tabi ki irufẹ ẹni naa fi Naijiria silẹ.
''A gbọdọ gbaruku ti Naijiria ni, ori bibẹ kọ loogun ori fifọ''























