Oduduwa Republic: Abeokuta, Ibadan ,Akure, Osogbo àti àwọn ibòmíràn tí ìwọ́de tí wáyé kọjá

Awọn oluwọde 'Yoruba Nation'nilu Abeokuta

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ilana Omo Odua

Ipinlẹ Ekiti ni iwọde awọn to n ja fun idasilẹ orileede Yoruba yoo sodo si lọjọ Abamẹta yi.

Saaju asiko yi, wọn ti se iwọde lawọn ipinlẹ ilẹ kaarọ o jiire miran ni Naijiria.

Lasiko awọn iwọde wọn, niṣe ni awọn alatilẹyin idasilẹ Odua Nation maa n kọ orin ti wọn a si tun gbe asia Yoruba Nation kiri.

Ọrọ iwuri naa a si maa waye paapa lati ẹnu ọkan lara awọn to lewaju ipe yi tii ṣe Sunday Adeyemo ti awọn eeyan mọ si Sunday Igboho.

Die ree lara awọn iwọde to waye kọja sẹyin ati oun to ṣẹlẹ nibẹ.

Àkọlé fídíò, Teachers retirement age and years of service: Ìrírí àwọn àgbà olùkọ́ ṣì wúlò fún àwa ọ̀dọ́

Iwọde ipinlẹ Oyo,ero pọ biba niwaju Mapo Hall

Ibadan ni o gbalejo iwọde yi lọjọ Kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin ọdun yi.

Bo tilẹ jẹ wipe awọn ọmọ ilana Odua ti kọkọ bẹrẹ iwọde ṣaaju ni ilu Ibarapa eyi to ṣokunfa bi wọn se le Seriki Fulani Igangan nilu.

Nibi iwọde Ibadan ti wọn fi pe fun idasilẹ Oodua Nation, niṣe lawọn ọlọpaa pọ biba ni Ori oke Mapo ṣugbọn ko si ikọlu pẹlu awọn oluwọde.

Awọn oluwọde 'Yoruba Nation'nilu Osogbo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ilana Omo Odua

Abeokuta:Ilana Ọmọ Odua ni ọlọpaa 200 le dena de awọn nibi iwọde

Ẹgbẹ to n ja fun ominira ilẹ Yoruba, Ilana Ọmọ Oodua sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi sikun ofin mu eeyan marundinlọgbọn ti wọn kopa ninu iwọde yi niluu Abeokuta.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

Ninu atẹjade kan ti akọwe ẹgbẹ naa, Maxwell Adeleye buwọlu, eyii to fi ṣọwọ si BBC lo ti kede bẹẹ.

O ni nnkan bii igba ọlọpaa lo yii awọn eeyan naa ka ki wọn to fi ofin mu wọn l'Abeokuta.

Awọn oluwọde 'Yoruba Nation'nilu Osogbo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ilana Omo Odua

Iroyin ni iwaju aafin Alake ti ilu Ẹgba ni awọn ọlọpaa naa ti ko awọn oluwọde ọhun sinu ọkọ Black Mariac ti wọn gbe wa.

Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kọkọ ki awọn oluwọde naa nilọ pe wọn ko gbọdọ gunle iwọde naa, bi bẹẹ kọ, awọn eeyan naa yoo foju wina ofin.

Ṣugbọn awọn ọmọ ẹgbẹ naa fesi pada pe ti ọlọpaa ni wọn n wi nitori awọn yoo tẹsiwaju pẹlu iwọde naa.

Àkọlé fídíò, Magaret Jimoh: Èrè díẹ̀ ti tó mi níbi oúnjẹ ti mò ń tà- Maggie Rice

Osogbo,IOO sọ pe ọwọ awọn tẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS

Awọn igun ọmọ Yoruba to n beere fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Yoruba nation pade ni ilu Oṣogbo tii ṣe olu ilu Ipinlẹ Ọṣun loni.

Iwọde wọn ọhun to waye fun ọpọlọpọ wakati da lilọ bibọ ọkọ duro ni ilu Osogbo.

Awọn oluwọde 'Yoruba Nation'nilu Osogbo

Gbogbo bi wọn ti n wọde ni wọn n kọrin ijagbara ati ẹhonu lori ipenija ti wọn woye pe o nkoju iran ọmọ Yoruba ni orilẹede Naijiria.

Lati ipinlẹ Kogi, Kwara, Eko, Ọyọ, Ogun, Ondo, Ekiti ati Ọṣun lawọn oluwọde naa ti wa.

Nibi iwọde itagbangba yi awọn iṣẹlẹ manigbagbe kan waye.

Awọn oluwọde 'Yoruba Nation'nilu Osogbo

Akọkọ ni pe Sunday Igboho sọ pe oun atawọn ẹlẹgbẹ oun ko ni gba eto idibo laaye mọ ni ilẹ Yoruba, titi di igba ti ẹkun naa ba gba ominira rẹ.

Ẹlẹẹkeji ni pe fidio kan tun fara han lori ayelujara lẹyin iwọde naa, eyi to ṣafihan bi awọn ọmọlẹyin Sunday Igboho ṣe mu eeyan kan ti wọn fura si pe oṣiṣẹ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS ni.

Ileeṣẹ ọtẹlẹmuye DSS ko fesi si fọnran yi

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....

Akure:Iwọde waye ṣugbọn Akeredolu loun ko faramọ Oduduwa Nation

Ni ikorita Isikan nilu Akure, ni iwọde naa ti gberasọ, ti awọn oluwọde naa si lọ yika ilu naa lati la awọn araalu lọyẹ nipa pataki idasilẹ orilede Oduduwa.

Akọroyin BBC Yoruba to wa nilu Akure jabọ pe ni irọwọrọsẹ ni iwọde naa n lọ, lai si rogbodiyan kankan.

Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, facebook/oluwarotimi akeredolu aketi

Aṣyinwa aṣẹyinbọ iwọde naa ti Sunday Igboho bawọn kopa, Gomina Rotimi Akeredolu sọ pe oun ko faramọ idasilẹ Oduduwa Nation.

Ọrọ yi to sọ ni idahun si iroyin to gbode pe Sunday Igboho ni Akeredolu wa lẹyin awọn ajijagbara jẹ koko pataki ta ri fa yọ lẹyin iwọde yi.

Akeredolu sọ pe lootọ lohun faaye gba awọn oluwọde ṣugbọn yatọ si ilẹ Yoruba to wa ni Naijiria, ohun ko faramọ idasilẹ orileede Yoruba miran