HND BSC Dichotomy: Àwọn sẹ́nétọ́ Naijiria buwọ́lu òfin tí yóò fi òpin sí ìdẹ́yẹsí àwọn tó ní HND

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn aṣofin agba ni Naijiria ti buwọlu ofin ti yoo koju bi awọn eeyan kan kii se tẹ́wọ́ gba àwọn akẹkọọ jade ni Polytechnic
Ile aṣofin agba ni Naijiria ti buwọlu ofin tuntun kan ti yoo fi opin si idẹyẹsi to ma n waye laarin awọn akẹkọọ jáde ni Fasiti ati awọn to ni iwe ẹri HND lati Polytechnic.
Igbimọ to wa fun idasilẹ àwọn ilé ẹ̀kọ́ giga ati ipese owo iranlọwọ TETFUND, lo gbe aba ofin naa lọ siwaju awọn akẹẹgbẹ wọn, ti awọn aṣofin agba si buwọlu abala kinni si ikẹfa.
- Ìjọba Nàìjíríà ṣàfikún owó aàbò fáwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera
- 'Àwọn ọmọ ogun Naijiria pa ọmọ ẹgbẹ́ ISWAP 50 ní Borno'
- A ti rí dírẹ́bà àti olùrànlọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nínú bọ́ọ̀sì- Adarí ilé ẹ̀kọ́ Chimola Schools, Akure
- Èmi ò lè káwọ́ gbera kí Nàìjíríà bàjẹ́ lójú mi o, Alaafin sọ̀rọ̀ sókè
- Àwọn adigunjalè pa èèyàn bí mẹ́rin, níbi ìkọlu bánkì méjì ni Ikire àti Apomu
Alaga igbimọ naa, Senator Ibrahim Shekarau sọ pe fifi ọwọ si ofin naa yoo fi opin si idẹyẹsi ti awọn akẹkọọ gboye HND ma n doju kọ ti wọn ba n wa iṣẹ́.
Bakan naa lo sọ pe aba ofin naa yoo gba àwọn to ni HND lọwọ oriṣiriṣi idiwọ ti wọn ma n ni, ti yoo si tun mu ki wọn o ma gba apọnle ati itẹwọgba bi ti awọn to jade ni fasiti.
O fi kun ọrọ rẹ pe ti wọn ba pa iyatọ to wa laarin awọn to ni HND ati degree run, yoo fi opin si aisi oṣiṣẹ to ni Naijiria.
O ni eyi yoo mu idagbasoke ba ìṣàkóso ijọba, yoo si tun fun awọn akẹkọọ jade naa ni ìwúrí lati ma a dá si nkan to n lọ níbi ti kaluku wọn ba ti n se iṣẹ.
Ki lo wa ninu ofin naa?
Ofin tuntun naa, ti Senator Ayo Akinyelure ṣe agbatẹru rẹ ni afojusun lati fi opin si idẹyẹsi, ikunsinu, owo oṣu ti ko dọ́gba, ati ilana igbani sisẹ, to ma n koju àwọn to ni iwe ẹri HND lọwọ, to si n sisẹ ni ileesẹ ijọba ati aladani.
O tun gbero lati gbe imọ ẹ̀rọ ni Naijiria lárugẹ, eyi ti yoo mu ki awọn akẹkọọ to nifẹ si imọ ẹ̀rọ lati lọ fun ẹ̀kọ́ ni polytechnic.
Nigba to n ṣorọ nibi agbeyẹwo aba ofin naa fun igba kejì, Senator Akinyelure sọ pe fifi ọwọ rọ àwọn to ni iwe ẹri HND le ṣe akoba fun afojusun Naijiria lati ni awujọ to ni imọ ẹ̀rọ ati sayẹnsi.
- Lẹ́kṣọ́rà fásitì FUOYE kan tún kó sí gbaga ẹ̀sùn aṣemáṣe pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́
- Ọwọ́ ikọ̀ Amọtẹkun ba Mutiu Abdul-Rasheed, afurasí tó ń ta ẹ̀yà ara èèyàn ní Ibadan
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ ìjọba, dẹndẹ ìyà yóò jẹ orí yín bí Nàìjíríà bá pínyà pẹ́rẹ́, toríi Yoruba Nation! - Oluwo
- Twitter kò dá sí ọ̀rọ̀ IPOB àti Nnamdi Kanu, bó ṣe wù wa la ṣe lè darí Nàìjíríà- Lai Mohammed
- Aàrẹ Muhammadu Buhari gba àmì ẹ̀yẹ Adarí tó dára jùlọ
Anfaani wo lo ni awọn akẹkọọ ni Naijiria yóò jẹ lara ofin yii?
Adari ile aṣofin agba, Senator Ahmed Lawan sọ pe ọjọ ti pẹ ti ọrọ idẹyẹsi ti wa laarin awọn akẹkọọ jáde ni Fasiti ati Polytechnic, sugbọn ofin ti awọn buwọlu yii yoo mu iwuri ba awọn akẹkọọ to ni HND.
O si rọ àwọn ileesẹ aladani ati ti ijọba pe ki wọn o tẹ́wọ́ gba a ni kete ti Aarẹ Muhammadu Buhari ba fi ọwọ si.
Nigba wo ni igbesẹ yii bẹrẹ?
Ọdun 2019 ni ile igbimọ asoju-sofin kọkọ fi ọwọ si aba ofin naa, ti wọn si sọ pe miliọnu marun-un Naira ni ileesẹ to ba tako o yoo san, nigba ti eeyan kan ṣoṣo to ba ta ko o yoo san miliọnu kan Naira.
Gẹgẹ bi akọsilẹ inu ofin naa, nkan kan naa (igbani sisẹ, igbega, anfaani lati kekọọ si, ati awọn nkan míì) ni yoo ma a tọ si ẹni to ni iwe ẹri BSC ati HND to ba n ṣe iru iṣẹ kan naa.
- UNILAG jáwé lọ gbélé ẹ fún àwọn olùkọ̀ méjì tí BBC tú àṣírí wọn nínú fíìmù 'Sex For Grades'
- Bíi ti UK, USA, Germany, France lẹ ó lè ṣe ẹ̀sìn tó bá wù yín yàlàyòlò ní orílẹ̀èdè Yorùbá Nation - Igboho
- Wo bí àwọn arúgbó ṣe le jẹ́ ìgbádùn ètò tí Buhari fi lọ́lẹ̀ fún wọn
- Èrò Akeredolu ni yẹ́n, àwa aṣòfin á ṣẹ̀sẹ̀ jókòó láti yọ tàǹda kúrò nínú ìrẹsí nígba tó bá ya- Senetọ Ajibola
- Òṣìsẹ̀ 170 tí Ajimobi lé ni Lautech ni ń o gbà padà, owó osù márun wọ́n yoo di sísan- Gómínà Oyo
Bakan naa ni Asofin Edward Pwajok to jẹ alaga igbimọ eto okoowo sọ pe, ko si idi pataki kankan fun idẹyẹsi naa, ati pe yoo kan mu ki awọn orilẹ-ede agbaye ma a fi oju tẹmbẹlu wo eto ẹkọ ni Naijiria ni.
"Ọpọlọpọ idẹyẹsi lo wa ni asiko igbani ṣíṣẹ, ipele kẹjọ ni wọn ma n fun awọn akẹkọọ jade ni fasiti, ti wọn si ma n fi àwọn to ni HND si ipele kẹfà tabi ikeje.".
Shekarau ni bakan naa lo ri ninu owo oṣu wọn, nitori pe awọn ileesẹ kan ma n san ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira fun akẹkọọ jade fasiti ti wọn gba ṣíṣẹ, ti wọn si n san ẹgbẹrun lọna aadọrin fun ẹni to ni HND, fun ipo kan naa.

Oríṣun àwòrán, @FPIlaro
Ile ẹ̀kọ́ Ilaro Polytechnic gba igbega.
Yatọ si ọrọ idẹyẹsi laarin awọn akẹkọọ jáde ni Fasiti ati awọn to jade ni polytechnic, ile aṣofin agba tun buwọlu pe ki ilé ẹ̀kọ́ Polytechnic Ilaro, ni ipinlẹ Ogun di fasiti ijọba apapọ fun imọ ẹ̀rọ.
Senator Solomon Adeola lati ipinlẹ Eko, to ṣagbatẹru aba naa sọ pe eyi yoo mu idagbasoke ba ẹ̀kọ́ nipa imọ ẹ̀rọ ni Naijiria.
- Pope Francis ṣe àyípadà òfin nínú ìjọ Aguda, ó sọ nkan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àlùfáà tó bá ní ìbálòpọ̀ kò tọ́
- Ìdí rèé tí Twitter kò fi le gbé ìdájọ́ Trump lé Ààrẹ Buhari
- Àwọn adigunjalè pa èèyàn bí mẹ́rin, níbi ìkọlu bánkì méjì ni Ikire àti Apomu
- Èmi ò lè káwọ́ gbera kí Nàìjíríà bàjẹ́ lójú mi o, Alaafin sọ̀rọ̀ sókè
- A ti rí dírẹ́bà àti olùrànlọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nínú bọ́ọ̀sì- Adarí ilé ẹ̀kọ́ Chimola Schools, Akure
- 'Àwọn ọmọ ogun Naijiria pa ọmọ ẹgbẹ́ ISWAP 50 ní Borno'














