Òṣìsẹ̀ 170 tí Ajimobi lé ni Lautech ni ń o gbà padà, owó osù márun wọ́n yoo di sísan- Gómínà Oyo

Makinde mu àdíku ba owo ile iwe LAUTECH

Oríṣun àwòrán, AFP

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, onímọ̀ẹ̀rọ Seyi Makinde Ti kéde mímú àdínkù bá owó ilé ìwé fásitì Ladoke Akintola (LAUTECH) pẹ̀lú ìdá márùndínlagbọ̀n nínú ọgọ́rùn.

Gómínà kéde ìgbésẹ̀ tuntun yìí lásíkò tó ṣe àbẹ̀wò àìròtẹ́lẹ̀ sí ilé ìwé náà nílú Ogbomoso, tí ó sì fi kun pé àdíkù owó náà yóò kan gbogbo ipele ẹ̀kọ́ lábẹ́ àkósòso bí ó ti wù kórí.

Nínú àtẹ̀jáde tó padà fọ́wọ́sí, akọ̀wé ìròyìn fún gómìnà Taiwo Adisa sàlàyé nǹkan ti Makinde sọ pé òun dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe gba òun láyé bótilẹ̀ jẹ́ pé òun kò fi ìwé ránṣẹ́ kí òun tó ṣe àbẹ̀wò síbẹ̀.

Bákan náà ló ṣe iléri pé láìpẹ̀ láìjìnà, ìpinlẹ̀ Oyo nìkan ni yóò ni ilé ẹ̀kọ́ náà,

O sọ fún àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ náà pé lẹ́yìn ìdìbò, ó ti yẹ kí òun pada wá láti dúpẹ́ sùgbọ́n ìgbìyànjú òun láti mú iléri ṣe lo da òun dúró, sùgbọ́n ẹbun àdínkù owó ilé ìwé ni òun múwa láti dúpẹ́.

Àkọlé fídíò, 'Èmi ọmọ Ikorodu ọ̀ga, ọmọ aṣalẹ̀ jẹ́jẹ! Wo bí àwọn ọmọdé tó "tuush" yìí ṣe ń fi oríkì Yorùbá dábíra

Makinde ni pe: Àdínkù owó náà kò nií fi ṣe bóya ọmọ ìpińlẹ̀ Oyo ni ẹni náà tàbi bẹ́ẹ̀ kọ́.

Makinde tún sàlàyé pé àra àra àwọn ìlérí tí òun ṣe ni láti ṣe àtúṣe òpópónà "Under -G Stadium pẹlú ètò iná ojú pópó láti dènà ṣíṣe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni ìṣekúṣe, jàwọ́n lólè tàbi ṣe ikú pa wọ́n.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson Shomolu Bariga ní 'Restructuring'ti bọ́ aṣọ kò bá Omọyẹ mọ́!

Gómìnà sàlàyé pé láti àsìkò yìí lọ, ètò ẹ̀kọ́ tí kò ju ọdún mẹ́rin lọ kò ni kọjá ọdún mẹ́rin bákan ni òun yóò túbọ̀ gba àwọn òṣìṣẹ́ tó le ni àádọ́jọ́ tí ìjọba tó lọ le kúrò lẹ́nú iṣẹ́ si ilé ìwòsàn ìkọ́ni Lautech ti òun yóò si san owó oṣù márùn tí wọ́n jẹ́ wọ́n .