Oro festival in Ikorodu: Idí tí obìrin kò gbọdọ̀ ṣe fi ojú rí Orò rèé

Oro festival

Ọjọ kinni, oṣu Kẹfa, ọdun 2021 ni oro jade niluu Ikorodu, ni ipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bii iwadii ti akọrọyin BBC to wa nibi ajọdun naa ṣe, oriṣi Oro meji lo wa nilu Ikorodu, oro kinni ni wọn n pe ni Magbo, eyii to jade lọjọ kinni, oṣu Kẹfa yii.

Oro keji ni wọn n pe Liwe ti yoo jade ni nnkan bii ọsẹ meji si mẹta lẹyin eyii to ṣẹṣẹ jade yii.

Irufẹ eeyan wo lo le foju ganni Oro?

Gẹgẹ bii ohun ti awọn to wa nidii iṣẹṣe ọhun sọ, gbogbo eeyan lo le foju ganni Oro, ko si yọ onile silẹ tabi alejo, koda ko yọ oyinbo alawọ funfun silẹ pẹlu.

Amọ ṣa o, obinrin kii ri Oro!

Ko si obinrin kankan to gbọdọ jade ni gbogbo asiko ti Oro ba n jade nitori ọkunrin nikan lo le ri oro.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson Shomolu Bariga ní 'Restructuring'ti bọ́ aṣọ kò bá Omọyẹ mọ́!

Idi re ti awọn agba ṣe sọ pe, ti obinrin ba foju ri oro, oro a gbe.

Gẹgẹ bii nnkan ti Oloye Ganiyu Taole sọ, ti obinrin alaboyun ba ṣeeṣi foju ganni Oro, ọmọ irufẹ obinrin bẹẹ le papoda lọjọ ikunlẹ.

Oro festival

Ṣugbọn to ba jẹ obinrin ti ko loyun ni tabi ti ko tii bi ọmọ kankan ri, irufẹ obinrin bẹẹ ko ni ṣe abiyamọ titi ti yoo fi jade laye.

Idi ree ti wọn sẹ maa n ṣe ipolongo pupọ ki asiko ọdun Oro to de ati ki Oro to jade.

Awọn Oniṣẹṣe

Oríṣun àwòrán, other

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Okunkun birimu, iloro asemọra, ferese atipa, olukuluku ninu iyẹwu. Eyi lohun tawọn obinrin yoo dojukọ lọjọ Iṣẹgun ọjọ kini oṣu kẹfa ọdun 2021 ni ilu Ikorodu.

Idi ni wipe, lọjọ iṣẹgun ni ajọdun oro Magbo yoo waye ni ilu Ikorodu.

Ajọdun Oro jẹ ọkan pataki lra awọn ajọdun iṣẹmbaye ni ilu Ikorodu awọn ọmọ onilẹ to jẹ ọkunrin. Awsn obinrin, ọmọde ati ajeji ko gbọdọ ysju sita ni gbogbo asiko oro naa.

Gẹgẹ bi iṣẹṣe, lasiko ọdun Oro yii obinrin kankan ko gbọdọ jade kuro ni ile rẹ,bẹẹni wọn ko gbọdọ ṣi oju wo awọn ọkunrin awọn ọkunrin to n ṣe atọkun fun Oro naa bi wọn ṣe n lọ lati agbegbe si agbegbe nibẹ.

Igbagbọ awọn eeyan agbegbe naa ni pe obinrin yoowu to ba fi oju ri awọn oloro naa yoo ku ni, tabi ki ohun buruku kan o ṣẹlẹ sii.

Àkọlé fídíò, 'Èmi ọmọ Ikorodu ọ̀ga, ọmọ aṣalẹ̀ jẹ́jẹ! Wo bí àwọn ọmọdé tó "tuush" yìí ṣe ń fi oríkì Yorùbá dábíra

Ọdun Oro kii ṣe ajeji si iran Yoruba; ọpọlọpọ awọn ilu lo n ṣe ọdun Oro ni ilẹ Yoruba, olukuluku wọn lo si ni ọna ti wọn gba fi n ṣe e.

Oloye Kazeem Adeniyi Roga to jẹ ọkan lara awọn adari ilu ni Ikorodu ṣalaye pe adura ni wọn n fi Oro ṣe lati le aburu lọ kuro ni ilu ati lati mu ki ire o maa wọ tọ awọn eeyan agbegbe naa wa.

Amọṣa arabinrin kan to ti figbakanri gbe nilu ti wọn ti gbe Oro ri ṣalaye pe eyi ko ri bẹẹ rara.

Àkọlé fídíò, Adebayo Murital David: Gbogbo iṣẹ́ tó ń múni là láyé wá láti ọpọlọ ni kìí ṣe agbára

Arabinrin Taiwo Yusuf ṣalaye pe to ba jẹ pe bẹẹ lo ṣe ri ni, ki lo de ti awọn ilu to n gbe Oro ṣi n foju wina aburu bii ajakalẹ arun iba eyi to n pa ọmọde ati gbogbo awọn ipaniyan loniranran to n waye.

O ni nṣe ni wọn n fi ọdun Oro naa tẹ ẹtọ awọn obinrin nitoripe awọn obinrin gan an lo n fara gba julọ lasiko ọdun Oro eleyi to lee waye fun bi ọsẹ meji lawọn ilu kan.

"Mo ms obinrin kan to ku sinu ile nitoripe ọkọ rẹ ko lee gbe lọ si ile iwosan nigba ti wahala ṣẹlẹ lori oyun to ni