Yoruba Nations agitation: Ẹ má jẹ kí ìdálúrú tó ń waye nilẹ Ibo rọnà wọ ilẹ Yorùbá o lórúkọ ìjìjàgbara - ẹgbẹ YWG

Bí wọn ṣe ń jó ilé kiri ní ilẹ Hausa àti Ibo, ẹ má gbabọdè rẹ nilẹ Yorùbá o!
Aarẹ ẹgbẹ Yoruba kan to n ri si igbe alafia (Yoruba Welfare Group) ti funpe si gbogbo awọn tọrọ kan nilẹ Yoruba bayii.
Wọn ni pe ki wọn wọn ma gbabọde dida wahala silẹ bo ṣe ti n ṣẹlẹ ni iha Ila-Oorun Ariwa ati Guusu-Iwọ Oorun Naijiria.
Iṣoro aisi aabo ti n peleke sii lorilẹede Naijiria to si ti n fa oniruuru gburu sita lawujọ eyi ti awọn ọdọ si n kara bọ gidi gan.
- 'Kò sí ààtò fún òfin Sharia àti ẹtọ àwa ẹlẹsìn Islam nínú Oduduwa Republic, a ò gbà!'
- Wo ohun ti yóò ṣẹlẹ̀ sí obìnri tó bá fi ojú rí Orò
- Ọ̀gá àgbà NECO papòdà- Kà nípa bí Ọjọ́gbọ́n Obioma ṣe kú
- Olorì Damilola fi èpè ránṣẹ́ sí 'bàbá' rẹ̀ to ní kò padà sọ́dọ̀ Aláàfin
- Wo ìdí tó fi ṣeéṣe kí ìjọba àpapọ̀ ó kéde àkọ̀tun ìséde n'ipínlẹ̀ Eko
Ẹwẹ, aarẹ ẹgbẹ YWG, Comerade AbdulHakeem Adegoke Alawuje sọ fun awọn akọroyin ninu atẹjade kan.
Wọn ni pe awọn gbọ iroyin pe iṣẹlẹ ipaniyan ati iwa idaluru to n lọ lọwọ lapaa Guusu - Ila Oorun paapaa julọ bi gbogbo oju ṣe n ri i ti eti n gbọ ọ nipa ipinlẹ Imo fẹ wọ ilẹ Yoruba.
Eyi lo mu ki wọn funpe si ijjọba, awọn gomina apaa Guusu - Iwọ Oorun, awọn lọbalọba ati onikaluku araalu lati fọwọsowọpọ bẹgi dina iṣẹlẹ yii.
- N kò tako Yoruba Nation, ohun tí mo sọ nípa Sunday Igboho rèé - Aseyin
- Tó bá dá Gani Adams lójú, kó dárúkọ àwọn ọ̀dàlẹ̀ inú Yoruba Nation - OPC New Era
- Ẹ̀yin aṣaájú APC, ẹ́ kábáàmọ̀ ìpinnu tẹ ṣe lórí ìdásílẹ̀ Yoruba Nation - Akitoye
- Ẹ wo àwọ́n lọ́balọ́ba tó ti ṣàtìlẹ́yìn jíjá fún Oduduwa Nation ní ilẹ̀ Yorùbá
- A ti rí ọmọ ilé kéú 11 míì nínú àwón tí agbébọn jí gbé ní ìpínlẹ̀ Niger
Adegoke to jẹ ajagunfẹhinti ki awọn ọdọ nilọ pe ki wọ́n ma fi aaye gba ki agbara ọdọ gun wọn de ibi pe wọn o maa "jo ile baba wọn" labẹ didbọn pe awọn n jijagbara lodi si aidaa ofin.
"Sí awọn ọmọ wa ti ko ni imọ nipa ogun, o n gun wọn lati ni iriri ọkan ṣugbọn awa kan ti a ti foju ri ogun la ni iṣẹ lati fi oye ye wọn bo ti le wu ko le to.
O ni o daju pe awọn Yoruba ko gbaradi de ogun "a ko si gbudọ gba ọkan laaye. Mo le ma mọ pupọ nipa awọn ẹya miran ṣugbọn mo mọ ti awọn lọbalọba ilẹ Yoruba".
O ni ni ọpọ igba ni a o bọwọ fun wọn "bẹrẹ latori awọn agberaga ọmọkunrin ati obinrin wa.
"Bi a ba ri olori ilu fin, dandan ni ki ilana aṣa ilu naa wo lulẹ bẹẹ si ni gbogbo aṣa adayeba wa ko ni ni apọnle mọ loju ara ita.
- Ọdún Oro bẹ̀rẹ̀ ní ìlú Ikorodu
- Adigunjalè ja Ọ̀gá ọlọ́pàá àti ẹni mẹ́ta míràn lólè
- Wo ìdí tí ECOWAS fi dá Mali dúró, tó tún fún àwọn ológun ní gbèdéke láti gbé ìjọba sílẹ̀
- Wo ìdí tó fi ṣeéṣe kí ìjọba àpapọ̀ ó kéde àkọ̀tun ìséde n'ipínlẹ̀ Eko
- A ti rí ọmọ ilé kéú 11 míì nínú àwón tí agbébọn jí gbé ní ìpínlẹ̀ Niger
- Ọjọ́ kínní oṣù kẹfà ni Amotekun yóò bẹ̀rẹ̀ sí ni máa gbógun tàwọn ọ̀daràn àti ajínigbé nílẹ̀ Yorùbá
O ni ori ni awọn oriade jẹ si awọn oloṣelu gan.
Amọ wọn o tẹle ilana to tọ mọ pẹlu bi wọn ṣe n pe awọn ajagun ibilẹ lai gba aṣẹ lọwọ awọn Oba ilu to yan wọn si iṣẹ.
O ni pe nitori eyi awọn ajagun ibilẹ gan ti wa bẹrẹ si ni ṣe bii pe awọn kọja ofin nipa riri awọn ọba fin tori awọn oloṣelu ti la wọn loju si owo nla nla biliọnu latẹyinwa.
Adegoke wa kilọ pe ẹgbẹ Yoruba Welfare Group o ni kawọ gbera maa woran ki wọn si jẹ ki awọn ti ko mọ nkankan dana sun ile toripe ina ko tilẹ da ẹni to da a jo mọ.
O ni apẹrẹ ni Nnamdi Kani to ni "kii ṣe olugbe Naijiria amọ ti oun atawọn ẹgbẹ rẹ ti dana sun gbogbo iha Guusu - Ila Oorun tan yanyan" o ni amọ wan o le ba odidi orilẹede jẹ, ẹkun tiwọn nikan naa ni wọn le ba jẹ".
Alawuje wa rawọ ẹbẹ si awọn ọdọ Yoruba lati ṣọra pẹlu ibinu ki wọn parapọ lati dena irufẹ nkan to n ṣẹlẹ nilẹ Ibo bayii ko ma baa waye nilẹ Yoruba, "ki wọn ma gba ki ilẹ wọn di ilẹ ija ogun".
Bakan naa, o gba awọn agbagba naa to n ti awọn ọda lẹyin lati maa da igboro ru ki wọn jawọ nibẹ wipe ilẹ Yoruba kii ṣe ibudo karakata fun ẹgbẹ tabi ọlọdani kankan.
"Ololufẹ alafia ni Yoruba a ko si gbudọ jẹ ki ipenija to wa lode lọwọlọwọ yii yi ọrọ daadaa naa pada".


















