Insecurity: Amotekun yóò bẹ̀rẹ̀ sí ni káàkiri ibodè nílẹ̀ Yorùbá láti máwọn ọ̀daràn àti ajínigbé- Adetunji adeleye

Awọn aṣiwaju ikọ Amọtẹkun ni Ọyọ n yẹ gomina Makinde si

Ọgagun ọga awọn Amotekun nilẹ Yoruba, Oloye Adetunji Adeleye ti kede pe ọjọ kinni oṣu kẹfa ni ẹṣọ eleto abo naa yoo bẹrẹ si ni maa kaakiri ibode awọn ipinlẹ Yoruba.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oloye Adeleye sọ pe awọn gomina ti pese ọkọ tawọn maa lo fun iṣẹ yii.

O tun fikun ọrọ rẹ pe kii ṣe wi pe awọn maa ṣiṣẹ ileeṣẹ aṣọbode.

''Amotekun nikan kọ lo maa ṣiṣẹ yii, awọn ọlọpaa, DSS ati Civil Defence yoo fọwọ sowọpọ pẹlu wa lati le gbogun tawọn adigunle loju popo.

Ṣe ẹ mọ pe idasilẹ Amotekun wa fun iranwọ fawọn agbofinro ni tẹlẹ.

Àkọlé fídíò, Adebayo Murital David: Gbogbo iṣẹ́ tó ń múni là láyé wá láti ọpọlọ ni kìí ṣe agbára

Ofin to gbe wa kalẹ sọ pe ibi ti apa ba ti n ro wọn ni ki a ti ba wọn gbe e soke.

Awọn eṣọ Amotekun to wa ni ipinlẹ Osun yoo maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn to wa ni Oyo, awọn ti ipinlẹ Oyo naa yoo gbera lọ si Ondo, bi a o ṣe maa ṣee niyẹn,'' Oloye Adeleye ṣalaye.

Amotekun yóò máa ṣọ́ ibodè àwọn ìpínlẹ̀ Yorùbá láti máwọn ọ̀daràn àti ajínigbé

Gbogbo eto lo ti to bayii fun ẹṣọ alaabo Amotekun lati maa ṣọ ibode awọn ipinlẹ Yoruba.

Igbesẹ yii gbaye lati pese abo to munadoko kaakiri ilẹ kaarọ o jiire.

Ọgagun ẹṣọ Amotekun ipinlẹ Ondo to tun jẹ alaga awọn ọgagun Amoteukun nilẹ Yoruba, Adetunji Adeleye lo fidi ọrọ yii mulẹ.

Aworan Amọtẹkun

Oríṣun àwòrán, Western Nigeria security network

Ọgbẹni Adeleye ni eyi ṣe pataki nitori o maa jẹ ko rọrun lati mu awọn ọdaran to ba sa lati ipinlẹ Yoruba kan si omiran.

Adeleye to sọrọ niluu Akure fidi rẹ mulẹ pe dida ẹranjẹko awọn ti dinku nipinlẹ Ondo bayii.

Àkọlé fídíò, Democracy day 2021: Kí ni Nàìjíríà ti jèrè lára gbogbo ààrẹ tó ti jẹ látọdún 1999?

O ni awọn darandaran ti bẹrẹ si ni sanwo fawọn agbẹ ti wọn ti da ẹran jẹ oko wọn.

Ọgagun Amotekun naa ni gbogbo opopona to wa kaakiri ilẹ Yoruba lawọn ẹṣọ Amotekun yoo maa ṣọ bayii.

''A fẹ rii pe iṣẹlẹ adigunjale ati ijinigbe dinku lawọn opopona wa nilẹ kaarọ o jiire.

Àkọlé fídíò, Simple tricks to identify designer shoes: Ṣe ìwọ lè wọ bàtà #2 mílíọ̀nú

A ti ṣe akiyesi pe awọn ibi ti ọna ti bajẹ tawọn awakọ kii ti lanfaani ti sare ni iṣẹlẹ ijinigbe ti maa n saaba ṣẹlẹ.

Bakan naa, a gbọdọ ri wi pe ofin maa dẹran ni gbangba mọ mulẹ kaakiri ilẹ Yoruba.

A ti bẹrẹ si ni mu awọn darandaran to ba dẹran jẹ oko awọn eeyan wa.

Darandaran to ba ti dẹran jẹ oko bayii ti di ọdaran.