Adeherself: Gbogbo ayé ti rí báyìí pé lọkọ láya orí ayélujára lèmi àti Cute Abiola jọ́ ń ṣe

Cute Abiola ati Adeherself

Oríṣun àwòrán, Adeherself

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Adedamola Adewale ti ọpọ mọ si Adeherself tun ti sọrọ lori igbeyawo Acute Abiola pẹlu ọrẹbinrin rẹ ọlọjọ pipẹ.

Adeherself fi ọrọ naa soju opo Instagram rẹ nibi to ti sọ pe gbogbo eeyan lo ti ri bayii pe iṣẹ loun ati Cute Abiola n ṣe pẹlu awọn fọto tawọn ti maa n fi sori ayelujara.

''Emi ati Cute Abiola dabi tẹgbọn taburo, ọrẹ kidi si ni ajọ jẹ.

Akẹgbẹ mi ti mo bu iyi fun gidi ni Cute Abiola, gbogbo ohun tawọn eeyan n gbe kiri lori ọrọ naa bayii fihan pe iṣẹ awọn ni ipa gidi lori awọn eeyan ni.

O jẹ ohun iwuri fun mi pe awọn ololufẹ wa n gba awada ti a n ṣe tọwọ tẹsẹ.

Amọ ere lasan ni gbogbo rẹ, kii ṣe wi pe a n fẹ ara wa.

Àkọlé fídíò, Wọ́n rò pé mo ya wèrè ni Saudi lẹ́yìn ikú ọkọ mi

Irufẹ iṣẹ ti a n ṣe lọwọ lo jẹ ki emi ati Cute Abiola ti a n ṣe ti a ṣe n fi fọto lọkọ laya ara wa sori ayelujara.

Nitori naa, gbogbo awọn to ti n fede fọ lori ọrọ yii, ẹ ṣee.

Àkọlé fídíò, Simple tricks to identify designer shoes: Ṣe ìwọ lè wọ bàtà #2 mílíọ̀nú

Mo le fi gbogbo ẹnu sọ pe inu mi dun pe emi ati Abiola ṣiṣẹ to jẹ nnkan iwuri,'' Adeherself lo ṣalaye bẹẹ.

Àkọlé fídíò, India, Coronavirus: Ìtọ́jú aláìsàn ló jẹ́ mi lógún nítorí ètò ìlera wa mẹ́hẹ- Nọ́ọ̀sì Kama