Adeherself: Adẹ́rìnpòṣónú Cute Abiola ṣe ìyàwó, àmọ́ kìí ṣe pẹ̀lú Adeherself

Cute Abiola pẹlu Adeherself

Oríṣun àwòrán, Adeherself

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Iyawo dun lọsingin, ọkọ tun mi gbe. Adẹrinpoṣonu Cute Abiola mori le ilu Ogbomoso lati lọ mu ẹni bi ọkan rẹ fi ṣe aya.

Ọpọ lo ti n sọ tẹlẹ pe Adedamola Adewale ti ọpọ mọ si Adeherself ni Abiola yoo fẹ sile gẹgẹ bi aya rẹ.

Amọ ọrọ ko ri bẹẹ mọ lẹyin ti Abiola gbọna Ogbomoso lọ ṣe igbeyawo pẹlu ọrẹbinrin rẹ ti wọn ti jọ wa tipẹ.

Abiola ati Adeherself maa n ṣaaba fi fọto ara soju opo ayelujara lo jẹ ki ọpọ maa ro wi pe ọrọ ifẹ wa laarin wọn.

Ṣugbọn gbogbo ahesọ ọrọ naa ti di afi sẹyin ti eegun fi aṣọ bayii lẹyin ti Abiola ti di alaya l'Ogbomoso.

Ẹwẹ, Adeherself naa ti sọrọ soke lẹyin ti fọto igbeyawo Abiola gbori ayelujara kan.

Àkọlé fídíò, Democracy day 2021: Kí ni Nàìjíríà ti jèrè lára gbogbo ààrẹ tó ti jẹ látọdún 1999?

O ni oun ti sọ tẹlẹ pe Abiola ko figba kan dẹnu ifẹ kọ oun ri, ati pe awọn mejeeji ko fẹra ri.

Awọn eeyan ro pe nkan wa laarin wa nitori Abiola fun ra rẹ ko sọ ohun kan lori ọrọ naa.

''Ọrẹ ni emi ati Cute Abiola, ọrẹ naa la o si maa jẹ lẹyin to ti ṣe igbeyawo yii.

Mo ki Abiola ati iyawọ rẹ ku oriire igbeyawo wọn, ṣe awọn eeyan ti wa ri pe iyawo Abiola gangan an ti de bayii,'' Adeherself lo ṣalaye bẹẹ,