Yoruba Nation: Ẹ jẹ́ ká pe àwọn ọ̀dọ́ ajìjàgbara yìí, ká ṣa àwọn tó dára sọ́tọ̀, ká bá àwọn tókù sọ̀rọ̀ - Ooni

Ọọni Adeyeye

Oríṣun àwòrán, Ọọni Adeyeye

Kabiyesi alayeluwa alaṣẹ ikeji oriṣa ti ile Ife, Ọọni Adeyeye Enitan Ogunwusi ti fesi lori ọrọ iṣoro aabo to n koju Naijiria lọwọlọwọ to si lọ ọ mọ ijijagbara to n lọ lọwọ nilẹ Yoruba.

Ọba Adeyeye n sọrọ nibi ipade to waye ni Ajọ to n ri si ọgbọn amulo nibi ti awọn eekan ilu bii, awọn aṣofin, awọn olori awọn oṣiṣẹ alaabo atawọn adari ilu nilẹ Yoruba lori ọna abayọ si iṣoro to wa nilẹ ati ọna fun ilọsiwaju.

"A o níbomiran, orilẹede yii ti gbogbo wa ni, gbogbo wa ati awọn alaṣẹ wa ni ijọba la mọ ipo ti orilẹede yii wa lọwọlọwọ lai tan ara wa jẹ".

Ọọni sọ pe lori ile atijọ to ti di alapa la tun n mọ le lori. Bẹẹ si ni awọn ọdọ orilẹede yii to jẹ wipe onka wọn lo pọ ju, ebi n pa wọn wọn si n binu.

Àkọlé fídíò, King Sunny Ade's son: Ohùn orin bàbá mi nìkan kọ ni l’Ọlọrun fún mi, ijó bíi kòkòrò ni ṣáá

Ọọni ṣapejuwe gbogbo awọn ti wọn jọ jokoo nibi ipade naa o si ke si wọn pe ki wọn boju wo ọjọ ori ara wọn, ki wọn tun wo awọn to wa ni ipo aṣẹ lọwọ ni Naijiria, gbogbo wọn ti dagba.

"Gomina to kere ju ni Naijiria jẹ ẹni ọdun mẹrindinlaadọta, laarin awọn to si wa laarin ọmọ ọdun mejidinlogun si awọn ti ko tii pe ogoji lo to ida to le ni aadọrin".

Ọba Adeyeye ni awọn ọdọ yii naa lo agbara ju bi a ba n sọ̀rọ̀ awọn to lee mojuto abo, "ṣe oku wa lawọn taa ni yii ni abi wọn o si lorilẹ aye, irọ ni awọn ọdọ wa wa laaye, wọn o ku".

Ọba ni Aarẹ to jẹ araalu ipo kini, ẹni to tẹle e, ati ẹni ipo kẹta, ọkan naa ni gbogbo wọn n sọ. O ni gbogbo awọn agba ilu yii lo mọ iṣoro Naijiria, "bawo la ṣe n jẹ ki wọn kopa?"

"To ba wa di igba idibo taa nilo wọn, ao maa tọ wọn lọ, amọ awọn ọdọ yii n binu ebi si n pa wọn".

Ọọni ni gbogbo awọn agba to di ipo nla nla mu o le ṣe aya gbangba lọ si ilu ti wọn ti bi wọn mọ ki wọn sun mọju lai foya - "ẹ wa fi awa lọba lọba nikan silẹ ti wọn, awa la si mọ gbogbo nkan ti wọn n la kọja".

Koda o ni ijọba ibilẹ to jẹ ipilẹ gangan fun gbogbo eto keto ti Naijria ba fẹ ṣe ti dawo patapata ijọba o si bikita rara nipa wọn. "Gbogbo wa taa wa nibi la ni ẹbi, taa ba ni ka maa sọrọ ni gbogbo igba, ao ni ri esi".

Ọọni pe akiyesi wọn si i wipe gbogbo awọn ọdọ yii lo n binu o ti ebi si n pa wn gidigidi koda wọn o kọ lati gbena woju ẹnikẹni.

Kabiyesi tun ni ninu gbọngan ti awọn joko si ti wn ti n ṣepade yii, ko tun si ọdọ nibẹ, bawo ni wọn ṣe wa fẹ ki awọn afẹnuko naa di ṣiṣe.

Ọọni sọ siwaju pe gbogbo eeyan lo lee ri awọn nkan ibanujẹ to n ṣẹlẹ niluu. "Ilana to wa nilẹ yii ti ja wa kulẹ o si ti kuna, gbogbo ipenija ta n koju gẹgẹ bi orilẹede naa, gbogbo wa lo kan.

A gbudọ ṣe atunto iwoye wa nipa jijẹ olufọkansin araalu. "Awọn oke iṣoro wa lee di ipẹtẹlẹ bi a ba jọ ṣiṣẹpọ ni irẹpọ".

Ọọni sọ pe nitori naa gbogbo eeyan ni lati ṣe iṣe ọrọ ti wọn n sọ kii ṣe ki wọn kan maa sọrọ lasan amọ ki gbogbo awọn tọrọ kan forikori eyi to nii ṣe pẹlu kí awọn ọdọ wa maa wa ni ijoko ibi ti wọn ti n ṣe awọn ipinu to ṣe koko. Ọọni ni eyi gangan ni ọna aa gba o.

Kóda Kabiyesi tun fi si oju opo Twitter rẹ pe "asiko yii ni asiko lati gbe igbesẹ".