King Sunny Ade's son: Ohùn orin bàbá mi nìkan kọ ni l’Ọlọrun fún mi, ijó bíi kòkòrò ni ṣáá

Àkọlé fídíò, King Sunny Ade's son: Ohùn orin bàbá mi nìkan kọ ni l’Ọlọrun fún mi, ijó bíi kòkòrò ni ṣáá

"Ati ipa daradara ati buburu ni orin baba mi ti mu ba iṣẹ orin temi"

Tẹẹ ba ni ipa buburu lọna wo?

Emperor Ademola Adegeye to jẹ ọmọ gbajugbaja olorin juju lagbaye, Oloye Sunday Adeniyi Adegeye ti ọpọ mọ si King Sunny Ade(KSA) ni lootọ loun gbadun anfani pe oun jẹ ọmọ gbajugbaja olorin ti gbogbo agbaye mọ tori o mu oun mọ awọn eeyan nla nla amọ sibẹ sibẹ, oun naa koju ipenija.

Kii ṣe gbogbo ọmọ King Sunny Ade lo gbe igba iṣẹ orin tọpasẹ baba wọn amọ Emperor ni tirẹ yan iṣẹ naa laayo tori ẹbun ohun orin akoda to fi mọ ijo jijo ti Ọlọrun fun un eyi ti wọn bi i mọ ọ.

Gẹlẹ bi baaba rẹ King Sunny Ade ṣe maa n kọrin bo si ṣe maa n jo ni Emperor naa ṣe ri, o tun wa foju jọ baba bii ẹpa.

Lẹyin to pari ileewe giga fasiti to si ṣe agunbanirọ tan lo to lanfani lati ja si gbangba maa kọrin ta gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ tori o ni baba awọn awọn ti ki awọn nilọ ṣaaju.

"King Sunny Ade sọ pé ìkankan nínú àwa ọmọ rẹ ò gbudọ ṣe orin àyàfi bi a ba pari agunbanirọ".

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to si ṣe to pari ileewe rẹ, o tọ baba rẹ lọ, Emeror ni oun so mọ King Sunny Ade lẹsẹ pe "Baba mi, ìgbà tí mò ń yọ orin kọ gan díẹ díẹ, mo mọ pé ẹ mọ̀ mọ síi, ṣùgbọn nísinsìnyìí, mo fẹ àdúrà yín".

Baba gba a laye lati maa lo gbogbo nkan ti wọn ni ti wan ti jere nidii iṣẹ orin titi to fi mọ ko maa wa kọrin lori itage wọn nigbakuugba ti wọn ba n ṣere.

Ẹwẹ, Emperor ni lara awọn ọ̀rs ti oun jẹ ni pe baba oun ṣi ọpọ ilẹkun fun oun, o si ti awọn ilẹkun kan pa fun oun.

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ alaye gbogbo ipenija to koju wa ninu fidio ifọrọwanilẹwo BBC Yoruba pẹlu ọmọ Oloye King Sunny Ade.