Yoruba Nation: Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ ìjọba, ìyà ń bọ̀ fúń yín bí Nàìjíríà bá túká pẹ́rẹ́ - Oluwo

Oluwo, Sanwoolu, Lai

Oríṣun àwòrán, Oluwo

"Owo oṣu oṣiṣẹ, ipinlẹ Eko nikan lo lẹmi ẹ lai duro de ijọba".

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Akanbi ti kilọ pe awọn oṣiṣẹ ijọba ẹkun Guusu - Ila Oorun ni yoo fara gba bi ipinya ba de ba orilẹede Naijiria.

Ọba Abdulrosheed wa rọ awọn ọdọ ilẹ Yoruba to n ja fun idasilẹ Yoruba Nation pe ki wọn na suuru si i.

Oluwo tu ọrọ yii sita nibi eto ti gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola ti ṣe agbekalẹ iwe ilana aato fun awọn ọdọ eyi to waye ni Oṣogbo, olu ilu ipinlẹ Osun.

Ọba Oluwo latilẹ ko figba kankan ti ija fun Yoruba Nation lẹyin ti ko si fi bo ninu awọn atẹjade rẹ.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

Nibi eto naa, Oluwo ti Iwo kan sara si ijọba gomina Oyetola pe o ni eto rere fun awọn ọdọ ni ipinlẹ naa o si rọ awọn ọdọ lati pawọpọ pẹlu ijọba ki wọn lee ṣe iṣẹ daadaa fun wọn ju ki wọn maa jijagbara fun ituka kiri.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson Shomolu Bariga ní 'Restructuring'ti bọ́ aṣọ kò bá Omọyẹ mọ́!

Oba Abdulrosheed sọ ninu ọrọ rẹ pe ipinlẹ kan ṣoṣo to lee da san owo oṣu awọn oṣiṣẹ rẹ lai duro de ijọba apapọ ni ipinlẹ Eko.

"Awọn ipinlẹ ẹkun Guusu - Ila Oorun to ku o lee san owo awọn oṣiṣẹ wọn bẹ si ni awọn to wọpọ nibẹ, oṣiṣẹ ijọba ni wọn".