Buhari: Twitter kò dá sí ọ̀rọ̀ IPOB àti Nnamdi Kanu, bó ṣe wù wa la ṣe lè darí Nàìjíríà- Lai Mohammed

Lai Mohammed

Oríṣun àwòrán, @Lai Mohammed

Minista Lai Mohammed ti sọrọsoke lori igbesẹ twitter si ọrọ aarẹ Mohammadu Buhari

O ni "a le dari ilu wa bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ, amọ, afurasi ni Twitter jẹ lorilẹede Naijiria".

Lai Mohammed beere pe ṣe Twitter ti kọkọ yọ awọn ọ̀rọ̀ abuku to ti ẹnu Nnamdi Kanu kuro?

Twitter yii kan naa lasiko EndSARS ṣe ohun ti wọn fẹ ṣe, awọn si lo kọkọ fa oju opo Aarẹ Amerika tẹlẹ, Trump yọ bii jiga".

Minisita iroyin ati aṣa ni Naijiria, Lai Mohammed ti fesi lori igbesẹ si ileeṣẹ to ti orilẹ-ede Amẹrika wa, Twitter nipa yiyọ ọrọ Aarẹ Muhammadu Buhari kuro lori itakun Twitter.

Lai Mohammed ni ọwọ ifura fẹ wa bayii ninu gbogbo ohun ti ileeṣẹ Twitter n ṣe ni Naijiria.

Ọrọ Lai Mohammed jade lẹyin ti ileeṣẹ Twitter yọ ọrọ ti aarẹ Buhari kọ kuro nibi to ti n sọrọ nipa pe oun yoo fi oju awọn to n da wahala silẹ ni ilu ri mabo to si n fi ọrọ we ohun ti oju rẹ ri gẹgẹ bi ologun fun ọgbọn ọdun.

Twitter logo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Twitter dey look to increase business wey go dey happen for di site

Nigba ti o n gbe igbesẹ rẹ lẹyin lori idi to fi yọ ọrọ Ààrẹ Buhari, Twitter ni atẹjade Aarẹ ru ofin idasilẹ Twitter.

Nigba to n ba awọn akọroyin ile aarẹ sọrọ l'Ọjọbọ, Minisita fi ẹsun kan Twitter pe "wọn le kọ eti ikun si awọn ọrọ alufansa ti olori ẹgbẹ ajijagbara IPOB, Nnamdi Kanu ti n sọ lati ọjọ yii, tori naa wọn o le tan awọn ọmọ Naijiria rara"

Lai Mohammed

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ó yẹ ka fura sí iṣẹ́ tí wọ́n rán Twitter wa ṣe ní Nàìjíríà, ejò fẹ́ lọ́wọ́ ńńú - Lai Mohammed

ìdí tí Twitter fi yọ ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ Buhari sọ sí àwọn aráàlú àti èsì Lai Mohammed

Àkọlé fídíò, 'Èmi ọmọ Ikorodu ọ̀ga, ọmọ aṣalẹ̀ jẹ́jẹ! Wo bí àwọn ọmọdé tó "tuush" yìí ṣe ń fi oríkì Yorùbá dábíra

O ni nigba tawọn eeyan n jo agọ ọlọpaa kiri ti wọn n pa awọn ọlọpaa ni Naijiria lasiko ifẹhonuhan EndSARS, loju Twitter, ẹtọ to dara ni lati fẹhonu han. Ṣugbọn nigba ti irufẹ nkan b ṣẹlẹ ni ilẹ Capitol, ogun able lo jẹ".

Lai Mohammed ranti pe asiko ifẹhonuhan #EndSARS to jẹ wipe wọn ji awọn ẹru ijọba ko wọn tun ba ọpọlọpọ nkan jẹ loṣu kẹwa ọdun to kọja, o ni ileeṣẹ Twitter yii kan naa ko ṣe bii pe wọn ri nkankan lasiko ọhun.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

Minisita ni ofin Twitter wo wa ni aarẹ Buhari tako to fi to ki wọn pa ọrọ rẹ rẹ to si jẹ pe awọn ọrọ igba EndSARS ṣi wa digbi.

Lai Mohammed fi kun un pe lootọ Twitter le ni ofin rẹ o, kii ṣe ofin agbaye. "Bi aarẹ ba lero bakan bakan nipa ọrọ kan, o lẹtọ lati sọrọ torinaa ka ma maa fi eso aapu we ọsan".

"Mi o rii ri nibi kankan lagbaye ti ileeṣẹ kan tabi eeyan kan yoo duro sibi kan nita Naijiria ti yoo wa maa dari awọn oṣiṣẹ rẹ lati maa gbogun ti awọn alaṣẹ orilẹede naa, ọlọpaa tabi awọn ologun".

aṣia PDP ati APC

Oríṣun àwòrán, other

Ohun tí wọ́n ní kí òkóbó Buhari bọ̀ lórí ọ̀rọ̀ àbò ni kó bọ̀, dípò dídúnmọ̀huru mọ́ aráàlú- PDP

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti ke si aarẹ Buhari pe ko ye fi ẹtẹ silẹ maa pa lapalapa lori ọrs abo lorilẹede Naijiria.

Ninu esi to fọ si ọrs ti aarẹ sọ pe oun n bs wa gbena woju awọn to n da ina ogun ati ọtẹ lorilẹede Naijiria.

ẹgbẹ oṣelu PDP ni ki aarẹ ye dun mọhuru mọ araalu ms , dipo bẹẹ ko gbe igbesẹ to loorin tako ipenija ọrs abo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria.

Buhari

Oríṣun àwòrán, @Presidency

Àbámọ̀ ńlá ń bọ̀ láìpẹ́ fún àwọn tó fẹ́ dojú ìjọba bolẹ̀, a má tó yọ sí wọn- Buhari

Aarẹ Buhari sọ pé àwọn tó n kọjú ìjà sí ìjọba Naijiria má a tó gé ìka àbámọ̀ jẹ

Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi ikilọ sita fún àwọn to fẹ ẹ pa awọn dukia ijọba run.

Ọjọ Iṣẹgun ni aare sọ ọrọ yii lẹyin ipade to ṣe pẹlu alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, lori bi awọn janduku ṣe n kọlu àwọn ọfiisi ajọ naa kaakiri Naijiria.

Aarẹ Buhari sọ pe ojoojumọ ni oun n gba iroyin nípa awọn ikọlu naa, to si daju pe erongba awọn to wa nidi rẹ ni pe ki ijọba yii kuna.

"Ọrọ eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria ti di nkan ti awọn eniyan n sọ kaakiri agbaye.

Buari ni pe: " Ẹnikẹni to ba n lepa ìṣubú ijọba yii, ko ni i pẹ kabamọ. A ti fun wọn ni asiko to. "

Buhari ní oun ranti pe gbogbo ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria ni oun de ṣaaju idibo ọdun 2019, "ọpọlọpọ awọn eniyan lo si ni igbagbọ ninu mi, eto idibo naa si jẹri si".

O ni oun yoo tẹsiwaju lati ma dari Naijiria ni ibamu pẹlu ilana ti ofin la kalẹ.

Aarẹ sọ pe o daju pe ọjọ ori awọn to n siwahu ni awọn ibi kan ni Naijiria kere pupọ lati mọ ibanujẹ ati òfò ẹ̀mí to waye lasiko oogun abẹle ni Naijiria.

"Àwa ti a wa loju ogun fun ọgbọn oṣu, ta a la ogun kọja, yoo dojú kọ wọn pẹlu èdè ti wọn gbọ.

" Ao ni i pẹ fi ọwọ lile mu wọn."

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson Shomolu Bariga ní 'Restructuring'ti bọ́ aṣọ kò bá Omọyẹ mọ́!

Bakan naa ni Aarẹ sọ pe oun ti paarọ àwọn Ọga ologun, ati Ọga ọlọpaa," ao si beere abo lọwọ wọn."

Lori ewu tó wa fun awọn eto idibo lọjọ iwaju, nitori bi awọn janduku ṣe n dana sun ileesẹ INEC, Buhari sọ pe gbogbo nkan ti ajọ naa ba nilo ni oun yoo fun un.

Àkọlé fídíò, Adebayo Murital David: Gbogbo iṣẹ́ tó ń múni là láyé wá láti ọpọlọ ni kìí ṣe agbára

O ni: "ki ẹnikẹni ma ba a sọ pe ao fẹ ẹ lọ, tabi boya a n wa saa kẹta nipo. Ko ni i si awawi kankan fun ijakulẹ. Gbogbo nkan ti INEC ba fẹ, lao fun un."

Alaga INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu sọ fun aarẹ pe ikọlu mejilelogoji ni wọn ti ṣe si awọn ọfiisi ajọ naa lati igba ti idibo gbogboogbo ti waye lọdun 2019.

O ni ipinlẹ mẹrinla si ni awọn ikọlu naa ti waye.

O ṣalaye pe pupọ ninu awọn ikọlu naa waye laarin oṣu meje si asiko yii, ko si si eyi to ni nkankan ṣe pẹlu idibo to kọja.