NECO ti kéde Ebikibina Ogborodi gẹ̀gẹ́ bíi ọ̀gá àgbà fìdíhẹẹ́ tuntun

Oríṣun àwòrán, @thereachfm1049
Awọn alaṣẹ ajọ to n mojuto idanwo aṣekagba ni Naijiria, NECO, ti buwọlu iyansipo ọgbẹni Ebikibina Ogborodi gẹgẹ bii ọga agba fidihẹ fun ajọ naa.
Wọn gbe igbesẹ yii lẹyin ti ọga agba ajọ ọhun tẹlẹ, Godswill Obioma jade laye.
Adari ọọfisi alukoro ajọ naa, Azeez Sani lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan nipinlẹ Niger.
Atẹjade ọhun ni "Iyansipo yii n waye lẹyin iku Ọjọgbọn Godswill Obioma to jade laye lọjọ kinni, oṣu Kẹfa, ọdun 2021."
Ki wọn to kede ọgbeni Ogborodi bii adari fidihẹ tuntu fun ajọ NECO, oun ni adari ẹka to n ri si akanṣẹ iṣẹ ninu ajọ ọhun.
Sani ṣalaye pe inu ipade pajawiri kan ti wọn ṣe ni wọn ti kede orukọ adari agba tuntun naa.
O fi kun pe awọn yan Ogborodi sipo naa lẹyi ti wọn ri pe oun ni adari to ga ju ninu ajọ ọhun lọwọ yii.
Awọn alakoso NECO sọ pe gbogbo eto ti wọn ti la kalẹ ṣaaju iku adari agba ana to di oloogbe ni yoo tẹsiwaju.
- Èmi ò lè káwọ́ gbera kí Nàìjíríà bàjẹ́ lójú mi o, Alaafin sọ̀rọ̀ sókè
- Pope Francis ṣe àyípadà òfin nínú ìjọ Aguda, ó sọ nkan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àlùfáà tó bá ní ìbálòpọ̀ kò tọ́
- Àwọn adigunjalè pa èèyàn bí mẹ́rin, níbi ìkọlu bánkì méjì ni Ikire àti Apomu
- Ìdí rèé tí Twitter kò fi le gbé ìdájọ́ Trump lé Ààrẹ Buhari
Ọmọ ijọba ibilẹ Sagbama ni Ogborodi ti wa, iyẹn lati ipinlẹ Bayelsa.
O kẹkọọ gboye ni fasiti ilu Jos lọdun 1986, o si tun kawe siwaju si nile ẹkọ kan naa lọdun 1999.
- Twitter kò dá sí ọ̀rọ̀ IPOB àti Nnamdi Kanu, bó ṣe wù wa la ṣe lè darí Nàìjíríà- Lai Mohammed
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ ìjọba, dẹndẹ ìyà yóò jẹ orí yín bí Nàìjíríà bá pínyà pẹ́rẹ́, toríi Yoruba Nation! - Oluwo
- Aàrẹ Muhammadu Buhari gba àmì ẹ̀yẹ Adarí tó dára jùlọ
- UNILAG jáwé lọ gbélé ẹ fún àwọn olùkọ̀ méjì tí BBC tú àṣírí wọn nínú fíìmù 'Sex For Grades'
- Ènìyàn 28 kú lẹ́yìn ààrùn Coronaviris láàrín wákàtí 24 ní Nàìjíríà
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
!["NECO Registrar dead": [Professor Godswill Obioma death] and 'how di NECO boss die'](https://ichef.bbci.co.uk/ace/ws/640/cpsprodpb/C1E4/production/_118763694_necoregistrardead-professorgodswillobiomadeathand'howdinecobossdie'.png.webp)
Oríṣun àwòrán, NECO
Ọ̀gá àgbà àjọ tó n mújútó ìdánwó àṣekágbá ní Nàìjíríà (NECO) ọ̀jọ̀gbọ́n Godwill Obioma ti kú
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀bí ṣe sọ Obioma kú ni ọjọ́kọ̀kànlélọ́gbọ̀n òsù karun, ọdún 2021, àjọ NECO kéde ni ọjọ́ Isegun.
Ẹni ọdún mẹ́tàdínláàdọ́rin kú lọ́yìn tí ó ṣe àisàn ránpẹ́, gẹ́gẹ́ bi àjọ NECO se sọ pé àwọn ẹbí olóògbé ṣe sọ.
- Ọdún Oro bẹ̀rẹ̀ ní ìlú Ikorodu
- Adigunjalè ja Ọ̀gá ọlọ́pàá àti ẹni mẹ́ta míràn lólè
- Wo ìdí tí ECOWAS fi dá Mali dúró, tó tún fún àwọn ológun ní gbèdéke láti gbé ìjọba sílẹ̀
- Wo ìdí tó fi ṣeéṣe kí ìjọba àpapọ̀ ó kéde àkọ̀tun ìséde n'ipínlẹ̀ Eko
- A ti rí ọmọ ilé kéú 11 míì nínú àwón tí agbébọn jí gbé ní ìpínlẹ̀ Niger
- Ọjọ́ kínní oṣù kẹfà ni Amotekun yóò bẹ̀rẹ̀ sí ni máa gbógun tàwọn ọ̀daràn àti ajínigbé nílẹ̀ Yorùbá
NECO fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde tí Mustapha fọwọ́ sí, yàtọ sí ìròyìn tó n fò ká pé àwọn agbébọn ló pa ọjọ̀gbọ́n náà
Ààrẹ Muhammadu Buhari fún Obioma sípò ni ọdún tó kọjá, òun sì lò rọ́pọ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n ló rópò Charles Uwakwe ti wọ́n ni ko lọ rọkún nílé nítori ìwà aṣemáṣe lẹ́nu iṣẹ́.
Nínú ìròyìn mííràn tó tún jẹyọ nínú àwọn ìwé ìròyìn abẹ́lé ṣàlàyé pé àwọn agbénipa ló wọ inú ọgbà ilé náà ní kété tó dé láti ilú Abuja.
Ìwé ìròyìn náà ṣàlàyé pé aya rẹ̀ Elizabeth Obioma ló ṣàlàyé yiì fún àwọn akọròyìn.
- Wo àsìkò tí ìdíje "BBNaija lockdown reunion" yóò bẹ̀rẹ̀
- Omoyele Sowore dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn tó fara gba ọta gáàsì tajútajú l'Abuja
- Ẹ kó àwọn ọmọ ọdún 12 títí dé 15 wá fún abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19
- Ìdí tí a fi mú àwọn olùfẹ̀hónúhàn pé wọ́n tẹ òfin ètò ààbò lójú.
- Adigunjalè ja Ọ̀gá ọlọ́pàá àti ẹni mẹ́ta míràn lólè







!["ASUU President": 'Emmanuel Osodeke, ASUU new president' & di issues wit [Federal Government]](https://ichef.bbci.co.uk/ace/ws/660/cpsprodpb/13CE6/production/_118762118_asuupresident'emmanuelosodekeasuunewpresident'-diissueswit-federalgovernment.png.webp)


!["Naomi Osaka": Japanese tennis player [Osaka pull out of French open 2021]](https://ichef.bbci.co.uk/ace/ws/660/cpsprodpb/176A2/production/_118760959_naomiosakajapanesetennisplayer-osakapulloutoffrenchopen2021.jpg.webp)









