Pope Francis, Catholic church: Àwọn àyípadà òfin tí Pope Francis ṣe yóò máa fìyà jẹ àlùfáà tó bá ní ìbálòpọ̀ kò tọ́

Pope

Oríṣun àwòrán, @PopeF

Poopu ìjọ Aguda, Pope Francis, ti buwọlu àwọn ofin ṣíṣe ayipada si awọn ofin ti wọn no ninu ìjọ naa, eyi ti yoo ma fi iya jẹ awọn alufaa to ba ni ibalopọ ti ko tọ ọ.

Àtúnṣe ofin naa tun fidirẹmulẹ pe kii ṣe awọn alufaa to n mojuto àwọn ọmọde , tabi awọn eeyan pataki ninu ìjọ nikan lo n ṣe àṣemáṣe. O ni awọn agbalagba mii naa ma n ṣe bẹ ẹ.

Ọjọ Iṣẹgun ni Poopu kede ilana tuntun naa to wa fun gbogbo ọmọ ijọ Aguda jakejado agbaye.

Àkọlé fídíò, Child Engineer: Olamide Odukọya nílò ìrànlọ́wọ́ láti lọ síléẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ

Lati ọdun 2009 ni ijọ naa ti n sisẹ lori ayipada gboogi si ilana 'Pascite gregem Dei (Ẹ ma a bọ̀ agbo agutan Ọlọ́run), eyi ti Poopu Benedict XVI fi lọlẹ.

Poopu naa kọ iwe pe oun fẹ ki ofin naa wa fun gbogbo eniyan lai fi ìlú tabi orilẹ-ede wọn ṣe, ati pe awọn to ti ṣẹ ẹsẹ ibalopọ ti ko tọ nilo aanu ati ìtọ́ni lọwọ ijọ.

Àkọlé fídíò, Mobile App: Àsìkò tó wu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni olùkọ́ máa jáde wa kọ́ wọn láti inú fóònù wọn

Bawo ni awọn ayipada naa yoo se ri?

Ijọ Aguda yoo fi iya jẹ ẹnikeni to ba ba ọmọdé tabi agbalagba ti ko ni ipá ni ibalopọ, lu jibiti tabi gbiyanju lati fi obìnrin jẹ oye alufaa.

Ti ẹni naa ba jẹ alufaa, o le padanu ipo rẹ, tabi ki wọn o le lọ patapata. Ofin to wa tẹlẹ faramọ pe ìjọ le saanu rẹ.

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....

Iwa ọdaran ni ti alufaa ba n fi fọ́nrán ibalopọ han ọmọde tabi pín iru fọ́nrán bẹ ẹ.

Ijọba le fa arufin le ijọba lọwọ fun ijiya, yatọ si awọn ijiya ti inu ìjọ.

Ijiya kan naa ni fun awọn eeyan pataki ninu ìjọ to ba hu iwa kan naa.

Awọn obinrin ati ipo alufaa

Ninu oṣu Kinni, Poopu Francis yi ofin kan pada ninu ìjọ naa lati fi aaye gba ki awọn obinrin ma a pin oúnjẹ alẹ Oluwa, ati lati ma a ṣe iṣẹ isin lori pẹpẹ.

Poopu sọ pe eyi jẹ ọna lati ṣe iwuri fun awọn obinrin nitori pe wọn n ko ipa pataki ninu ìjọ.

Sugbọn ibi to mọ nìyẹn, nitori pe Poopu sọ pe ọkùnrin nikan lo le di alufaa ninu ìjọ Aguda.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

Igbeyawo laarin ọkùnrin ati ọkunrin tabi obìnrin ati obinrin.

Ko ti i fi oju han boya ilana tuntun yii sọ ohunkóhun nipa igbeyawo laarin iru eniyan kan naa.

Nkan ti a mọ ni pe ni ipari ọdun 2020, Poopu Francis sọ pe oun gbagbọ pe o yẹ ki iru àwọn eeyan yii le ṣe igbeyawo oloruka lábẹ́ ofin.