Muhammadu Buhari ṣe ìfilọ́lẹ̀ ibùdó àwọn arúgbó ní Naijiria
Wo bí àwọn arúgbó ṣe le jẹ́ ìgbádùn ètò tí Buhari fi lọ́lẹ̀ fún wọn.

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe ifilọlẹ ibudo itọju àwọn arugbo ni Naijiria.
Nibi eto naa to waye lọjọ Aje ni Aarẹ Buhari ti sọ pe ibudo naa yoo maa mojuto ọrọ awọn ọmọ Naijiria to ti pe aadọrin ọdun.
- Olorì Damilola fi èpè ránṣẹ́ sí 'bàbá' rẹ̀ to ní kò padà sọ́dọ̀ Aláàfin
- Wo ìdí tó fi ṣeéṣe kí ìjọba àpapọ̀ ó kéde àkọ̀tun ìséde n'ipínlẹ̀ Eko
- Nǹkan kò burú tó báyìí ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn tí mo kọrin pé kí Ọlọ́run bá wa tún Nàijíríà ṣe- Funmi Aragbaye
- Ìdí tí a fi mú àwọn olùfẹ̀hónúhàn pé wọ́n tẹ òfin ètò ààbò lójú.
- Àwọn ọ̀dọ́ lé kábíyèsí jáde láàfin l'Ondo
- Adigunjalè ja Ọ̀gá ọlọ́pàá àti ẹni mẹ́ta míràn lólè
O ni yoo mu ki igbeaye irọrun ba wọn, ti yoo si din wahala kù fun awọn arugbo ni Naijiria.
Asiko diẹ sẹyin ni ile aṣofin fi ontẹ lu ofin naa, eyi ti wọn pe ni 'National Senior Citizens Act of 2017'.
Aarẹ Buhari sọ nibi ifilọlẹ pe ojúṣe ibudo naa wa ni ibamu pẹlu abala ofin 16 (2) (d) ti orilẹ-ede Naijiria.
Nkan ti ofin naa sọ ni pe ki awọn ipinlẹ to wa ni Naijiria ṣe gbogbo nkan to ba wa ni ikapa rẹ lati mu ki igbeaye rọrun fun awọn arugbo.
Ibudo naa yoo ni akọsilẹ orúkọ gbogbo eeyan to ti pe aadọrin ọdun, eyi ti yoo lo lati ṣe eto to yẹ fun wọn.
Lara awọn nkan ti ofin ni ki ajọ naa o ma a ṣe ni idasilẹ ere idaraya ati awọn eto miran ti yoo mu ki awọn arugbo gbadun igbeaye wọn.
- A ti rí ọmọ ilé kéú 11 míì nínú àwón tí agbébọn jí gbé ní ìpínlẹ̀ Niger
- 'Kò sí ààtò fún òfin Sharia àti ẹtọ àwa ẹlẹsìn Islam nínú Oduduwa Republic, a ò gbà!'
- Ọwọ́ ikọ̀ Amọtẹkun ba Mutiu Abdul-Rasheed, afurasí tó ń ta ẹ̀yà ara èèyàn ní Ibadan
- Ilẹ̀ Yorùbá kìí ṣe ibi kátàkárà fún yín, ẹ̀yin àgbà tẹ ń gbárùkù ti ọ̀dọ́ lẹ́yìn láti máa da ìlú rú ẹ sọ́ra - Ẹgbẹ́ YWG
- 'Kò sí ààtò fún òfin Sharia àti ẹtọ àwa ẹlẹsìn Islam nínú Oduduwa Republic, a ò gbà!'
- Èrò Akeredolu ni yẹ́n, àwa aṣòfin á ṣẹ̀sẹ̀ jókòó láti yọ tàǹda kúrò nínú ìrẹsí nígba tó bá ya- Senetọ Ajibola
Awọn ijọba ibilẹ si ni yoo ma a sisẹ pẹlu lati le ni akọsilẹ to tọ́ nipa awọn arugbo to wa.
Ni Naijiria, àwọn to ti le lọdun marunlelọgọta ni ofin da mọ gẹgẹ bi arugbo.
Àwọn eeyan yii si lo jẹ bi ìdá mẹ́ta ninu apapọ awọn ọmọ Naijiria.
- Èrò Akeredolu ni yẹ́n, àwa aṣòfin á ṣẹ̀sẹ̀ jókòó láti yọ tàǹda kúrò nínú ìrẹsí nígba tó bá ya- Senetọ Ajibola
- Wo ohun ti yóò ṣẹlẹ̀ sí obìnrin tó bá fi ojú rí Orò
- A ti rí ọmọ ilé kéú 11 míì nínú àwón tí agbébọn jí gbé ní ìpínlẹ̀ Niger
- Òṣìsẹ̀ 170 tí Ajimobi lé ni Lautech ni ń o gbà padà, owó osù márun wọ́n yoo di sísan- Gómínà Oyo