Nítorí ọ̀rọ̀ Orò, ìjọba ti mọ́ṣáláṣí kan pa lórílẹ̀èdè Benin

Oríṣun àwòrán, Others
Mọṣalaaṣi Jimọ kan lo ti di titipa bayii ni ilu Savè, lorilẹede Olominira Benin.
Adari iṣẹ ijọba ni ilu Savè, Ọgbẹni Déni Obachabi, lo paṣẹ pe ki wọn ti mọṣalaaṣi ọhun pa.
Eyi waye nitori ọrọ kan ti wọn ni Imaamu mọṣalaṣi naa, Ismail Dossoumou, sọ nipa awọn Oloro niluu naa.
Kí ni Ìmáàmù Dossoumou
Gẹgẹ bi ẹsun ti wọn fi kan Imaamu Dossoumou, wọn ni ọkunrin naa sọrọ tako awọn Oniṣẹṣẹ ti ilana ẹsin wọn jẹ Oro ṣiṣe.
Nibi waasi ọjọ Jimọ to kọja ti Imaamu yii ti kirun fun awọn Musulumi ni wọn sọ pe o ti mu ẹnu ba awọn Oloro.
Eyi si lodi si ofin ilẹ naa bi wọn ṣe sọ.
Idi ree ti alabojuto agbegbe Savè naa ṣe gbe igbesẹ titi mọṣalaṣi naa pa ko too di ohun ti awọn Oloro yoo maa fi ẹhonu han lọ sibẹ.
Ìmáàmù ṣàlàyé
Ninu alaye to ṣe lori ọrọ yii, Imaamu Ismail Dossoumou, sọ pe ohun ko ro wi pe o yẹ ki ọrọ naa di ariwo nitori pe inu mọṣalaṣi ti oun ti ṣe waasi fun awọn musulumi loun ti sọ ọrọ naa kii ṣe wi pe oun tọ awọn oniṣẹṣe lọ lati lọ wa ija wọn.
''Mo ni ki Musulumi jẹ Musulumi, ki Oloro jẹ Oloro. Ki Baba Adinni jẹ Baba Adinni, ki Baba Oloro si jẹ Baba Oloro
''Ṣugbọn iwọ ni Baba Adinni, iwọ naa tun ni Oloye Ajanna Oro, ko boju-mu rara, ko daa bẹẹ.
"Ọrọ waasi mi koju bẹẹ lọ. Ọrọ inu Quran ni mo fi ṣe waasi fun awọn to waa kirun Jimọ ninu mọṣalaṣi o. Iyalẹnu lo jẹ fun mi lati gbọ pe mo sọrọ to tako awọn Oloro.''
Imaamu yii sọ pe dajudaju, lara awọn to waa kirun Jimọ ninu mọṣalaṣi naa lo lọọ fi ọrọ naa to alabojuto ilu Savè leti.
O ni awọn to waa kirun le jẹri si i pe inu mọṣalaṣi loun ti ṣe waasi, oun ko lọọ ba awọn Oloro ninu igbo Oro wọn.
Ki ni alabojuto ijọba nilu Savè sọ?
Ninu ọrọ to ba BBC sọ, alabojuto ijọba ni ilu Savè, Ọgbẹni Déni Obachabi,ṣalaye pe ki alaafia le jọba lawọn fi gbe igbesẹ naa.
O ni onilu ko ni laju silẹ ki ilu bajẹ ati pe ijọba ko ni kawọ gbera titi di igba ti ọrọ naa ba di oruyeye ati gbodonroṣọ ko to ṣe ohun to tọ.
gẹgẹbi ọrọ rẹ, oṣu mẹfa gbako ni mọṣalaṣi naa yoo fi wa ni titipa titi ti wọn yoo fi yanju ọrọ naa.














