Ilé aṣòfin Oyo ní kí àwọn tó tàbùkù Soun Ogbomoso lórí rédíò Lagelu FM wá sọ tẹnu wọn

Oríṣun àwòrán, Oba Ghandi Afolabi Olaoye/Facebook
Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti kepe Ọmọwe Doyin Odebowale ati ileeṣẹ redio Lagelu FM lati wa sọ tẹnu wọn lori fọnran eto Bosenlọ, to lu ori itakun ayelujara pa, to waye nileeṣẹ redio naa nibi ti Ọmọwe Odebowale ti sọ pe ko si ọba alade niluu Ogbomoso.
Igbakeji olori ile, Họnọreebu Mohammed Fadeyi, to dari ipejọ naa ṣalaye pe o ṣe pataki fawọn agbohunsafẹfẹ lati maa tẹle ofin to de iṣẹ wọn ki wọn si maa ko awọn alejo to wa sori eto ni ijanu ti wọn ba ti n sọrọ kobakungbe lori afẹfẹ.
Olori ẹgbẹ oṣelu to pọju nile, Họnọreebu Sanjo Adedoyin Onaolapo lo gbe ọrọ naa wa siwaju ile aṣofin ipinlẹ Oyo lẹyin to pe akiyesi ile si awọn ọrọ abuku ati alufansa ti Ọmọwe Odebowale sọ nigba ti o n kopa lori eto Bosenlo nileeṣẹ redio Lagelu FM eyi ti Temidayo Oyeladun ṣagbatẹru rẹ.
Lẹyin apero awọn aṣofin ni ile sọ pe ki igbimọ to n ri si eto iroyin ati ọrọ ijọba ibilẹ pe igbimọ alaṣẹ ileeṣẹ redio Lagelu FM ati Ọmọwe Odebowale pe ki wọn wa sọ tẹnu wọn niwaju ile lori ọrọ naa.
Ninu ọrọ tiẹ, Kọmiṣọna eto iroyin ati ilanilọyẹ, Dotun Oyelade, ti oun naa wa nibi apero ile sọ pe igbesẹ awọn aṣofin dara, o si ṣe pataki lati daabo aṣa ati iṣe Yoruba.
O ni kete ti ile ba ti fi iwe ọrọ naa ṣọwọ si ọfiisi oun loun yoo ṣiṣẹ lori rẹ ni kiakia.
Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ ree
Ọrọ yii bẹrẹ nigba ti Ọmọwe Odebowale n kopa lori eto Bosenlo nileeṣẹ redio Lagelu FM.
Lori eto yii ni Ọmọwe Ọdebowale ti sọ pe ''wọn o ni ọba ni Ogbomoso.
Mi o fẹ sọ pe gomina ologun David Jemibẹwọn tẹlẹri lo jẹ ki wọn maa dade l'Ogbomoso.
Oloye agba Alaafin Oyo ni Soun jẹ tẹlẹ, itan niyẹn kii ṣe pe bo ya mo n bẹnu ẹtu ipo Soun.''
Ọmọwe Odewale fikun ọrọ rẹ lori eto naa pe bi Soun ṣe jẹ Oloye Alaafin to, awọn oniṣẹṣe lo ti n jẹ oye Soun lati ọjọ to ti pẹ.
O ni oun ko le dọbalẹ fun Ọba Ghandi Afolabi Olaoye to wa lori apere Soun ilu Ogbomoso lọwọ yii.
Ọmọwe Odebowale ni oun maa na ọwọ si Ọba Ghandi ni ''nitori kii ṣe ọba lẹyin to kunlẹ siwaju Pasitọ ati oludari ijọ Redeem, E.O. Adeboye.
Arakunrin Ijesa yii lo gbade le e lori, ade ẹgun lo de kii ṣe ade ọba tori Jesu o de ade.''
Ọmọwe Odebowale to jẹ oludamọran Gomina Rotimi Akeredolu nipinlẹ Ondo tẹlẹ ri sọ pe ni kii ṣe tipa tipa ni eeyan fi n jẹ ọba.
Nitori pe ọba ti di oriṣa ni awọn eeyan fi n dọbalẹ fun ọba, nnkan ti a wa n titori rẹ dọbalẹ fawọn ọba yii ni ọpọlọpọ wọn ko ṣe mọ.
''Ẹ ma jẹ ki a maa bawọn sọ pe ọba kan n ṣe ẹsin, ọba o lẹsin kankan yatọ si ẹsin ilu.
Ko oyinbo to de, ẹsin ti ilu ba ni ni gbogbo eeyan n ṣe, ohun si ni ọba n ṣe.
Ole ni gbogbo ọba to ba sọ pe kristẹni tabi musulumi loun, o jọba ko le maa ta ilẹ ni,'' Ọmọwe Odebowale lo sọ bẹẹ.
Soun kan si ileeṣẹ ọlọpaa ati ajọ NBC, Oyeladun ni awọn kan n dunkoko iku mọ oun
Ọluranlọwọ Ọba Ghandi Olaoye lori ọrọ iroyin, Ẹniọwọ Peter Olaleye, fidi rẹ mulẹ pe aafin Soun ti fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa ati ajọ to n ṣamojuto eto igbohunsafẹfẹ lori redio ati tẹlifisan leti lati ṣe iwadii lori iṣẹlẹ naa.
Igbesẹ yii waye lẹyin ti agbohunsafẹfẹ to ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Ọmọwe Odebowale sọ pe awọn eeyan n dunkoko mọ oun lati gbẹmi oun.
O sọrọ naa loju opo Facebook rẹ lati ke gbajare sawọn eeyan wi pe ki wọn ran oun lọwọ tori iṣẹ oun loun n ṣe.
Oyeladun sọ loju opo Facebook rẹ pe awọn eeyan to lẹnu lawujọ n dunkoko pe awọn yoo gba iṣẹ lẹnu oun.
O ni ko si nnkan toun maa fi tọju awọn ọmọ ati iyawo oun ti wọn ba le gba iṣẹ lẹnu oun.
Ẹka to n ṣe iwadii ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleyele niluu Ibadan ti ranṣẹ pe Oyeladun ati Ọmọwe Odebowale to fi mọ Ọmọwe Festus Adedayo toun naa kopa lori eto Bosenlo lọjọ naa.
Iroyin kan to tun tẹ wa lọwọ sọ pe awọn idile marun un to n jẹ oye Soun Ogbomoso n gbero lati gbe gbogbo awọn to tabuku paere Soun lọ sile ẹjọ.
Ẹwẹ, oluranlọwọ Soun lori eto iroyin ni oun pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ redio Lagelu FM lẹyin ti eto Bosenlo naa waye lati fi aidunnu kabiyesi han lori bi Ọmọwe Odebowale sẹ tabuku apere Soun.
''Awọn alaṣẹ Lagelu FM ni awọn yoo ṣatunṣe lori iṣẹlẹ naa, ṣugbọn wọn ko tii ṣe bẹẹ.
Nitori a ko fẹ ṣe idajọ lati ọwọ ara wa lo jẹ ka gbọrọ naa lọ sọdọ awọn ọlọpaa ati ajọ NBC.
Ajọ NBC si ti sọ fun Lagelu FM lati tọrọ aforijin lori eto Bosenlo fun ọsẹ meji, ki wọn si tun kọ iwe si Soun lati tọrọ aforijin,'' Ẹniọwọ Adeleye ṣalaye.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ileeṣẹ redio Lagelu FM ti tọrọ aforijin lọwọ Soun ilu Ogbomoso wi pe awọn gbero lati tabuku apere ọba alade naa gẹgẹ bi ajọ NBC ṣe dari wọn.















