Gómìnà Ìjọba Ogun ní kí ọba tó dá olóyé dọ̀bálẹ̀ níta gbangba lọ rọ́ọ́kún nílé, ọlọ́pàá fọ̀rọ̀ wá Kábíyèsí lẹ́nu wò

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba ipinlẹ Ogun ti paṣẹ pe ki Olorile ti Orile-Ifo, Oba Abdulsemiu Ogunjobi, lọ rọkun nle fun oṣu mẹfa gbako lẹyin ti fidio kan to ṣafihan bi kabiyesi naa ṣe n fiya jẹ Oloye Areola Abraham lu ori itakun ayelujara pa.
Fọnran naa tun ṣafihan bi ọba ọhun ṣe n ṣẹ epe nla nla fun oloye yii ẹni ọdun mẹtalelaadọrin, ti ọkan ninu awọn ẹmẹwa rẹ si n gba baba yii leti nibi to ti wa lori ikunlẹ.
Ohun ti Ọba Ogunjobi sọ ninu fidio naa wi pe Oloye Abraham lẹdi apo pọ pẹlu awọn eeyan kan lati ditẹ mọ oun.
Bi kabiyesi yii ti n ṣepe fun Oloye Abraham lo tun n ṣepe nla nla fun ẹbi baba yii.
Ninu atẹjade ti ipinlẹ Ogun fi sita loju opo X rẹ, oludamọran fun Gomina Dapo Abiodun, lori eto iroyin ati ọgbọn inu, Kayode Akinmade, ṣalaye pe ijọba paṣẹ idaduro Ọba Ogunjobi lẹyin ti kọmiṣọna fun ijọba ibilẹ ati ọrọ oye jijẹ, Họnọrebu Ganiyu Hamzat, ti kọkọ pe kabiyesi naa ati oloye Abraham fun ifọrọwanilẹnuwo.
Ijọba ipinlẹ Ogun sọ ninu atẹjade naa wi pe igbesẹ idaduro Olorile-Ifo ko ṣẹyin awọn ọrọ kobakungbe ati aṣemaṣe ti kabiyesi naa ṣe ninu fidio to lu ori ayelujara pa.
''Lẹyin iwadii to waye lori iṣẹlẹ naa ni ijọba paṣẹ pe ki kabiyesi naa kuro lori apere Olorile ti Orile-Ifo titi igba ti a o fi mọ bo ya ori ade naa jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an tabi ko jẹbi.
Ijọba gbe igbesẹ yii lẹyin to fi ọrọ naa to Igbimọ Egba Traditional Council leti gẹgẹ bi o ṣe wa ni ẹka 52(1) iwe ofin awọn ọba atawọn ijoye ọdun 2021 ni ipinlẹ Ogun.
Ọpọ eeyan lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu ihuwasi ọba Ogunjobi ninu fọnran to lu ori itakun ayelujara pa naa eyi to ṣafihan bi ori ade ọhun ṣe n fiya jẹ Oloye Abraham.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ko sẹni to le sọ pe oun lagbara lori ọlọpaa – Adejobi
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Olorile ti Orile-Ifo, Oba Ogunjobi lọjọ Aje ọjọ kẹta oṣu Keji ọdun yii, lẹyin ti fọnran to ṣafihan bi kabiyesi naa ṣe da Oloye Abraham, ẹni ọdun mẹtalelaadọrin dọbalẹ nita gbangba niluu Ifo lu ori itakun ayelujara pa.
Kabiyesi naa ti a gbọ pe oṣiṣẹ fẹyinti lẹnu iṣẹ ọlọpaa lo jẹ sọ ninu fidio naa pe oun lagbara lori ileeṣẹ ọlọpaa, tori naa oun le ran baba oloye to da dọbalẹ lẹwọn.
Ọkan lara awọn to wa pẹlu kabiyesi naa gba baba yii leti ti o si sọ fun un pe ko dọbalẹ, gẹgẹ bi o ti wa ninu fidio naa.
Amọ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, Muyiwa Adejobi, sọ loju opo X rẹ pe ko si ẹni to lagbara lati dari ileeṣẹ ọlọpaa.
Adejobi to tun fi idi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti pe Kabiyesi Ogunjobi, wọn si ti fọrọ wa a lẹnu wo sọ pe idajọ ododo gbọdọ waye lori iṣẹlẹ naa.
Agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa fikun ọrọ rẹ pe baba ti wọn fiya jẹ yii gbọdọ lanfaani lati ri kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun.
O ni iwa ipa ni ohun ti wọn ṣe si baba oloye Abraham, o si gbọdọ ri idajọ ododo.
Adejobi ni ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ fun baba lati darukọ awọn eeyan yooku ti wọn jọ huwa ipa si i ninu fọnran tu lu ori ayelujara pa yii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ọba tó dá olóyè dọ̀bálẹ̀, fìyà jẹ ẹ́ ní Ifo, Ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe nípa rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọrọ lori fidio kan to lu ori itakun ayelujara eyi to ṣafihan bi afurasi kabiyesi kan ti n ṣẹ epe nla nla ti o si tun fiya jẹ ọkunrin kan ti wọn pe ni Oloye, Ọgbẹni Abraham Areola.
Baba naa ti a gbọ pe o jẹ ẹni ọdun mẹtalelaadọrin ni o ti sọ fun iwe iroyin Punch pe Olorile ti Orile Ifo, Oba Semiu Oginjobi, ni afurasi kabiyesi tawọn eeyan n gbọ ohun rẹ ninu fidio to lo ori ayelujara pa ọhun.
Oloye Areola ti wa sọ fawọn akọroyin pe kabiyesi ti n dunkoko mọ oun lati ṣeku pa oun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori fidio to lu ori ayelujara pa yii
Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ ninu atẹjiṣẹ ori foonu, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa Ogun, Omolola Odutola, sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti ri fidio tawọn eeyan n sọ nipa rẹ naa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣalaye pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ ti fidio ọhun ṣe afihan rẹ lori itagun ayelujara.
Arabinrin Odutola sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo tu iṣu de isalẹ ikoko lori iṣẹlẹ ọhun lai fi igba kan bọ ọkan ninu.
Ohun to ṣẹlẹ ṣaaju
Lopin ọsẹ to kọja ni fidio kan ṣadeedee lo ori ayelujara pa eyi to ṣafihan baba kan to wa lori ikunlẹ ninu fidio naa.
Ninu fidio yii ni ọkunrin ti wọn n pe ni kabiyesi ti sọ pe baba to wa lori ikunlẹ naa wa lara awọn to ditẹ mọ oun.
Kabiyesi naa sọ pe ibi ni baba naa fi san oore ti oun ṣe fun un atawọn oloye mii pada.
Bi baba yii ti n sọ pe oun ko ditẹ mọ kabiyesi yii ni oriade naa n sọ pe oun ṣetan lati ran baba yii lẹwọn.
Ori ade naa tun sọ ninu yii pe oun loun ni ọlọpaa orilẹede Naijiria, tori naa oun lagbara lati baba naa lẹwọn.
Niṣe ni kabiyesi naa n ṣepe rabandẹdẹ rabandẹ pe baba yii ko ni jere ọmọ, ko ni jere aya tori o ditẹ mọ oun.
Bi ẹnikan ṣe gba baba yii leti ni o n sọ wi pe ara oun ko ya.















