Àwọn ohun tó yẹ kí omọ̀ nípà Tems, ọmọ Nàìjíríà tó gba Grammy Awards

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbajumọ akọrin takasufe ni Tems kaakiri agbaye. Bi o tilẹ jẹ wi pe Tems ni ọpọ mọ ọ si ṣugbọn orukọ abisọ rẹ ni Temilade Ọpẹniyi.
Temilade to jẹ orukọ rẹ lo ge kuru si Tems ti o jẹ orukọ itage rẹ bayii.
Lati igba ewe ni Tems ti bẹrẹ orin kikọ lasiko to maa n ṣe ẹkọṣẹ orin pẹlu ẹni to jẹ ọga akọrin fun ile ẹkọ to lọ nigba naa, Ọgbẹni Sosan, iyẹn Dowen College ni ilu Eko lọdun 2011.
Orilẹede UK lo wa pẹlu awọn obi rẹtiti di igba to pe ọmọ ọdun mẹrin ki awọn obi rẹ to kọ ara wọn silẹ ti iya rẹ si pada wa si orilẹede Naijiria.
Iya rẹ lo tọ oun ati aburo rẹ ọkunrin ni agbegbe Badagry ni ilu Eko.
Lẹyin to gba oye imọ ijinlẹ nipa eto ọrọ aje ni fasiti Monash University lorilẹede South Africa, Tems bẹrẹ iṣẹ gẹgẹbi ontaja ori ayelujara nilu Eko.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọdun 2018, o kọwe fi iṣẹ naa silẹ lati gbe orin rẹ akọkọ jade to pe akọle rẹ ni 'Mr Rebel'jade. Lọdun 2020 ni okiki rẹ jade lẹyin ti o darapọ mọ Wizkid ṣe orin 'Essence'.
Oniruuru ami ayẹ lo ti gba kaakiri agbaye fun imọriri awọn orin to ti kọ jade.
Lọdun 2023, Tems gba ami ẹyẹ akọkọ ni Grammy fun ami ẹyẹ 'Best Melodic Rap Performance' pẹlu awo orin rẹ 'Wait For You'eyi to ti lo gbajumọ akọrin agbaye ni, Drake.
Lọdun 2025, ami ẹyẹ mẹjọ ọtọọtọ ni wọn mu orukọ Tems silẹ fun pẹlu "Love Me Jeje" to gba ami ẹyẹ orin to ta lẹnu julọ lati ilẹ Afrika.
Ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ni.
Awọn ọmọ Naijiria to ti gba amin ẹyẹ Grammy Awards ri atawọn ti wọn ti fa orukọ wọn kalẹ tẹlẹ ri

Oríṣun àwòrán, instagram
Burna Boy ati Wizkid gbe ogo orilẹede Naijiria ga lẹyin ti wọn wa lara awọn to gbami ẹyẹ Grammy ninu orin takasufe.
Burna Boy to dantọ julọ lagbaye pẹlu awo orin rẹ to pe ni "Twice as tall," nigba ti Wizkid gba ẹyẹ tirẹ pẹlu ilumọọka olorin ilẹ Amẹrika, Beyoncé ati Blue Ivy.
Akọle orin ti wọn jọ kọ papọ lati gba ami ẹyẹ naa ni wọn pe ni "Brown Skin Girls."
Amọ, awọn alaṣẹ ami ẹyẹ Grammy ti fa awọn olorin kan to jẹ ọmọ Naijiria kalẹ fun awọn ami ẹyẹ Grammy tẹlẹ ri. Orukọ wọn ni wọnyii:
Wizkid

Oríṣun àwòrán, Instagram/ wizkidayo
Ayodeji Ibrahim Balogun ti ọpọ mọ si Wizkid kọkọ pegede fun ami ẹyẹ Grammy pẹlu iṣẹ ajọṣepọ rẹ pẹlu olorin takasufe ilẹ Amẹrika, Drake lọdun 2015.
Ilumọọka olorin ni Wizkid ti ọpọ gbagbọ pe o bẹrẹ iṣẹ orin kikọ lọmọ ọdun mọkanla.
Wizkid di ẹni tu araye n sọ nipa rẹ lagba ile orin lọdun 2011 lẹyin to gbe orin ''Holla at Your Boy'' jade.
Wizkid naa ti darapọ mọ awọn to ti gba ami ẹyẹ Grammy lagbaye lẹyin to gba ami ẹyẹ ọhun fun igba akọkọ.
Orin rẹ to pe ni "Brown Skin Girls" to gbe jade pẹlu gbajugbaja olorin ilẹ Amẹrika, Beyoncé ati Blue Ivy lo fun ni ami ẹyẹ naa.
Burna Boy
Burna Boy tun ni olorin takasufe ni Najiria ti wọn ti fa kalẹ fun ami ẹyẹ Grammy.
Ọdun 2019 ni wọn kọkọ fa Burna Boy kalẹfun ami ẹyẹ Grammylori orin rẹ to pe ni ''Fall Out Boy's Mania.''
Ọdun 2020 ni wọn tun kede Burna Boy fun ẹka awo orin to pegede julọ ti o pe akọle rẹ ni ''African Giant.''
Ṣugbọn Burna Boy pada gba ami ẹyẹ Grammy lọdun 2021 yii pẹlu orin rẹ to pe ni ''Twice as Tall.''
King Sunny Ade

Oríṣun àwòrán, Instagram/sunnyadeofficial
Gbajugbaja olorin Juju, King Sunny Ade ni olorin ọmọ Naijiria akọkọ ti wọn kede orukọ rẹ lara awọn ti wọn mu lati gba ami ẹyẹ Grammy.
Koda igba meji ni orukọ KSA ti jade fun ami ẹyẹ Grammy.
Ọdun 1984 ni wọn kọkọ kede orukọ Sunny Ade fun ami ẹyẹ Grammy pẹlu orin rẹ to pe ni Syncro System ni ẹka orin ibilẹ.
Wọn kede King Sunny Ade fun ami ẹyẹ Grammy lọdun 1999, ni ẹka awo orin to pegede julọ.
Babatunde Olatunji

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Onilu ara, Babatunde Olatunji ni ọmọ Naijiria keji ti iṣẹ orin to yan an laayo gbee de ibi ami ẹyẹ Grammy.
Ọdun 1998 ni wọn kede orukọ Olatunji fun ami ẹyẹ Grammy ni ẹka onilu to pegede julọ julọ lagbaaye.
Wọn bi Ọgbẹni Olatunji ni ilu Ajido ti ko jinna si Badagry nipinlẹ Eko lọdun 1927.
Ọdun 1950 ni Olatunji fi Naijiria silẹ lọ si orilẹede Amẹrika.
Femi Kuti

Oríṣun àwòrán, instagram/femikuti
Olorin Afro, Femi Kuti ni olorin ọmọ Naijiria kẹta ti wọn fa kalẹ fun ami ẹyẹ Grammy.
Wọn fa Femi silẹ fun ami ẹyẹ Grammy lọdun 2003, 2010, 2012 ati 2014.
Ẹka awo orin to pegede julọ ni wọn kede ori Femi to akọle rẹ ni ''Fight to Win'' lọdun 2003.
Ọdun 1962 ni wọn bi Femi niluu London, oun si ni ọmọkunrin akọkọ oloogbe olorin Afro, Fela Anikulapo Kuti.
Seun Kuti
Seun Kuti to jẹ ọkan lara awọn ọmọkunrin oloogbe Fela Kuti to n kọrin jọ ọkan lara awọn olorin ọmọ Naijiria ti wọn fa kalẹ fun ami ẹyẹ Grammy lọdun 2018.
Ẹka awo orin to pegede julọ ni wọn ti fa Seun kalẹ fun ami ẹyẹ Grammy pẹlu orin to pe akọle rẹ ni ''Black Times.''
Seun ni ọmọkunrin Fela to kere julọ, oun lo si n dara ẹgbẹ olorin baba rẹ ti wọn n pe ni Egypt 80.
Chimamanda Ngozi Adichie
Chimamanda Ngozi Adichie ni obinrin akọkọ to jẹ ọmọ Naijiria ti wọn kọkọ kede orukọ rẹ fun ami ẹyẹ Grammy.
Wọn fa Chimamanda kalẹ fun ami ẹyẹ Grammy lọdun 2015 lori ajọṣepọ rẹ pẹlu olorin Amẹrika, Beyonce ti wọn pe orukọ rẹ ni ''Flawless.''
Chimamanda ti ọpọ maa n pe ni CNA jẹ gbajugbaja onkọwe ati ajijagbara fun ẹtọ awọn obinrin.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbajugbaja akọrin takasufe, Temilade Openiyi, ti ọpọ eeyan mọ si Tems ti gbami ẹyẹ Grammy ọlọdanni fun igba akọkọ.
Tems lo gbami ẹyẹ Grammy ni isọri orin ilẹ Afirika to dara julọ pẹlu orin rẹ to pe akọle rẹ ni ''Love Me Jeje.''
Tems la awọn gbajugbaja akọrin takasufe mii bii Burna Boy, Davido, Aṣake, Yemi Alade, Chris Brown mọlẹ lati gbami ẹyẹ naa.
Ni gbọngan Crypto.com Arena niluu Los Angeles lorilẹede Amẹrika ni ayẹyẹ ifami ẹyẹ dawọn akọrin lọla naa ti waye lalẹ ọjọ Aiku ọjọ keji oṣu Keji ọdun yii.
Ninu ọrọ rẹ, Tems ni ''mo dupẹ lọwọ Ọlọrun to fun mi lanfaani lati wa nibi fun ami ẹyẹ Grammy.
Bakan naa ni mo tun dupẹ fun gbogbo eeyan to n ṣiṣẹ pọ pẹlu mi.''
Tems tun lo anfaani naa lati ki mama rẹ ẹni to sọ pe oni ọjọ Aje ọjọ kẹta oṣu Keji ni ọjọ ibi rẹ.
Tems dupẹ lọwọ iya rẹ fun gbogbo nnkan to ti ṣe fun un ati arakunrin rẹ ti wọn jọ jẹ ọmọ iya kan naa.
Ami ẹyẹ ti Tems gba yii ṣapujuwe idagbasoke ati ilọsiwaju ninu iṣẹ orin kikọ fun Tems.
Lọdun 2023 lo kọkọ gbami ẹyẹ Grammy pẹlu akọrin orilẹede Amẹrika, Drake, fun orin kan tawọn mejeeji jọ kọ papọ eyi ti wọn pe akọle rẹ ni 'Wait For You.'
Lọdun 2025, ọna mẹjọ ni wọn ti darukọ orin rẹ ''Love Me Jeje'' fun ami ẹyẹ Grammy ti isọri ilẹ Afirika.
Bakan naa ni wọn tun darukọ orin Tems fun ami ẹyẹ Grammy ni isọri orin R&B pẹlu orin rẹ - "Burning" ati "Born in the Wild'' fun isọri orin to dara julọ lagbaaye.















