Ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa '3rd Party Insurance' àti bí o ṣe lè gbà á

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oriṣiiriṣii ilana ma-da-mi da- ofo ti i ṣe inṣọransi lo wa.
Ohun ti wọn wa fun naa ni pe bi ijamba ba ṣẹlẹ, ti eeyan si ti ba ileeṣẹ adojutofo to n ri si nnkan bayii ni adehun ati ajọsọ nipa sisan owo to yẹ fun wọn, awọn ileeṣẹ naa yoo ba ẹni naa gbọ bukaata ijamba to ba waye.
Ẹni to ṣe inṣọransi ọkọ, ile, ileeṣe, okoowo tabi dukia rẹ mi-in, koda ko jẹ ti ẹmi rẹ lo ṣe, yoo maa sanwo ti wọn la kalẹ fun un lọdọọdun tabi nigba yoowu ti wọn ba fi adehun owo sisan naa si.
Owo naa ni wọn yoo fi ba a tan iṣoro to tori ẹ ṣe e lọjọ ti ijamba ba ṣẹlẹ.
Ni ti Third-party ti ọga ọlọpaa kede yii, ohun to wa fun ni pe bi awakọ kan ba gba ọkọ mi-in to si ba a jẹ, ileeṣẹ adojutofo ti ẹni to daran naa ti sanwo fun ni yoo tun ọkọ naa ṣe.
Bakan naa, bi ijamba ba ṣe ẹni to wa ọkọ pẹlu, yatọ si mọto rẹ ti wọn gbá, ojuṣe ileeṣẹ adojutofo naa ni lati sanwo itọju awakọ naa.
Itọju yii le ma kan ẹni to fi mọto gba mọto mi-in, nigba to ba ti jẹ pe oun lo jẹbi.
Ilana Third-party yii wa fun lati kọ awakọ ni kiko ara ẹni nijaanu ni pópó, lẹyin ti wọn ba ti n sanwo to yẹ fun ileeṣẹ adojutofo ti wọn jọ ni adehun.
Ni bayii to ti waa di dandan fun awọn ọmọ Naijiria gẹgẹ bi aṣẹ ọga ọlọpaa, irufin ni bi awakọ ko ba ni inṣọransi yii.
Bi o se le gba iwe 'Third-party Insurance'
Gbigba Iwe Inṣọransi ni o jẹ ohun to rọrun pupọ lati igba
Ọpọ ileeṣẹ Inṣọransi lo n fun awọn eeyan ni iwe yii fun ọkọ wọn pẹlu owo perete .
Sisan owo yii lo da lori iye ti ileeṣẹ inṣoransi yii ba gbe sita
Gbigbe iwe yii yoo pese iranlọwọ lasiko ti ijamba ba waye fun ọlọkọ.
Ẹ ja fafa lọ fọrukọ silẹ ni ileeṣẹ insọransi to ba sun mọ yin lati le gba iwe yii.
Iléeṣẹ̀ ọlọ́pàá ti ń fi òfin Ìǹṣọ́ráńsì múlẹ̀ l'Eko, Edo àtàwọn ìpínlẹ̀ mí

Oríṣun àwòrán, others
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Akwa Ibom ati Edo ti kede pe wọn ti bẹrẹ si ni mu ọmọ Naijiria to n wa mọto loju ọna ijọba ṣugbọn ti wọn ko ni iwe inṣọransi bẹrẹ lati ọjọ kinni oṣu keji ọdun 2025.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ninu atẹjade kan to fi lede fi idi rẹ mulẹ pe o ṣe koko fun awọn eeyan to n lo mọto niluu Eko lati ni iwe Inṣọransi
O gba awọn eeyan ti wọn ko ti ni iwe Inṣọransi naa pe ki wọn tete lọ gba ti wọn ni kiakia.
Hundeyin ni ẹnikẹni ko to ba kuna si aṣẹ ni o ṣeeṣe ko ri ija ofin, ko dẹ tun san owo itanran fun ijọba.
"Ofin wa fun idabobo awọn awọn ati awọn eeyan mii to n lo oju opopona."
Nipinlẹ Akwa Ibom, Kọmisana fun Ileeṣẹ ọlọpaa, CP Baba Azare, lewaju fun awọn ikọ ọlọpaa lọ si awọn agbegbe Uyo ati Ikot Ekpene lọjọ Satide.
Azare ni igbesẹ yii lo wa ninu akọsilẹ ofin Inṣọransi pe o ṣe koko ki gbogbo eeyan to wa moto ni oju opopona ni iwe inṣọransi ọkọ.
Ipinlẹ Edo naa o gbẹyin rara, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa. Moses Yamu ninu atẹjade kan ni Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ , Betty Enekpen Isokpan Otimenyin n rọ awọn awakọ nipinlẹ naa lati ri daju pe wọn gba iwe inṣọransi naani kiakia nitori o wulo gan an.
Kọmisana ni ẹnikẹni to ba kọ lati gbe iwe yii ni o ri ija ofin ni ọna ti ko nifẹ si rara.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ìǹṣọ́ráǹsì di dandan fún gbogbo ọmọ Naijiria tó ń wa mọ́tò-Egbetokun

Oríṣun àwòrán, @Nigerian Police
Ọga ọlọpaa pata ni Naijiria, Kayode Egbetokun, ti paṣẹ pe gbogbo ọmọ Naijiria to n wa mọto loju ọna ijọba gbọdọ lọọ ṣeto ma-dami-da-ofo ta a mọ si Insọransi (Insurance), fun mọto wọn ki wọn too maa gbe e sojuu popo.
O kere tan, awọn araalu gbọdọ ṣe oriṣi inṣoransi ti oloyinbo n pe ni Third-party, gẹgẹ bi aṣẹ ọga ọlọpaa Naijiria.
Egbetokun fi kun un pe aṣẹ naa ti bẹrẹ lati ọjọ kin-in-ni, oṣu Keji ọdun 2025 yii.
Kí làwọn aráàlú ń wí?

Oríṣun àwòrán, Kayode Egbetokun/Facebook.
Loju opo X ti Egbetokun ti kede ọrọ yii, ero araalu ṣotọọtọ.
Awọn eeyan kan sọ pe asiko didọbalẹ ti o ba kọlu mọto onimọto ti kọja, ko si aaye ẹbẹ mọ, afi ki ẹni to daran tan an.
Awọn wọnyi gba pe ohun to daa ju ni ofin ọlọpaa yii, nitori yoo dena awọn ikọlu ati iwa ta ni yoo mu mi ti awọn awakọ mi-in maa n hu ni popo.
Ṣugbọn ọpọ eeyan lo koro oju si ofin naa, paapaa bo ṣe jẹ pe ẹsẹkẹsẹ ti ọga ọlọpaa kede rẹ naa lo si ti sọ ọ di ofin.
Ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 ni Egbetokun kede ọrọ naa, o si ni o ti dofin lọjọ akọkọ oṣu Keji, 2025.
Awọn mi-in sọ pe ileeṣẹ inṣọransi ki i ṣe ẹtọ ni Naijiria, wọn ni wọn le ma tọju ẹni ti ijamba ṣẹlẹ si.
Fun idi eyi, wọn ni ko yẹ ki ọga ọlọpaa maa fi dandan le e fawọn eeyan lati ṣe e.
Bakan naa la ri awọn ti wọn ni ọna Naijriria ko sunwọn, ijamba le waye nigbakigba. Wọn ni nibi ti ọna ba ti daa ni Inṣọranti ti le jẹ aabo, ki i ṣe ni Naijiria yii.
Ọlọpaa yoo tun maa fi eyi wa ounjẹ si ẹnu wọn ni ero awọn ẹlomi-in.
Wọn ni wọn tun maa da awakọ duro bayii, ti wọn yoo si maa beere iwe inṣoransi, ẹni ti ko ba si ti ni, tiẹ ti ba a niyẹn.
Eyi ati awọn ọrọ mi-in ni awọn araalu n wi, ti wọn si n fi aidunnu wọn han si aṣẹ inṣọransi to ṣẹṣẹ de.














