A ti ń kọ́ àwọn dókítà mí-ìn níṣẹ́ làti rọ́pò àwọn tó ń jápa- Mínísítà ètò ìlera

Bi awọn dokita atawọn oṣiṣẹ eleto ilera mi-in ṣe n japa lọ siluu oyinbo, Minisita fun eto ilera lorilẹede yii, Ọjọgbọn Ali Pate, ti sọ pe awọn ti n kọ awọn mi-in ti yoo gba ipo awọn to n japa.
Ninu ifọrọwerọ kan ti Ọjọgbọn Pate to tun wa fun ọrọ igbayegbadun araalu, ṣe pẹlu BBC lo ti sọ pe bawọn kan tiẹ n japa, awọn iṣi mi-in tun wa ti yoo rọpo wọn.
" Nitori awọn to n japa la ṣe n kọ awọn mi-in niṣẹ iṣegun oyinbo.
Igba ti a ba ti n kọ awọn mi-in, koda bawọn kan n lọ, awọn kan yoo maa wa ti wọn yoo tun maa kọ awọn miran niṣẹ.
" Awọn orilẹede yoku fẹran lati maa gba wọn nitori wọn mọ pe wọn mọṣẹ yii daadaa, nitori a ti kọ wọn daadaa."
Ọjọgbọn Ali Pate lo ṣalaye bẹẹ.
Nigba to n tẹsiwaju, Ọjọgbọn Pate sọ pe bawọn oniṣẹ ilera ṣe n japa ti dinku lẹnu ọjọ mẹta yii.
O ni lati nnkan bii ọdun kan ati oṣu mẹfa sẹyin ni jijapa ti dinku gidi laaarin awọn dokita atawọn oniṣẹ ilera yoku.
Ẹ o ranti pe ọpọ igba ni ẹgbẹ awọn oniṣegun oyinbo lorilẹede yii, Nigeria Medical Association, ti fi ẹhonu han, ti wọn si yanṣẹ lodi nitori ai si itọju ati igbayegbadun ti wọn n beere.
Ai si awọn nnkan naa lo fa a ti ọpọ dokita, nọọsi ati awọn oniṣẹ ilera mi-in fi n japa lọ sawọn ilu oyinbo kiri.
'Lóòótọ́ ni pé àwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì kò tó níléèwòsàn kéréje ní Naijiria'

Nipa bi ọpọ eeyan ṣe gba pe awọn dokita ati nọọsi ki i pọ lawọn ileewosan kereje (Primary Health Centre), Minisita eto ilera sọ pe loootọ niyẹn.
O ni idi niyẹn ti awọn ṣe n bẹ ijọba ipinlẹ ati tawọn ibilẹ, lati sowọpọ pẹlu ijọba apapọ lori ai to oṣiṣẹ ilera yii.
Ọjọgbọn Pate sọ pe, "Idi gan-an niyẹn ti Aarẹ Tinubu ṣe ni ka kọ awọn eleto ilera 1200,000 niṣẹ, ki wọn le maa ṣiṣẹ ninu awọn ileewosan kereje kiri."
O ni bi ẹnikẹni ba lọ sile iwosan kereje kan ti ko si ba dokita tabi nọọsi ti yoo tọju rẹ nibẹ, ko beere lọwọ awọn ara ijọba ibilẹ ibẹ, ko si bi gomina ibẹ pe ki lo n ṣẹlẹ gan-an.
" Ijọba apapọ ti ṣe pupọ ninu ẹ, o le lẹgbẹrun mẹjọ ti wọn ti kọ (8,800), awọn yoku naa ni lati sowọpọ pẹlu wa, ka le jọ ri i pe awọn eeyan Naijiria n ri itọju to peye gba ati ilera pipe."
Ṣíṣe iṣẹ́-abẹ ọ̀fẹẹ́ àti ìtọ́jú pàjáwìrì fún olóyún
Awọn obinrin maa n ba oyun ku lasiko ti wọn ba fẹẹ bimọ ni Naijiria, eyi ri bẹẹ nitori ko si itọju pajawiri to le ran wọn lọwọ.
Ọjọgbọn Pate ṣalaye fun BBC lori eyi, pe ọpọ awọn obinrin to n ku naa ni ko ni owo ti wọn le sare san fun itọju pajawiri ti yoo doola ẹmi wọn.
O ni idi niyi tijọba fi kede iṣẹ abẹ ọfẹ fun awọn oloyun lorilẹede Naijiria.
Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ UNICEF kan ṣe sọ, ida mẹwaa ni iku alaboyun lasiko ibimọ ni Naijiria, ti a ba ka a ni onka bo ṣe n ṣẹlẹ lagbaaye.
Eyi tumọ si pe oloyun 576 lo n ku ninu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan (100,000).
Minisita Ilera sọ pe ko si obinrin to yẹ ko padanu ẹmi rẹ nitori ọmọ to fẹẹ bi, o ni ijọba n sa ipa rẹ lati ṣẹgun biba oyun lọ si ọrun.
Tẹ o ba gbagbe, oṣu Kọkanla ọdun 2024 ni ijọba kọkọ kede eto iṣẹ abẹ ọfẹ fawọn obinrin to loyun lorilẹede yii.
Wọn ni afojusun awọn ni lati din iku aboyun lasiko ibimọ ku.














