Èèyàn méjìlá kú lásìkò táwọn èèyàn ń tẹ ara wọn pa níbi ọdún ìwẹ̀ odò

Aworan awon meji to wa ninu odo

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii ni pe ko din ni eeyan mejila to ti ku nibi ọdun iwẹ̀ odo kan ti wọn maa n ṣe ni India.

Oru mọju owurọ Ọjọruu, ọjọ Kọkandinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 yii ni iṣẹlẹ naa waye nibi ọdun naa, ti wọn n pe ni Kumbh Mela, eyi to waye ni agbegbe Prayagrai.

Ayajọ pataki ti eeyan to le ni miliọnu lọna gọrun maa n kopa ninu rẹ, ni wọn pe ni ọdun iwẹ ni India.

Olootu ijọba Uttar Pradesh, Yogi Adityanath, sọ pe ọpọ awọn mi-in to tun n kopa ninu iwẹ ọdun ibilẹ naa farapa yanna-yanna.

Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀?

Aworan ibi iṣẹlẹ naa ati awọn eeyan to ṣoju wọn
Àkọlé àwòrán, Aworan ibi iṣẹlẹ naa .

Gẹgẹ bi awọn to ṣoju wọn ṣe wi, laaarin aago kan oru si aago meji ni ijamba ọhun ṣẹlẹ.

Wọn ṣalaye fun BBC pe awọn kan ninu awọn akopa ninu iwẹ ibilẹ naa n gbiyanju lati fo ori pepele tawọn ọlọpaa fi da oju ọna.

Ero ọkan awọn eeyan naa ni lati kọja sibi kan ti wọn n pe Sangam Nose, nibi ti odo ti wọn bọwọ fun ju ni India, Ganges, ti pade awọn odo alagbara meji mi-in, Yamuna ati Saraswati.

Nibi ti wọn ti n gbiyanju naa wọn ti n ti ara wọn ti wọn si tẹ ara wọn pa.

A gbọ pe Ọjọruu ti ijamba ṣẹlẹ yii ni wọn ya sọtọ bii ọjọ ironu nipa aye ẹni.

Awọn alaṣẹ eto naa sọ pe eeyan to le ni ọgọrun-un miliọnu (100 million)ni yoo wa sibi ayẹyẹ naa lonii Ọjọruu.

Ati pe awọn eeyan miliọnu marundinlogoji (36million) ni wọn ti wẹ ni nnkan bii aago mẹwaa ilẹ India.

Eyi ti wọn ka kun ọba iwe ni wọn pe ni 'Shahi snan', to tumọ si iwe ọmọ ọba.

Wọn yoo kun eeru si ara wọn, wọn yoo si ki ori bọ odo lọ.

Awọn to wa nidii eyi ti kọkọ ni awọn ko ni i ṣe e mọ lọdun yii, ṣugbọn wọn pada pinnu lati lọ si Sangam. Wọn ni awọn yoo kan fi ọgbọn ṣe e ni.

Ìdí tí ìtẹra-ẹni-pa fi máa ń sábà ṣẹlẹ̀ n'India

Aworan obinrin kan ti wọn dimu lẹyin iṣẹlẹ naa

Ko ti i ju oṣu mẹfa lọ ti awọn kan tẹra wọn pa nibi eto ijọsin kan to waye ni Tirupati, nipinlẹ Andhra Pradesh. Eeyan to le lọgọfa (120) lo ku nigba ti wọn tẹra wọn pa.

Akọsilẹ ijọba India paapaa sọ pe ẹẹmẹtadinlaaadọta igba (47) ni itẹra ẹni pa waye ni India ni 2021 si 2022.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, apọju ero ni wọn lo n fa itẹra ẹni pa naa, eyi ti wọn maa n gbe kalẹ nitori ẹsin, ọdun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Aiṣe eto to yẹ ṣiwaju ayẹyẹ, lilo ibi to kere ju fun ọpọ ero, ai si ọna miran ti awọn eeyan le gba jade bi ijamba ba de, tun jẹ awọn idi mi-in ti wọn lo n fa itẹra ẹni pa ni India.

Àwọn èèyan ṣì ń tẹ̀síwájú nínú ìwẹ̀ láì wo ti àwọn tó kú

Aworan awọn eeyan to n ṣe akọsile awọn ohun to sọnu nipi iṣẹlẹ naa

Oríṣun àwòrán, Getty image

Àkọlé àwòrán, Aworan awọn eeyan to n ṣe akọsile awọn ohun to sọnu nipi iṣẹlẹ naa

Gẹgẹ bi akọsilẹ ijọba lati Uttar Pradesh ṣe wi, ọpọ eeyan lo ṣi n wẹ iwe odo naa lọ lẹyin iṣẹlẹ iku yii.

Eeyan miliọnu mẹtadinlogun (17, million) ni wọn ti wẹ iwe odo to jin laaarọ Ọjọruu naa, ni nnkan bii aago mẹfa owurọ awọn India.

Bakan naa ni awọn alaṣẹ sọ pe o ti to eeyan miliọnu lọna igba (200 million) ti wọn ti wẹ ni Kumbh Mela latigba ti ọdun naa ti bẹrẹ lọjọ kẹtala, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025.

Wọn ni ireti awọn ni pe yoo to irinwo miliọnu eeyan (400million) ti yoo wa sibi ayẹyẹ ọlọjọ marundinlogoji naa.

Àwọn aráàlú ń retí ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ ìjọba

Aworan iya ti ko ri awọn ẹbi rẹ mọ nibi iṣẹlẹnaa
Àkọlé àwòrán, Aworan iya ti ko ri awọn ẹbi rẹ mọ nibi iṣẹlẹ naa

Lasiko ti a n kọ iroyin yii, o ti le ni wakati mẹfa ti itẹnipa naa ti waye, ṣugbọn ijọba India ko ti i sọ nnkan kan lori rẹ.

Awọn araalu to ba BBC sọrọ ṣalaye pe awọn n reti ohun ti ijọba yoo sọ lori rẹ.

Ṣugbọn Yogi Adityanath, olootu ijọba Uttar Pradesh, kọ si oju opo X rẹ laaarọ oni pe:

''Ẹ wẹ iwe yin leti odo to ba sunmọ yin, ẹ ma gbiyanju lati lọ si igi imu Sangam.

''Awọn eeyan n wẹ iwẹ wọn pẹlu alaafia leti odo Sangam. Ẹ ma da awọn to n gbe ahesọ kiri lohun.''

Ohun ti awọn eeyan n beere ni pe ewo gan-an ni ahesọ ti Yogi n sọ, nigba to jẹ pe ọpọ eeyan ni wọn padanu awọn ẹbi wọn ti wọn ko si ti i ri wọn.