Wo ohun mẹ́jọ tí wà á ṣe tí táńkà epo bá ṣubú, tí ìbúgbàmù iná sì wáyé

Àkọlé fídíò, Wo ohun mẹ́jọ tí o le è ṣe tí táńkà epo bá ṣubú, tí ìbúgbàmù iná sì wáyé
Wo ohun mẹ́jọ tí wà á ṣe tí táńkà epo bá ṣubú, tí ìbúgbàmù iná sì wáyé
Tanka to gbina

Ọba oke mase jẹ ka rin arinfẹsẹsi ni adura ti ẹda kọọkan maa n gba lojoojumọ to ba n jade nile.

Amọ nigba miran, awọn eeyan kan maa n se kongẹ ibi ati ijamba ninu irinajo wọn eyi to maa n tete da ẹmi wọn legbodo tabi sọ wọn di alaabọ ara.

Ọkan ninu iru awọn ijamba abi isẹlẹ ibi yii ni ki tanka to gbe eroja epo bu gbamu lojiji laarin ero.

Irufẹ ọpọ isẹlẹ yii lo ti waye ni Naijiria, ko si fẹrẹ si osu kan, ti a ko ni gbọ pe tanka epo subu, tabi danu, ti ina yoo si sọ lojiji.

Isẹlẹ naa ko pin si agbegbe kan nilẹ Naijiria, bo se n waye lẹkun Ariwa, naa lo n awye lẹkun guusu, ti ọpọ ẹmi si n sofo sinu awọn isẹlẹ naa.

Lati ọdun 2009, o le ni ẹgbẹrun meji ọmọ Naijiria to ti ba isẹlẹ ibugbamu tanka epo lọ, ti ọpọ eeyan miran si di alaabọ ara nitori agbako naa.

Bakan naa ni ọdun 2025 ti a sẹsẹ bẹrẹ yii, isẹlẹ tanka epo to n subu, to si n bu gbamu ti pọ yanturu, tu eeyan to le ni ọgọrun si ti ba isẹlẹ naa lọ.

Idi ni pe ọpọ eeyan kii mọ ohun to yẹ ki wọn se lasiko ti ibugbamu ba waye ni ẹgbẹ wọn, ti ọpọ eeyan miran yoo si maa gbọn epo to n da silẹ latinu awn mọto yii.

Awọn isẹlẹ ibugbamu yii ati ọpọ ẹmi to n ba rin, lo n kọ BBC Yoruba lominu, idi si ree ti a se kọ iroyin idlanilọyẹ yii lati jẹ ki awọn eeyan mọ ohun to yẹ ki wọn se ti ibugbamu ba waye.

Tanka epo gbina

Wo ohun to yẹ ki o se ti ibugbamu tanka epo ba waye lẹba rẹ:

  • Farabalẹ lati wo ohun to n sẹlẹ ni ayika rẹ ati ibi to le ja si
  • Mase dara pọ pẹlu awọn eeyan miran lati gbọn epo bẹntirolu to ba n danu lati inu tanka epo to subu
  • Mase duro lati ya fọto isẹlẹ naa tabi se fidio rara
  • Mase duro lati ba ẹnikẹni rojọ nibi isẹlẹ naa lori ohun to n waye ọhun
  • Ti o ba n wa ọkọ lọwọ lati i ibugbamu naa waye ni ayika to wa, tete fi ọkọ rẹ silẹ, ki o si sara kuro nibi isẹlẹ naa jinna-jinna
  • Kan si ajọ panapana ati ajọ to n dena isẹlẹ pajawiri NEMA lati fi isẹlẹ naa to wọn leti
  • Ni kete ti ọkọ agbepo naa ba si ti gbina, fun awọn osisẹ panapana laaye lati sisẹ wọn bo se yẹ lai yọ wọn lẹnu
  • Pe fun iranlọwọ awọn osisẹ eleto ilera, ki o si tun ran awọn eeyan miran lọwọ lati okeere, ti aabo ti wa fun ọ, ti o duro si.