Kí ló ń fa ìfànfà láàárín àwọn Alfa àti Wasiu Ayinde, tí Kwam 1 ṣe kọ̀ láti tọrọ àforíjìn?

Wasiu Ayinde, Akeugbagold, Sulaiman Onikijipa

Oríṣun àwòrán, Wasiu Ayinde, Akeugbagold, Sulaiman Onikijipa/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbajúgbajà olórin Fuji nnì, Wasiu Ayinde tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí K1 De Ultimate ti kọ̀ láti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn Alfa lórí ọ̀rọ̀ tó sọ ṣáájú ètò ìsìnkú ìyá rẹ̀.

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kìíní ọdún 2025 ni ìyá K1, Alhaja Halimah Anifowoshe jáde láyé lẹ́ni ọdún márùnlélọ́gọ́rùn-ún tí wọ́n sì ṣe àdúrà Fidau fún ìyá lọ́jọ́ Kẹrìnlélógún oṣù Kìíní.

Ṣáájú ètò ayẹyẹ Fidau ọ̀hún ni fídíò K1 kan gba orí ayélujára tó sì ń fa awuyewuye pàápàá láàárín àwọn Alfa.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé K1 nínú fídíò náà níbi tó ti ń bá èèyàn kan sọ̀rọ̀ pé gbogbo àwọn Alfa wá jòkòó sí ilé òun láti ìgbà tí ìyá òun ti kú dípò kí wọ́n lọ sí ilé bàbá òun.

Ó ní "àwọn Alfa wọn ò ríbẹ̀, ilé bàbá mi ní Fidipote, àwọn Alfa ò lọ síbẹ̀, ibi ni gbogbo wọn wá ṣe kíni, ni wọ́n wá ganu sí."

‘Ganu sí’ tí Wasiu Ayinde sọ yìí bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Alfa nínú, tí wọ́n sì ní ó ọ̀rọ̀ tàbùkù àwọn.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tú ọ̀rọ̀ náà sí pé níṣe ni Wasiu Ayinde ń pe àwọn Alfa ní elébi àti pé nítorí ìjẹkújẹ ni wọ́n ṣe ń lọ sí ilé rẹ̀ láti ìgbà tí ìyá rẹ̀ ti kú.

'Mi ò ní tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn Alfa, mi ò ṣẹ̀ wọ́n'

Èyí ló mú kí gbajúmọ̀ àgbà Alfa, Mufty Ilorin, Sheikh Sulaiman Faruq Onikijipa níbi ayẹyẹ Fidau ọjọ́ mẹ́jọ ìyá náà sọ fún K1 pé kó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn Alfa fún ọ̀rọ̀ tó sọ náà.

Sheikh Onikijipa ní òun mọ̀ pé K1 kò lè tàbùkù àwọn Alfa nítorí ìfẹ́ tó ní sí wọn àti pé àwọn tó ń gbé ọ̀rọ̀ náà kiri lórí ayélujára ló ń fa ọ̀rọ̀ náà gùn.

Nígbà tó fèsì, K1 ní òun kò ní tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni nítorí òun kò ṣẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi kan òun.

Ó ní òun tí òun bá ti bẹ̀bẹ̀, ó túmọ̀ sí pé òun gbà pé òun ṣe nǹkan tí wọ́n fẹ̀sùn rẹ̀ kan òun, tó sì jẹ́ pé òun kò ṣe nǹkan náà.

"Àwa ò kàwé ṣùgbọ́n àwọn tó kàwé pọ̀ láàrin wa... tí èèyàn bá sọ pé ẹ má binú túmọ̀ sí pé èèyàn gbà pé òun jẹ̀bi ni, kò sì ṣẹlẹ̀, kò lè ṣẹlẹ̀, kò sí ìdí tí mo fẹ́ fi sọ pé kí ẹnikẹ́ni má bínú.

"Àwọn èèyàn ló ń gbé ìròyìn kiri lórí ayélujára... kí àwọn tó ń gbé ìròyìn náà kiri mú ẹ̀rí wọn jáde, ẹ jẹ́ ká máa ṣe Fidau ìyá mi lọ."

Kò sí bó ṣe le wù kí inú máa bí K1 tó, ó yẹ kó tọrọ àforíjì ní ìjókòó Fidau - Akeugbagold

Sheikh Taofeeq Akeugbagold

Oríṣun àwòrán, Sheikh Taofeeq Akeugbagold/Facebook

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ìdáhùn K1 yìí kò tẹ́ àwọn Alfa lọ́rùn rárá, tí ọ̀pọ̀ wọn sì ń fapá jánú pàápàá lórí ayélujára.

Ọ̀kan lára àwọn Alfa tó ti sọ̀rọ̀ lórí ìfaǹfà yìí nínú fídíò kan tó wà lórí ìkànnì Facebook rẹ̀ ni Sheikh Taofeeq Akeugbagold.

Sheikh Akeugbagold ní ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún òun nígbà tí òun rí fídíò níbi tí K1 ti sọ pé àwọn Alfa wá ganu sí ilé òun lẹ́yìn tí òun kúrò ní ilé rẹ̀ tán.

Akeugbagold ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kọ̀rọ̀ yàrá ni Wasiu Ayinde ń bá èèyàn kan sọ nínú fídíò àkọ́kọ́ tó gba orí ayélujára ṣùgbọ́n èsì tí K1 fọ̀ nígbà tí Sheikh Onikijipa ń bá a sọ̀rọ̀ kò da rárá.

Ó ní kò sí bí ó ṣe lè wù kí ọ̀rọ̀ náà lè máa bíi nínú tó, ó ní ó yẹ kó bọ̀wọ̀ fáwọn Alfa tó wà lórí ìjókòó níbi Fidau náà kó sì fi tọrọ àforíjì lọ́wọ́ wọn.

Lẹ́yìn náà ló gba K1 nímọ̀ràn láti ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, máa ṣe àdúrà àti sàárà fáwọn òbí rẹ̀ kí arayé má ṣe kà-á-tán rẹ̀ lẹ́yìn tí ìyá rẹ̀ ti jáde láyé.

Ó fi kun pé kó máa kó àwọn ẹbí rẹ̀ pọ̀ , kó ri dájú pé àwọn okùn ẹbí kò ti ọwọ́ rẹ̀ bọ́.

Ó tún sọ fún K1 láti jìnà sí ìbínú, kó sì máa ṣọ ọ̀rọ̀ sọ nítorí ọ̀rọ̀ lágbára púpọ̀.

Bákan náà ló ní àwọn èèyàn nílò láti ṣọ́ra fún gbígbé àwọn ìròyìn tó lè fa awuyewuye tàbí ìfaǹfà láàárín àwọn èèyàn.