Èèyàn mọ́kànlá nínú ìdílé kan ṣoṣo kú sínú ìbúgbàmù táńká epo

Níṣe ni àwọn ẹbí Nwaji ní Abofia-Agbaja, ìpínlẹ̀ wà nínú ìbànújẹ́ bí táńkà epo tó gbiná ní agbègbè Ugwu Onyeama, ìpínlẹ̀ Enugu ṣe gbẹ̀mí èèyàn mọ́kànlá nínú ẹbí náà lọ́jọ́ kan ṣoṣo.
Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń rí sí ètò ìrìnnà ojú pópó, FRSC ṣe sọ, èèyàn méjìdínlógún ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná náà lọ àmọ́ èèyàn mọ́kànlá nínú àwọn èèyàn náà ló jẹ́ ẹbí Nwaji, ìpínlẹ̀ Ebonyi.
Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní, ọdún 2025 ni táńkà agbépo kan ṣubú tó sì fa ìjàmbá iná ní ìpínlẹ̀ Enugu.
Èèyàn kan láti ìdílé náà, Ikechukwu Nwaji ṣàlàyé fún BBC bí ìjàmbá iná náà ṣe gbẹ̀mí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àtàwọn ẹbí rẹ̀, tó fi mọ́ àwọn èèyàn mẹ́ta míì.
Ó sọ pé "ẹ̀gbọ́n mi, Nwaji Jeremiah Uchechukwu, ìyàwó rẹ̀ Eucheria Nwaji àtàwọn ọmọ wọn mẹ́fà, àbúrò mi, àtàwọn òṣìṣẹ́ wọn méjì ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ iná náà lọ."
Ikechukwu ṣàlàyé pé Uchechukwu ń kó àwọn ẹbí rẹ̀ láti ìpínlẹ̀ Anambra lọ sí ìlú àwọn ní ìpínlẹ̀ Ebonyi fún ètò ìsìnkú bàbá àwọn kí wọ́n tó pàdé ìjàmbá iná ní ìpínlẹ̀ Enugu.
Ó ní orí ìrìnàjò yẹn ni wọ́n wà kí wọ́n tó kó sọ́wọ́ ọkọ̀ agbépo tó dá ẹ̀mí gbogbo wọn légbodò ní ìpínlẹ̀ Enugu.
Ikechukwu rọ ìjọba láti dènà àwọn ọkọ̀ agbépo àtàwọn ọkọ̀ ńlá láti máa rìn ní ojú ọ̀sán, pé alẹ́ nìkan ló yẹ kí wọ́n máa rìn lójú pópó.
Bákan náà ló tún rọ ìjọba láti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn lórí ìsìnkú èèyàn mọ́kànlá tó jáde láyé náà.
Àjọ tó ń rí sí ìrìnnà ojú pópó ní Nàìjíríà, FRSC ní yàtọ̀ sí èèyàn méjìdínlógún tó jáde láyé, àwọn mẹ́wàá míì ló tún farapa nínú ìjàmbá náà.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló ń wáyé láàárín ọ̀sẹ̀ kan tí ọks agbépo tó gbiná ṣokùnfà ikú èèyàn méjìdínlọ́gọ́rùn-ún (98) ní ìpínlẹ̀ Niger.

Tánkà epo bẹntiró tó gbiná gbẹ̀mí èèyàn méjìdínlógún ní Enugu
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe o kere tan, eeyan mejidinlogun lo ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti tanka epo bẹntiro kan gbina loju ọna marosẹ Enugu si Onitsha.
Iroyin ni ṣe ni ọkọ agbepo naa takiti lẹyin ti ijanu rẹ kọṣẹ, eyii to mu ki epo inu rẹ danu, to si gbina.
Gomina Peter Mbah ti yọju sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, o si sọ pe o ba oun ninu jẹ gidi.
O fi kun pe awọn to farapa nibẹ ti n gba itọju nile iwosan, ijọba oun yoo ṣi ṣe gbogbo ohun to yẹ lọna ati dena irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lara awọn igbesẹ to ni ijọba oun yoo gbe lati dena iṣẹlẹ bẹẹ ni ṣiṣe atunṣe awọn opopona ijọba to ti bajẹ ati lati ri daju pe awọn tanka epo n tẹle ilana to yẹ fun iṣe wọn.
Mbah sọ pe iṣelẹ naa gba omi loju oun, lẹyin naa lo ba mọlẹbi awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ atawọn to farapa kẹdun.
Lẹyin naa lo ke si adari ajọ FRSC ati kọmiṣọna fun eto irina lati ri daju pe gbogbo ọkọ to ba n ko ohun to le gbina nipinlẹ naa ni irinṣẹ to n ṣe iranwọ fun ijanu ọkọ ninu ọkọ wọn lọna ati dena irufẹ ijamba ọhun lọjọ iwaju.
O ni "A ṣẹṣẹ bẹrẹ iwadii ni, awọn ọlọpaa atawọn agbofinro mii ti n ṣiṣe lori rẹ, a fẹ wa kulẹkulẹ ohun gan to ṣojunfa ijamba naa ni pato."
Amọ ṣa, ajọ FRSC sọ fun gomina naa pe ijanu ọkọ agbepo naa to kọṣẹ lo ṣokunfa ijamba ọhun.
Kii ṣe igba kọkọ ree ti irufẹ iṣẹlẹ bayii yoo gbẹmi eeyan ni Naijiria, paapaa lẹnu lọlọ yii.
Lọjọ kejidinlogun, oṣu Kinni. ọdun 2025 ti a wa yii ni eeyan 86 padanu ẹmi wọn nibi ti wọn ti n gbọn epo bẹntiro ninu ọkọ to danu nipinlẹ Niger.
Bẹẹ naa ni eeyan marun un jade laye nigba ti tanka epo ti ijanu oun naa kọṣẹ gbina ni Agbor, ipinlẹ Delta.
















