Àwọn tó ń wa kùsà láìtọ́ ló ń kó Boko Haram àti ISWAP wọ ilẹ̀ Yorùbá - Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Gani Adams
Aare Ona-Kakanfo ilẹ̀ Yorùbá, Iba Gani Adams ní gbogbo ìgbìyànjú ni òun ń sà láti ri dájú pé gbogbo ìwà ìjínigbé àti ìṣekúpani kò rí ààyè ní ilẹ̀ Yorùbá.
Gani Adams nígbà tó ń bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ gba ẹnu agbẹnusọ rẹ̀, Kehinde Aderemi ṣàlàyé láti ìgbà tí àwọn ti ń kẹ́fín pé àwọn ikọ̀ Boko Haram àti ISWAP ti ń yawọ ilẹ̀ Yorùbá ni àwọn ti ń ké gbàjerè sáwọn ìjọba láti wá ọ̀nà àbáyọ sáwọn ìṣòro náà.
Ó ní èyí ló mú òun gbé ìgbìmọ̀ kan kalẹ̀ láti tí yóò máa rí sí ètò ààbò ilẹ̀ Yorùbá láti wá ojútùú sọ̀rọ̀ ààbò.
Aderemi ṣàlàyé pé èyí ló mú Gani Adams kàn sí gbogbo àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá pé kí wọ́n gba òun láàyè láti wá báwọn dásí ọ̀rọ̀ ààbò kí àwọn le ṣe àṣeyè tí alákàn ń ṣepo.
Ó ní Gani Adams ń fọwọ́ sọ̀yà pé gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ti pe òun ni òun ṣetán láti dáwọn lóhùn nítorí ààbò ilẹ̀ Yorùbá jẹ òun lógún.
Ó wòye pé àwọn tó ń wa kùsà lọ́nà àìtọ́ láwọn ilẹ̀ Yorùbá ló ń fi ọgbọ́n kó àwọn agbéṣùmọ̀mí wọ ilẹ̀ Yorùbá fún ìmọ̀ ara wọn nìkan àti láti máa rí iṣẹ́ ibi wọn ṣe.
Ẹ kúrò nílẹ̀ Yorùbá tàbí kí ẹ jáde láyé - Gani Adams fọnmú mọ́ Boko Haram lọ́wọ́
Láti bíi ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn ni àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Yorùbá kan ti ń fọnrere lórí ààbò ilẹ̀ Yorùbá.
Àwọn àgbààgbà yìí ń kọminú pé àwọn ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí pàápàá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram àtàwọn ISWAP ti ń yawọ ilẹ̀ Yorùbá.
Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Ààrẹ̀ ona-kakanfo ilẹ̀ Yorùbá, Iba Gani Adams ti rọ àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá láti wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí nípa ètò ààbò ní agbègbè kóówá wọn.
Àrọwà Gani Adams yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde kọminú lórí bí àwọn agbébọn ṣe ń ya kúrò ní ẹkùn àríwá wọ gúúsù Nàìjíríà.
Gómìnà Makinde ti ṣáájú ké gbàjarè pé àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá nílò láti tètè mójútó ọ̀rọ̀ náà kó tó di ohun tí apá kò ní ká mọ́.
Ìdí nìyìí táwọn àgbààgbà ilẹ̀ Yorùbá fi ń ṣèkìlọ̀, tí wọ́n sì ń sọ fún àwọn agbéṣùmọ̀mí náà láti tètè kúrò ní ilẹ̀ Yorùbá tàbí kí àwọn kojú oro sí wọn.
Àtẹ̀jáde tí olùrànlọ́wọ́ pàtàkì lórí ìròyìn sí Gani Adams, Kehinde Aderemi fi léde rọ àwọn gómìnà láti má kọ etí ikún sí ìkìlọ̀ náà.
'Mo ṣetán láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn gómìnà láti ri pé ààbò tó péye wà nílẹ̀ Yorùbá'
Ààrẹ ona-kakanfo náà ṣàlàyé pé àwọn tó ń wa kùsà ní ẹkùn gúúsù Nàìjíríà ló ń fi àwọn agbéṣùmọ̀mí náà pamọ́ ní ibùba wọn.
Gani Adams wòye pé ọ̀rọ̀ ètò ààbò jẹ́ ìpèníjà ńlá tó ń bá Nàìjíríà fínra àti pé láti ọdún tó kọjá ni òun ti ń pe àkíyèsí àwọn gómìnà sí ọ̀rọ̀ náà àmọ́ tí wọn kò ṣe ohunkóhun sí ìpè òun.
Ó ní àwọn ti ṣèpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ òun, ẹgbẹ́ OPC, àtàwọn ikọ̀ tó ń rí sí ààbò ilẹ̀ Yorùbá ìyẹn South-West Security Stakeholders' group.
"Nǹkan tó ń mú àwọn èèyàn láti àréwà máa yawọ Ilesha àti Ile Ife ní ìpínlẹ̀ Osun kò ṣẹ̀yìn ìwakùsà tó ń wáyé ní àwọn ìlú náà.
"A ti ṣàwárí àwọn ibùdó kan tàwọn ará àríwá tó wà níbẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀rún ọgbọ̀n nínú àwọn igbó ní Ilesha àti Ile-Ife. Wọ́n ti sọ àwọn igbó náà di ìlú àmọ́ tí kò sí Yorùbá kankan ntó ń báwọn gbé ibẹ̀.
"Ọ̀pọ̀ àwọn agbègbè tó wà ní ìlú Ilesha ni àwọn tó ń wakùsà ti gba gbogbo rẹ̀ tán , ó rọrùn fáwọn tó ń wa kùsà yìí láti fi àwọn Boko Haram àti ISWAP sí abẹ́ wọn láìsí ìmọ̀sí ẹnikẹ́ni.
"Mo ti kọ̀wé sí gbogbo àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá, mo ṣetán láti ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú wọn lórí ààbò gbogbo ilẹ̀ Yorùbá pátápátá nítorí gbogbo wa la jọ gbọdọ̀ jọ ṣiṣẹ́ papọ̀."
Gani Adams ní àjọṣepọ̀ ti ń wà láàárín OPC àti ikọ̀ Amotekun àti pé ẹ̀ṣọ́ ààbò tí iléeṣẹ́ òun ń ṣàkóso yóò máa ṣe àtìlẹyìn fún OPC àti Amotekun láti ri pé ètò ààbò tó gbọ́pọn wà nílẹ̀ Yorùbá.
Ó ní ohun tó dájú ni pé àwọn gómìnà kò lè dá iṣẹ́ náà ṣe tí àwọn náà sì ti ṣetán láti kún wọn lọ́wọ́ lójúnà àti ri pé wọn kò gba àwọn agbébọn àti àwọn ajínigbé láàyè sọ ilẹ̀ Yorùbá di ilé.
Gbogbo ibùba àwọn agbébọn la mọ̀ – Àwọn ọdẹ
Ní ìpínlẹ̀ Oyo, ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn ọdẹ Soludero, Oba Nureni Akintola Anabi sọ pé gbogbo àwọn ọdẹ tó wà ní ìpínlẹ̀ náà ló mọ ibi tí àwọn àgbébọn náà ń fara pamọ́ sí, táwọn sì ti ṣetán láti lé gbogbo wọn kúrò tí àwọn bá rí àtìlẹyìn tó péye.
Ó ní gbogbo àwọn inú àti ìfun inú igbó tó wà ní ìpínlẹ̀ Oyo ni àwọn mọ̀ àti pé àwọn ń retí kí gómìnà Seyi Makinde kàn sí àwọn lórí ọ̀nà tí wan lè gba ṣe ìrànlọ́wọ́.
Anabi ní ẹ̀ṣọ́ ààbò NSCDC ti kàn sáwọn lórí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà láti ṣàwárí àwọn agbébọn náà kúró nínú igbó.















