Àwa ọmọ Yoruba kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àṣà wa parun, ayé ti ń fi ọwọ́ rọ́ wa sẹ́yìn – Obasanjo

Oríṣun àwòrán, @Naija_PR
Aarẹ Naijiria nigba kan ri, Olusegun Obasanjo ti ke si awọn ọmọ Yoruba lati gbaruku ti aṣa wọn ko ma baa parun.
Obasanjo lo sọ ọrọ naa lasiko to n gbalejo agba ayanbinrin, Olumuyiwa Aralola, ti ọpọ mọ si Ara, niluu Abeokuta.
Baba Iyabo sọ pe o tọ fun awọn ọmọ kaarọ oojiire lati bojuto aṣa wọn ko ma baa di ohun igbagbe.
Eto naa lo waye ni gbagede Legacy Resort, to wa ninu ọgba Olusegun Obasanjo Presidential Library, OOPL, niluu bi Abeokuta
O fi kun pe obinrin naa ti ṣaṣeyọri ninu iṣẹ ti ọpọ ọkunrin ti n gba ogo.
Ninu ọrọ rẹ, o ni "Ara jẹ obinrin to fẹran aṣa, o si n gbe aṣa wa larugẹ, bẹẹ lo tun ja eewọ ohun ti ọpọ eeyan gbagbọ pe o jẹ iṣẹ ọkunrin nikan ṣoṣo.
"Nigba ti mo n dagba, nnkan meji lo wa ti ẹ ko le gbagbọ pe obinrin le ṣe, akọkọ ni pe ẹ ko le ri obirin ko maa kọ ọpẹ, ekeji ni pe ẹ ko le ri obinrin ko maa lu gangan, amọ Ara n lu gangan, o si dantọ ninu rẹ.
"Ṣaaju akoko yii, awọn obi kii gba awọn ọmọ wọn ọkunrin laaye lati maa gba bọọlu, amọ lode oni, awọn obi ti n bẹ awọn ọmọ wọn lati maa gba bọolu.
"Fun emi o, to ba jẹ pe ijo lo mọ ọ jo, jo daadaa, ti o ba si fi iwe pe mi fun ajọyọ, mo maa yọju sibẹ... Ohunkohun ti o ba n ṣe, ri pe o n ṣe daadaa."
Obasanjo tẹsiwaju pe "A ko gbọdọ fi aṣa wa ṣere, wọn ti n fi ọwọ rọ wa sẹyin, wọn ti n fi ọwọ rọ aṣa wa sẹyin, bẹẹ ni ounjẹ wa, aṣọ wa atawọn nnkan mii nipa wa, a ko gbọdọ gba eyii laaye.. Ede Yoruba kii ṣe ede fanakula."
Aarẹ nigba kan ri naa pari ọrọ rẹ pe ọmọlẹyin Kristi loun amọ iyẹn ko tumọ si pe oun yoo gbagbe aṣa ibi oun.
Nigba to n fesi, Ara sọ pe inu oun dun fun ayẹsi ti Obasanjo ṣe fun oun.















