Ìlànà Yorùbá la gbà pẹ̀tù sí Afe Babalola nínú lórí aáwọ̀ tó wà láàrin rẹ̀ àti Dele Farotimi - Ooni Ife

Àkọlé fídíò, Ìlànà Yorùbá la gbà pẹ̀tù sí Afe Babalola nínú lórí aáwọ̀ tó wà láàrin rẹ̀ àti Dele Farotimi - Ooni Ife
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ni irọlẹ ọjọ Aiku, ọjọ kẹrindinlọgbọn osu kinni ọdun 2025, ilu Ado Ekiti gba alejo awọn oriade ati eekanlu nilẹ Yoruba.

Lara awọn oriade naa ni Ooni tilu Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ọjaja Keji ati awọn oriade miran nilẹ Yoruba to kọwọrin pẹlu rẹ.

Ewi tilu Ado Ekiti, Ọba Rufus Adejugbe si lo gba wọn lalejo.

Koko ohun ti wọn ba wa silu naa ni lati sepade awọn akọroyin pẹlu agba amofin Afe Babalola lori aawọ to wa laarin rẹ ati amofin Dele Farotimi.

BBC Yoruba bawọn peju sibi ipade awọn akọroyin naa, ti Ooni si ba wa sọrọ nipa ohun to waye nibẹ.

Ooni tilu Ile Ife

Orúkọ rere ní Afe Babalola ń jà fún, gbogbo wa lá gbọdọ̀ jà fún orúkọ wa - Ooni

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ooni tilu Ile Ife salaye pe awọn agbaagba Yoruba lo kora jọ lati da si aawọ to wa laarin Amofin Afe Babalola ati Dele Farotimi.

Ooni ni agba kii wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ, idi ree ti awọn se gbera lati wa pẹlu si amofin Babalola ninu.

"Ilana ilẹ Kaarọ o jire la lo lati wa pẹtu si baba pe ki wọn fi ọwọ wọnu lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn fi kan Dele Farotimi.

Lootọ orukọ rere ni baba n ja fun, gbogbo wa si la ri ẹkọ kọ ninu isẹlẹ yii pe ka maa daabo bo orukọ rere wa.

Yoruba lo ni ti a ba fi ọwọ ọtun ba ọmọ wi, a fi ti osi fa mọra ni. A ti bẹ baba ni ilana Ọmọluabi, wn si ti gbọ ẹbẹ wa lati jami lori ẹjọ iwa ọdaran naa.

Nibayi tawọn agbaagba ti da si ọrọ naa, igun keji ti ọrọ kan gbọdọ so ewe gbejẹ mọwọ ni."

Àkọlé fídíò, Wo ohun mẹ́jọ tí o le è ṣe tí táńkà epo bá ṣubú, tí ìbúgbàmù iná sì wáyé

N kò bá Dele Farotimi ṣe ẹjọ́ mọ́, kò sí ohun tí mo fẹ́ gbà tó bá lọ sẹ́wọ̀n - Afe Babalola

Ooni Ogunwusi, Afe Babalola ati Ewi Ado Ekiti

Agba Amofin ati Oludasilẹ fasiti nilu Ado Ekiti, Aare Afe Babalola ti kede pe ija ti dopin, ogun si ti tan laarin oun ati amofin ajafẹtọẹni nni, Dele Farotimi.

Bakan naa, Afe Babalola kede pe oun ti jami lori ẹjọ ẹsun iwa ọdaran ti oun pe amofin ajafẹtọẹni naa.

Ikede ipari ija ọhun lo waye nibi ipade awọn akọroyin kan lọjọ Aiku nilu Ado Ekiti nibi ti Ooni tilu Ile Ife, Ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi peju si pẹlu awọn oriade ati agbaagba miran nilẹ Yoruba.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Afe Babalola lo figbe ta laipẹ yii pe Dele Farotimi ta epo si asọ ala oun, to si gbe lọ sile ẹjọ.

Ipade awọn akọroyin

"Mo kọ lati gba kanga epo rọbi, mose atilẹyin fun ofin ajọ EFCC, mo kọ lati gba ipo Minisita ni ẹẹmeji, eeyan kan ko le tẹmbẹlu gbogbo ohun ti mo se laalaa fun"

Nigba to n sọrọ nibi ipade awọn akọroyin naa, Afẹ Babalola ni oun pinnu lati jami lori ẹjọ to pe agbẹjẹro Dele Farotimi nitori bi Ooni Ogunwusi, Ewi tilu Ado-Ekiti, Ọba Rufus Adejugbe ati awọn oriade miran yika Naijiria se da si aawọ naa.

Aare Babalola ni oun ti kọkọ kọ ẹyin sawọn oriade atawọn eeyan jankajankan miran, to da si aawọ naa saaju yika orilẹede yii ati lẹyin odi.

Amọ o ni oun ko gbọdọ tapa sawọn oriade nitori lati igba iwasẹ, asẹ ni ọba maa n pa, ọba kii daba.

"Mo ti kọ lati gba kanga epo rọbi, ti mo si se atilẹyin fun ofin ajọ EFCC, bakan naa, mo kọ lati gba ipo Minisita ni ẹẹmeji, amọ iyalẹnu lo jẹ fun mi pe eeyan kan yoo kan dide lọjọ kan lati tẹmbẹlu gbogbo awọn ohun ti mo se laalaa le lori."

Afe Babalola n sọrọ

Afe Babalola, bi a ba fi ọwọ ọtun ba ọmọ wi nilẹ Yoruba, a maa n fi ọwọ osi fa mọra ni - Ooni

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba toun naa n bawọn akọroyin sọrọ, Ooni tilu Ile Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi, Ọjaja Keji tun rawọ ẹbẹ si Afe Babalola pe ko wo ti gbogbo awọn eekanlu to ti da si aawọ naa, ko si jeburẹ.

Oriade naa wa yonbo Afe Babalola lori ọpọ ipa to n ko si idagbasoke iran Yoruba, orilẹede Naijiria ati awujọ agbaye lapapọ.

"Gbogbo wa pejọ lati jiroro lori isẹlẹ yii pẹlu Afe Babalola, to si bọwọ nla fun wa gẹgẹ bi ọba alaye, to si gba ẹbẹ wa yẹwo.

A le fọwọ gbaya nipa isẹ nla ti Afe Babalola n se ati bo se saayan lati wa orukọ rere fun ara rẹ eyi ti yoo nira fun ẹnikẹni lati ta epo si asọ ala rẹ.

Aare Afe Babalola ti fidi rẹ mulẹ fun gbogbo aye bayi pe oun mọ riri orukọ oun, ti gbogbo aye naa si ti gbọ ọ ni agbọye.

Ọmọ rẹ ni Dele Farotimi, oniruuru ọmọ ni a maa n bi nile aye, gẹgẹ bi agbalagba, tawọn ọmọ wa ba sẹ wa nilẹ Yoruba, ti a ba fi ọwọ ọtun ba wi, a si tun fi ọwọ osi fa a mọra".

Awọn oriade miran to tun peju sibi ipade akọroyin naa ni Ewi ti Ado-Ekiti, Oba Rufus Adejugbe, Olojudo ti Ido-Ekiti, Oba Ilori Faboro, Ogoga ti Ikere-Ekiti, Oba Adejimi Alagbado, ati Oloye tilu Oye-Ekiti, Oba Michael Ademolaju.

Ooni Ogunwusi ati Afe Babalola

Ki lo fa aawọ laarin Afe Babalola ati Dele Farotimi?

Ni bii osu melo kan ni ariwo ta yika Naijiria pe agba amofin Afe Babalola n binu, to si n fapa janu pe amofin miran, to filu Eko se ibujoko, Dele Farotimi, ta ẹrẹ si asọ aala oun.

Afẹ ni ninu iwe kan ti Farotimi kọ, eyo ti pe ni "Nigeria and its Criminal Justice System" lo ti fi ẹsun kan Afe Babalola pe sọ ẹka eto idajọ Naijiria di alajẹbanu ati onijẹkujẹ.

Idi si ree ti Afe Babalola fi wọ Farotimi lọ sile ẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ to wa ninu iwe to gbe sita ati bo se ta epo si asọ aala rẹ.