Bí ìgbẹ́jọ́ Olorì Naomi àti Oriyomi Hamzat ṣe lọ lónìí rèé

Olorì Naomi àti Oriyomi Hamzat
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ile ẹjọ Majistreeti sun igbẹjọ siwaju lori ẹsun ti wọn fi kan Oriyomi Hamzat ati Olori Naomi.

Oriyomi Hamzat, Olori Naomi ati alakoso ile ẹkọ girama 'Islamic Secondary School' fi ara han nile ẹjọ Majistreeti to n bẹ ni agbegbe Iyaganku niluu Ibadan l'owurọ oni.

Igbẹjọ naa da lori ẹsun ti wọn fi kan awọn mẹtẹẹta lẹyin ti awọn ọmọde marundinlogoji ṣe alaisi nibi apejẹ ti Olori Naomi ṣe ni opin ọdun 2024.

Ile ẹjọ Majistreeti Iyaganku ni adajọ ti kọkọ paṣẹ wi pe ki wọn sọ awọn ẹni afẹsunkan mẹtẹẹta naa si ọgba ẹwọn l'ọdun to kọja.

Bakan naa, ileẹjọ ni ki ijọba ipinlẹ Ọyọ gbe ẹjọ naa lọ si ile ẹjọ giga to n bẹ ni agbegbe Ring Road niluu Ibadan, nitori ile ẹjọ Majistreeti ko ni agbara lati gbe idajọ kalẹ lori ọrọ naa.

Oni lo yẹ ki ile ẹjọ Majistreeti Iyaganku beere lọwọ awọn ẹni afẹsunkan naa boya wọn jẹbi tabi wọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn ki o to di pe wọn o fi ẹjọ naa ṣọwọ si ile ẹjọ giga.

Sugbọn awọn agbẹjọro fun Oriyọmi Hamzat bẹ ile ẹjọ naa lati fun wọn ni ọsẹ meloo kan, ki wọn fi yanju awọn igbesẹ ti ile ẹjọ giga fẹ gbe, lẹyin ti wọn gba beeli awọn mẹtẹẹta lọjọ kẹtala oṣu kinni ọdun yii.

Lẹyin atotonu wọn ni Adajọ agba Ọlabisi Ogunkanmi sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹta ọdun yii.

Agbẹjọrọ fun Oriyọmi Hamzat, Dapọ Akinosi ṣe alaye fun awọn oniroyin pe awọn fẹ ki ile ẹjọ giga to n bẹ ni Ring Road ṣe afihan ọna ti wọn fẹ gbe ẹjọ naa gba, ko to di pe ile ẹjọ Majistreeti to n bẹ ni Iyaganku yoo yọwọ nibi ẹjọ naa.