Wo àwọn ìṣẹ̀lẹ́ gbankọgbì tó sọ Oriyomi Hamzat di ààyò ọ̀pọ̀ èèyàn àtàwọn èyí tó kó o sí wàhálà òfin

Oríṣun àwòrán, oriyomi hamzat/ instagram
Njẹ ẹ mọ wi pe kii ṣe igba akọkọ niyi ti gbajugbaja agbohunsafẹfẹ ni ilu Ibadan, Oriyọmi Hamzat yoo maa lọ si ọgba ẹwọn tabi ba ara rẹ ninu wahala kan tabi omiran ti yoo di ilumọọka.
Oriyọmi Hamzat wa lara awọn eeyan mẹta ti wọn niwaju ile ẹjọ bayii lati koju ẹsun to niiṣe pẹlu iku awọn ọmọde marundinlogoji lasiko eto opin ọdun ti wọn gbe kalẹ loṣu kejila ọdun 2024.
Awọn meji yoku ni olori tẹlẹ laafin Oodua ni Ile Ifẹ, Naomi Silẹkunọla ati Fasasi Abdullahi to jẹ ọga agba ileẹkọ girama Islamic High School ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Ko si aniani pe ilumọọka ni Oriyọmi Hamzat paapaa nilu Ibadan atawọn agbegbe to yii ka paapaajulọ fun awọn ipa to ko lawọn iṣẹlẹ kan to kan araalu gbọngbọn nigba kan ri ati awọn miran to kan igbesi aye oun funrarẹ gbọngbọn.
Eyi mu ki ọpọ tilẹ maa fi oju ajafẹtọ ọmọniyan wo o.
Eyi lawọn iṣẹlẹ jankanjankan ti Oriyọmi Hamzat ti lọwọ si eyi to sọ ọ di ilu mọọka lawujọ.
Eto Kọkọrọ Alatẹ

Oríṣun àwòrán, oriyomi Hamzat/instagram
Eto Kọkọrọ alatẹ jẹ eyi to ti gbajumọ laarin awọn olugbọ redio Agidigbo FM eyi ti Oriyọmi Hamzat da silẹ lọdun diẹ sẹyin.
Eto naa jẹ eyi ti wọn fi n gbe ọpọ awọn iṣẹlẹ abẹaṣọ jade eleyi to jẹ ki ọpọlọpọ awọn olugbọ redio naa o maa kan sara si awọn eto iranwọ fun awọn idile ati eniyan ti ọrọ kan lori eto naa.
Lara awọn eyi to gbajumọ julọ lawọn iṣẹlẹ ti wọn ti gbe wa sori eto naa ni ti arabinrin kan to bi ọmọ mẹrin ṣugbọn ti kii ṣe ọkọ rẹ lo ni eyikeyi ninu wọn. Lẹyin ayẹwo gbogbo ti wọn ṣe ni ọkọ arabinrin naa to mọ lori eto ọhun pe oun gan kọ ni baba awọn ọmọ naa.
Eto naa gbalẹ kan nigba naa to si di koko ọrọ ijiroro.
- Àwọn olólùfẹ Oriyomi Hamzat sọ̀rọ̀ láti UK àti Canada
- Ìdí tí Naomi Silekunola, Oriyomi Hamzat kò fí kúrò ní àtìmọ́lé ọgbà ẹ̀wọ̀n Agodi lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun
- Bó ti wù kó rí, Olorì tẹ́lẹ̀, Naomi, Oriyomi Hamzat àtàwọn tó lọ́wọ́ nínú ètò tó ṣekúpa ọmọdé 35 yóò kojú òfin - Makinde
- Mọ̀ nípa ìrìnàjò Olorì Naomi láti ìgbà èwe títí di olùtọrẹ àánù
- Iléẹjọ́ ju Olorí tẹ́lẹ̀, Naomi ati Oriyomi Hamzat sọ́gbá ẹ̀wọ̀n
Iku Timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, timothy adegoke damilare
Iṣẹlẹ iku oloogbe Timothy Adegoke, igbẹjọ ati idajọ rẹ jẹ iṣẹlẹ miran to tun fọnrere orukọ Oriyọmi Hamzat nitori ipa ati bi o ti ṣe n gba iwaju gba ẹyin lasiko iṣẹlẹ naa lati rii daju pe idajọ ododo waye fun oloogbe naa ati ẹbi rẹ.
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, Timothy Adegoke jẹ akẹkọọ eto ẹkọ imọ-kun-imọ, MBA ni fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ University, OAU nilu Ile Ifẹ. Idanwo rẹ lo wa ṣe ni ile ẹkọ fasiti naa to fi lọ wọ si ile igbafẹ kan ni ile Ifẹ ti awọn kan fi ṣekupa a ti wọn si tun lọ gbe oku rẹ bo ni idakọnkọ ki ilẹ to mọ.
Oriyọmi Hamzat fọnrere fun idajọ ododo lori iṣẹlẹ nigba naa titi ti idajọ fi waye nigba naa.
Iku Mohbad
Nigba ti iṣẹlẹ iku gbajugbaja akọrin takasufe, ti ọpọ mọ si Mohbad waye losu kẹsan an ọdun 2023, Oriyọmi Hamzat kun ara awọn ilumọọka to gbe ọrọ naa ru nigba naa lati rii pe iwadii to gbọngbọn waye lori iku rẹ lati mọ boya ẹnikẹni lọwọ ninu iku rẹ ati lati rii daju pe ẹnikẹni ti wọn ba kẹẹfin pe o lọwọ ninu iku rẹ foju wina ofin.
Bi ọpọ awọn ilumọọka ṣe n lewaju iṣẹlẹ naa nilu Eko ni Ọgbẹni Hamzat naa n lewaju rẹ nilu Ibadan.
Lara awọn igbesẹ to gbe nigba naa ni kikede pe wọn ko lo awọn awo orin lati ileeṣẹ agborinsita kan ti ẹnu n kun nigba naa lori iku Mohbad lori afẹfẹ ileeṣẹ redio rẹ,
Muyideen ati ijọ Agbala Gabriel niluu Ibadan

Oríṣun àwòrán, Facebook
Lara awọn iṣẹlẹ to tun mu ki Oriyọmi gbajumọ ni ipa to ko nigba ti ọrọ ede aiyede waye laarin alufaa ijọ Agbala Gabriel nilu Ibadan ati arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Muyideen ẹni ti wọn ṣe iranwọ fun lasiko to fi n rago ni oju popo.
Ede aiyede naa waye eyi ti iroyin kan fi gbode pe alufa ijọ naa ti le arakunrin naa kuro ni ile tawọn eeyan dawo kọ fun arakunrin naa ati iyawo rẹ ni agbala ijọ ọhun.
Oriyọmi ni lati rin irinajo lọ si ijọ naa lati pẹtu si aawọ naa ati lati rọ alufa ijọ naa Pasitọ Gabriel Ademọla Ọlasunbọ ko fọwọ wọnu lori ohunkohun yoowu ti arakunrin naa le ti ṣe
Yatọ si awọn iṣẹlẹ ti o da si, awọn iṣẹlẹ miran wa to jẹ pe Oriyọmi gangan funra rẹ lo wọ gau ninu wọn.
Diẹ lara wọn niyi:
Ẹsun ipaniyan lori iku ọmọdekunrin ẹni ọdun mẹtadinlogun

Oríṣun àwòrán, oriyomi hamzat/ instagram
Ni ọdun 2017 ni awọn agbofinro mu Oriyọmi Hamzat lori ẹsun ipaniyan lẹyin ti wọn ba oku ọmọdekunrin ẹni ọdun mẹtadinlogun kan ni inu ile ajọ ẹlẹyinjuaanu kan to da silẹ.
Ọmọdekunrin naa wa lara awọn to wa labẹ itju ajọ naa nigba naa ki wọn to ri oku rẹ pẹlu ọgbẹ ni ori ati ara rẹ.
Awọn agbofinro sọ pe iṣẹlẹ naa waye lọjọ kọkanlelogun oṣu keje ọdun 2017 ni agbegbe Agugu Ọrẹmeji nilu Ibadan.
Ọrọ naa sọ di ero ẹwọn fun ọpọlọp oṣu ki o to gba ominira.















