Oníṣẹ̀ṣe tó dáná sun Al-Quran di èrò àtìmọ́lé nílùú Ibadan

Oríṣun àwòrán, others/getty images
Balogun Aba Ọdọfin ilẹ Iṣẹyin, to jẹ oludasilẹ ikanni igbohunsafẹfẹ lori ayelujara, 'Ọrọ Yoruba TV' la gbọ wi pe o ti wa ni ahamọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS, niluu Ibadan lori ẹsun wi pe o dana sun Al-Quran.
Alaye ti gbajugbaja Oniṣẹṣe, 'Tani Olohun' fi sita lori ikanni ibanidọrẹ Facebook ni wi pe, ilu Iṣẹyin ni iṣẹlẹ naa ti waye ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin lasiko ti Arakunrin naa n ba Musulumi kan jiyan lori pe Al-Quran le jona tabi ko le jona ti wọn ba dana sun un.
Ariyanjiyan yii la gbọ wi pe o mu ki o sọ ina si Al-Quran kan lati fi idi ọrọ mulẹ wi pe ina ko mọ oju ẹni to daa.
Lẹyin iṣẹlẹ yii ni iroyin fi idi rẹ mulẹ wi pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ bẹrẹ si ni ṣọ arakunrin naa ti ọpọ mọ pẹlu inagijẹ 'Ọrọ Yoruba' kiri ko to di pe wọn ri i mu laarin ọsẹ yii, ti o si wa ni ahamọ wọn niluu Ibadan titi di asiko ti a ko iroyin yii jọ.
Ọkan lara awọn aṣoju ẹgbẹ Oniṣẹṣẹ to ba wa sọrọ labẹ aṣọ fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, pẹlu alaye wi pe ẹsin Islam naa ni afurasi naa n ṣe tẹlẹri ki o to di Oniṣẹṣe.
Ẹni to ba wa sọrọ fi kun ọrọ rẹ wi pe awọn ti gba agbẹjọro ti yoo ba wọn da si ọrọ naa ki wọn le ri arakunrin ọun gba jade ni atimọle.








