Tani Olohun vs Ilorin Alfa: A ṣí wà lẹnu rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà kò tí níyànjú tàn

A ṣi wa lẹnu rẹ ko tii yanju.
Gbolohun ree to jade lẹnu gbajugbaja onisẹse ni, Abdulazeez Adegbọla ti ọpọ mọ si Tani-Ọlọhun, lasiko to yọju si ile ẹjọ Majisireeti Ilorin fun itẹsiwaju igbẹjọ rẹ lori ẹsun ti wọn fí kan an.
Ọjọ Aje, tii ṣe ọjọ kẹjọ, osu kini, ọdun 2024 yi ni igba akọkọ ti eekan onisẹse ọhun yoo yọju si ile ẹjọ lẹyin ipade tubi n nubi to waye laarin ohun ati awọn Alfa Ilọrin lọjọ kọkandinlogun, osu kejila, ọdun 2023.
Nibi ipade naa lo ti tọrọ aforijin lọwọ awọn olupẹjọ rẹ ati gbogbo Musulumi aye pata wi pe ki ija pari patapata.
Olujẹjọ naa, ni oun jẹjọ ni ile ẹjọ mẹrin ọtọọtọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ati sisun Kurani nina ti awọn mẹrin ọtọọtọ pe e.
Awọn olupẹjọ wọnyi si ni: ẹgbẹ Association of Proud Sons and Daughters of Ilọrin (Ogo Ilorin), Alfa Tonile Okutagidi, Sheikh Labeeb Lagbaji ati ẹgbẹ Modrasat Mohammed.

BBC Yoruba ri pe, Tani Ọlọhun ati awọn onisẹse ti wa ni ikalẹ ni ile ẹjọ ti wọn si n reti ki igbẹjọ bẹrẹ sugbon ko ri bẹẹ titi wọn fi tuka.
Tani-Ọlọhun to wa ileẹjọ pẹlu ọkọ jiipu ti wọn fi taa lọrẹ, sọ fun BBC pe, Iroyin to tẹ awon leti ni pe ile ẹjọ ko ni joko loni nitori ayajọ ọdun ofin, (Legal Day) ti yoo waye lọla.
Nigba to n dahun ibeere lori boya wọn yoo wọgile ẹjọ rẹ ni igbakugba ti ile ẹjọ ba joko, o sọ pe, "A o ti le sọ, Ọwọ wọn lọbẹ wa, ọwọ wọn nisu wa, awọn naa lo le sọ, ọwọ wọn ni gbogbo ẹ wa, ka fi gbogbo rẹ sọwọ Eledumare, Eledumare yoo bawa yanju ẹ.
"Sugbọn ohun ti gbogbo aye ro ni wi pe, o ti yanju, a si wa lẹnu ẹ, ko tii yanju o, ki Eledumare bawa yanju ẹ"
BBC kan si agbẹjọro to n duro fun un, Ọgbeni Ademola Banks, o ni gbogbo igbesẹ ti awọn gbe ni pe ki wọn wọgile awọn ẹjọ ti wọn pe onibara nitori awọn ti ṣe gbogbo nnkan ti wọn beere.
O ni lotitọ ni ayajọ ofin (Legal Day) yoo waye lọla ti awọn ile ẹjọ ko ni sisẹ sugbọn sugbọn Tani-Ọlọhun yoo tun yọju si ile ẹjọ keji to ti n jẹjọ lati ma tapa si ofin ti ile ẹjọ gbe kalẹ.
O ni ọjọ tuntun ti awọn mu fun igbẹjọ Majisireeti yii ni ọgbonjọ osu kinni, ọdun 2024.
Tani Ọlọhun fojú ba ílé ẹjọ́ lónìí fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìpàdé àlàáfíà pẹ̀lú àwọn Alfa Ilorin
Loni ni Tani-Ọlọhun yoo mọ odo ti yoo da ọrunla si boya o ti moribọ abi ẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan an si n tẹsiwaju.
Igbẹjọ eekan onisẹse n ni, Abdulazeez Adegbọla tawon eeyan mọ si Tani Ọlọhun tẹsiwaju loni ọjọ kẹjọ, ọjọ Aje oṣu kinni ọdun 2024.
Ile ẹjọ Majisireeti niwaju Adajọ Ibrahim Muhammed ni igbẹjọ ọhun ti n waye.
Eyi ni igba akọkọ ti ile ẹjọ yoo jokoo lori ọrọ rẹ lati igba to ti tọrọ aforiji lọwọ awọn Alfa Ilorin ati gbogbo Musulumi aye pata.
Tẹ o ba gbagbe, Tani-Ọlọhun tọrọ aforiji lọwọ awon olupẹjọ rẹ ni ibi ipade itubi-inubi to waye ni ọjọ kọkandinlogun osu kejila, ọdun 2023.
Gbogbo awon olupẹjọ, agbẹjọro ati molẹbi rẹ to fi mọ awọn Alfa ati awon Onisẹse lo peju sibi ipade alaafia naa lati rii wi pe, o see gẹgẹ bi awọn olupẹjọ ṣe fẹ, ki ija baa lee pari patapata.
Olujẹjọ naa, ni oun jẹjọ ni ile ẹjọ mẹrin ọtọọtọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ati sisun Kurani nina ti awọn mẹrin ọtọọtọ fi kan an.
Awọn olupẹjọ naa ni, ẹgbẹ Association of Proud Sons and Daughters of Ilọrin (Ogo Ilorin), Alfa
Tonile Okutagidi, Sheikh Labeeb Lagbaji ati ẹgbẹ Modrasat Mohammed.
Lotitọọ, ipade alaafia ọjọ naa lọ ni irọwọ rọsẹ, onikaluku si fi ayọ lọ sile sugbon a o tii mọ boya o tẹ awọn olupẹjọ lọrun lati wọgile ẹjọ ti wọn pee.














