Èmi kọ́ ni arákùnrin tó hùwà aláìní-ìtìjú nínú fídíò ìbálòpọ̀ tó wà lórí ayélujára - Ninalowo

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/@IAMNINO_B
Gbajugbaja oṣere tiata Nollywood ni Naijiria Bolanle Ninalowo ti sọ pe oun kọ ni arakunrin tàwọn eeyan n sọrọ nipa rẹ ninu fidio kan to gbode.
Ninalowo ti ọpọ mọ si Makanaki l'awọn eeyan sọ pe o wa ninu fidio yi to ṣafihan arakunrin kan to n hu iwa alufansa ṣugbọn ti oju rẹ ko han níbẹ.
Koda awọn eeyan n fi ogun rẹ gbari pe Ninalowo lo wa ninu fidio naa tori pe arakunrin naa ya ami si ara rẹ.
Amọ ninu fidio to ṣe lati fí takò ọrọ yi loju opo Instagram rẹ, Ninalowo salaye pe kedere lo han pe "emi kọ larakunrin to wa ninu fidio yi!"
O ni "awọn eeyan pe mi nipa arakunrin kan to n da ara rẹ laraya ninu fidio to gbode.Arakunrin ti kii ṣe Bolanle Ninalowo "
O fikun pe " Ki Ọlọrun sanmi lẹsan to ba tọ tabi ko fi iya jẹ mi fún aburu ti mo ba ṣe .
Ẹ gbami! Tatoo ti da wahala silẹ
Arewa oṣere yi sọ pe ọpọlọ ko jọ ikọnkọ tori naa k'awọn eeyan ma fi ojo pe ojo oun ati arakunrin to n gbe nkan ọmọkunrin rẹ jo nínú fidio yii.
"Tattoo lo da wahala silẹ o ! Mo mọ wi pe arakunrin naa niṣu lapa bi temi ṣugbọn mo ṣe apọnle ara mi ju pe ki n ma ṣe iru nkan bayi"
Ninu akọle to fi si ọrọ to so yi, o ni oun ri idi t'awọn eeyan fi n ṣi awọn mu sirawọn tori pe tatoo apa wọn jọ sra wọn sugbọn kii ṣe kankan naa.
O fikun pe awọ awọn mejeeji yatọ ati pe ara wọn ko ri bakan naa
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ta ni Bolanle Ninalowo?
Bolanle Ninalowo ti inagijẹ rẹ a maa jẹ Makanaki jẹ gbajumọ ati oṣere tiata Naijiria.
A maa kopa ninu ere sinima lede Yoruba ati Gẹẹsi to sì ti wa lagbo oṣere lati ọdun 2010.
Ọjọ keje oṣu Kaarun ọdun 1980 ni wọn bi Ninalowo.
Ṣaaju ko to darapọ̀ mọ agbo oṣere o ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi olusiro owo ni ile ifowopamọ kan lorileede America ati ni omiran ni Naijiria.
Oludari sinima lo ba wọle sí agbo sinima tí orúkọ fiimu to kọkọ dari a si máa jẹ Rebirth.
Wọn ti fi ọpọ Ami ẹyẹ da lọla latara ipa to ko ninu ere fiimu.
Ọkan ni amí ẹyẹ AMVCA to gba lọdun 2020.
Ninalowo ati iyawo rẹ pinya laipẹ yi.
Wọn bi ọmọ méjì Ọkùnrin kan ati obinrin kan.














