EFCC bẹ̀rẹ̀ ìwádìí Dangote àti àwọn 51 míràn lórí ẹ̀sùn màgòmágó owó dọ́là

Aworan afihan owo Naira sí Dollar

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ Dangote, ọkan lara awọn agbarijọpọ ileeṣẹ to duro wamu nilẹ Africa ti fi atẹjade sita to fidi ọrọ mulẹ pe ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra kan si ọfisi wọn.

Atẹjade naa to tẹ BBC lọwọ lọjọ Abamẹta sapejuwe bi Efcc ṣe yabo ọfisi wọn gẹgẹ bi ọna ati tabuku orukọ ileeṣẹ naa.

O fi kun pe awọn ti ṣaaju fesi si iwe ti Efcc fi beere awọn iwe to jọ mọ bi wọn ṣe gba owo dọla lọdọ awọn alaṣẹ tii ṣe banki apapọ Naijiria.

Efcc kon ti fesi si ọrọ yi amọ eeyan kan to ni ka forukọ bo ohun lasiri ni ajọ naa sọ fún wa pe ayẹwo iwe owo Dangote yi ni ṣe pẹlu iwadii kan to nii ṣe pẹlu bawọn kan ṣe n gba owo ni ọna aitọ lọdọ banki apapọ Naijiria.

Lẹnu lọọlọ yi Gomina banki apapọ Naijiria tẹlẹ ri Godwin Emefiele n koju ẹsun to jọ mọ lilo ipo rẹ lọna aitọ lati le fi sọ awọn kan di olowo tabua nipa fifun wọn ni owo ilẹ okere lasiko to wa lori oye.

Emefiele tako ẹsun yi ati gbogbo awọn miran ti wọn tori rẹ wọ lọ si iwaju adajọ

Dangote nikan kọ ni ọrọ yi kan

Iṣọwọ bi Efcc ṣe ja wọ ofisi Dangote niluu Eko ti bakan ti wọn si gbegi dina abawọle ileeṣẹ na ni Ikoyi.

Oṣiṣẹ Dangote kan ti ọrọ yi s'oju rẹ sọ fun BBC pe awọn oṣiṣẹ Efcc naa ṣa sọ pe dandan awọn fẹ foju ri Arvind Pathak to jẹ ọga agba ileeṣẹ simẹnti Dangote ti wọn sọ pe ko si lọfisi.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wọn pada mu oṣiṣẹ kan nipa lati si ilẹkun ofisi rẹ.

Atẹjade Dangote tẹsiwaju pe awọn aṣoju ileeṣẹ naa ti ṣaaju ki awọn iwe kan ti Efcc beere lọ si ọdọ wọn.

Amọ, awọn oṣiṣẹ Efcc kọ lati gba iwe yi ti wọn sì ni afi dandan k'awọn ṣe abẹwo si ileeṣẹ Dangote lati wa gba iwe ti wọn beere yi fún arawọn.

Anthony Chiejina to jẹ oludari eto ibanisọrọ ileeṣẹ Dangote fi atẹjade yi s'ọwọ sí BBC eyi to sọ pe " a ri iwe lati ọdọ Efcc lọjọ Kẹfa oṣù Kejìlá 2023 eyi to ni ka salaye nipa gbogbo idunadura to ṣafihan baa ṣe gba owo dọla lọdọ Banki apapọ lati 2014 di akoko yi. A fesi nipa pe a sọ pe a ri iwe naa gba taa si tun beere alaye si lori awọn ẹka ileeṣẹ wa tọrọ kan."

O fikun pe " a tun beere igbalaye asiko si ki a baa le ṣe akojọ awọn iwe ti wọn beere.Amọ wọn ko salaye nkan ti wọn fẹ bẹẹ ni wọn ko dahun nípa ibeere igbalaye asiko sí lati le fi yanju nkan ti wọn beere "

Awọn ti ọrọ yi ko ṣokunkun sí wọn sọ fun BBC pe Gbenga Fapohunda to jẹ ọga ọrọ iṣiro owo ileeṣẹ naa ti ko awọn iwe yi lọ si ọfisi Efcc ki wọn to yabo ibẹ

O ni awọn oṣiṣẹ Efcc pada kuro nibẹ̀ nigba ti wọn rii pe iwe tàwọn wa lọ yi ṣaaju awọn de ọfisi.

Efcc ti ṣaaju kọ iwe si Dangote ati awọn ileeṣẹ mọkanlelaadọta mii tí wọn. Sí láwọn fẹ ti iwe ẹrí bi wọn ṣe gba owo dọla lati nkan bi ọdun mẹwàá seyin ati bi wọn ṣe lọ owo naa

O ti to ọjọ mẹta bayii ti ajọ Efcc ti bẹrẹ si tọ pinpin ọrọ owo dọla ti awọn kan gba lọwọ banki apapọ Naijiria CBN.

Gomina banki naa tẹlẹ Godwin Emefiele ṣẹṣẹ ribi bọ ni ahamọ laipẹ yi ni lẹyin ti adajọ gba ki oniduro gba beeli rẹ.

A ko le sọ boya iwadii yi lohun ṣe pẹlu bi Efcc ṣe n sẹjọ pẹlu Emefiele bẹẹ si ni Efcc kọ darukọ awọn ileeṣẹ mii ti ọrọ yi kan.