Àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn pe Tinubu lẹ́jọ́ lórí ₦400b owó ìrànwọ́ orí epo

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, SERAP ti pe Aare Bola Tinubu lẹjọ lori ọrọ owo iranwọ ori epo bẹntiro.
SERAP ni oun pe ẹjọ naa lẹyin ti Tinubu kọ lati ṣalaye bi ijọba rẹ ṣe na owo ti iye rẹ to irinwo bilọnu naira to jẹ afikun owo epo bẹntiro ti ijọba fi pamọ.
Ẹjọ yii lo n waye lẹyin ti iroyin ni ijọba apapọ fi irinwo biliọnu naira naa pamọ laarin ọsẹ mẹrin pere ti Tinubu gori alefa.
Ninu iwe ipẹjọ naa to ni nọmba FHC/L/CS/1514/2023 ti SERA pe nile ẹjọ giga kan nilu Abuja, o ni ki ile ẹjọ ọhun kan an nipa fun Tinubu ko ṣalaye bi ijọba rẹ ṣe na owo naa.
O tun rọ ile ẹjọ naa lati kan an nipa fun Tinubu lati ṣalaye lẹsẹsẹ bi yoo ṣe na awọn owo iranwo ori epo lọjọ iwaju ati awọn kanṣẹ iṣẹ ti ijọba rẹ yoo maa na owo naa le lori.
Yatọ si eyii, SERAP tun bẹ ile ẹjọ ọhun ko ri daju pe Tinubu ṣalaye awọn ọna ti yoo gbe gba ti owo naa ko fi ni bọ sapo awọn eeyan kan dipo ko wa fun anfani awọn araalu.
O ni “nitori Tinubu lẹtọọ labẹ ofin lati ri daju pe gbogbo owo ti wọn ya sọtọ gẹgẹ bii afikun owo ori epo wa fun anfani awọn ọmọ Naijiria ti oṣi n ta julọ ti iye wọn jẹ 137 miliọnu.”
“Bi ijọba ba ṣe na owo naa yoo ni ipa to pọ lara awọn araalu, wọn si gbọdọ mọ bi jọba ṣe owo ọhun.”
“O ṣeeṣe ki abala awọn eeyan kan ko owo naa sapo ara wọn nikan.”
“Ofin orilẹ-ede Naijiria ti wọn kọ lọdun 1999, ti wọn si ṣe agbeyẹwo rẹ jẹ ko ye wa pe awọn araalu lẹtọ si awọn iroyin kan, paapaa nipa awọn nnkan ti ijọba n ṣe.
SERAP ni ijọba ko gbọdọ ṣe ohunkohun to rọ mọ ọrọ owo naa ni ikọkọ, gbogbo eto naa gbọdọ han si gbangba.
Wayi o, ile ẹjọ naa ko tii kede ọjọ ti igbẹjọ ọhun yoo bẹrẹ.












