Ìjọba Ondo yóò bọ́ ìdílé mílíọ̀nù kan nítorí wàhálà ‘Subsidy’

Gomina Akeredolu

Oríṣun àwòrán, arakunrin rotimi akeredolu

Ijọba ipinlẹ Ondo ti kede pe awọn yoo bọ mọlẹbi miliọnu kan ni ipinlẹ naagẹgẹ bi ara eto iranwọ ti ijọba gbe kalẹ fawọn olugbe ipinlẹ ọun.

Alaga igbimọ to n ṣakoso mimu idẹrun ba ara ilu lori inira ti ọwọn gogo epo bẹntiroolu ko ba wọn ni ipinlẹ naa, Wale Akinteriwa, ni ijọba ipinlẹ Ondo ti ya owo to to biliọnu meje naira sọtọ lati ṣe oniruuru eto ti yoo d’ẹrin p’ẹrẹkẹ awọn olugbe ipinlẹ naa.

Yatọ si ounjẹ ti ijọba yoo pin lati ojule de ojule fun mọlẹbi miliọnu kan, ijọba ipinlẹ Ondo tun ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ fẹyinti pẹlu yoo lanfani si ẹgbẹrun mẹwa naira owo iranwọ to yatọ si owo ifẹyinti ti wọn gba loṣooṣu

Nigba wo leto naa yoo bẹrẹ?

Gbogbo eto yii ni yoo bẹrẹ ni oṣu kẹjọ ọdun 2023.

“Ijba yoo da ọkọ to n ko awọn akẹkọọ lọfẹ pada soju popo, to fi mọ ọkọ oju omi lawọn agbeegbe ori omi, bẹrẹ lati ọjọ ti wọn ba ti pada wọle saa ẹkọ miran ninu oṣu kẹsan ọdun titi di ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila.

Amọṣa, gẹgẹ Akintẹrinwa ṣe sọ, awọn akẹkọọ yoo bẹrẹ si ni san owo taṣọrẹ lori eyi ni oṣu kini ọdun 2024

“Bakan naa ni gbogbo ọkọ bọọsi to wa lawọn ile iṣẹ ijọba jakejado ipinlẹ yoo bẹrẹ si nii ko awọn oṣiṣẹ lọ ibi iṣẹ ati pada sile wọn lọfẹ titi di ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun yi.

“A si tun ti ṣe eto lati ra awọn ọkọ bọọsi tuntun ti yoo ma lo afẹfẹ gaasi lati maa ko awọn oṣiṣẹ bakan naa.”

Bakan naa lo fi kun un pe, “ẹgbẹrun mẹwa naira lati ṣeto kalẹ lati maa pin fun eeyan ẹgbẹrun kan to ku diẹ kaato fun ni ijọba ibilẹ kọọkan ti gbogbo wọn si jẹ ẹgbẹrun mejidinlogun jakejado ipinlẹ yi. Wọn yoo si jẹ anfaani yi fun oṣu mẹta”.