Ẹ̀mí àìrí àti èkúté wo ló yọ ojú àti ahọ́n òkú ọmọ kí ilẹ̀ tó mọ́ ní Ado-Ekiti?
Kayeefi, a ko ri iru eleyi ri, ni ọrọ da fun awọn olugbe adugbo Oke Oniyo, ni agbegbe Ajilosun niluu Adeo-Ekiti, ipinlẹ Ekiti, lẹyin ti iroyin jade pe oju ati ahọn ọdọmọkunrin kan deede di awati lẹyin to ku.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023, ni iroyin jade pe iṣẹlẹ yii waye, eyi to fa awuyewuye.
Awọn ara adugbo to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe ọjọ diẹ ṣaaju asiko naa ni Goodluck ṣe aisan ranpẹ lẹyin to fi ara pa ni papa iṣere bọọlu.
Wọn ni iya rẹ ti kọkọ n tọju ọgbẹ bọọlu naa ninu ile, ko to o di ọjọ kan to ni oun n gbe e lọ si ileewosan.

Ọrọ naa jẹ kayeefi nitori pe ko si ami pe wọn ja ilẹkun yara ti wọn tẹ oku ọmọ naa si - Ọlọpaa
Olugbe agbegbe naa kan, Ọgbẹni Bayo Ilesanmi sọ fun BBC pe oun ti iya ọmọ naa sọ fun ara adugbo ni pe oju ọna ileewosan ni ọmọ naa ti gbẹmi mi ninu kẹkẹ Marwa ti wọn fi n gbe e lọ.
“Wọn ni wọn tẹ oku ọmọ naa sinu yara iya rẹ lorumọju, nitori pe ni nnkan bi aago mẹjọ alẹ lo ku.
“Amọ iyalẹnu lo jẹ fun ara adugbo pe ko si ahọn ati oju ọmọ naa nibẹ mọ nigba ti awọn ẹbi rẹ fẹ ẹ ma a a gbe lọ si ilu wọn fun isinku.”
Ọgbẹni Ilesanmi sọ pe ohun ti awọn ẹbi to sun ti oku ọmọ naa mọju sọ fun ara adugbo ni pe “o ṣeeṣe ko jẹ ekute ile tabi alujọọnu lo yọ awọn ẹya ara ọmọ naa”.
Ọrọ naa jẹ kayeefi nitori pe ko si ami pe wọn ja ilẹkun yara ti wọn tẹ oku ọmọ naa si, bakan naa ni ẹni ti kọkọrọ wa lọwọ rẹ sọ pe ẹnu ọna ni awọn sun si, ti ẹnikẹni ko si gba kọkọrọ ni ọwọ oun.
Ẹkunrẹrẹ iroyin wa ninu fidio to wa loke.
Ọrọ naa ti de ileeṣẹ ọlọpaa bayii, ti iwadii si ti n lọ lati mọ awọn to ṣe iṣẹ ibi naa.
Bi iṣẹlẹ kayeefi naa ṣe bẹrẹ
Inu ibẹrubojo lawọn olugbe agbegbe Ajilosun, niluu Ado Ekiti wa bayii lẹyin ti awọn kọlọrọsi kan yọ oju, ti wọn si tun ge ahọn ọdọkunrin kan lọ lagbegbe naa.
Ohun ti a gbọ ni pe ọdọkunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Goodluck ṣaisan ranpẹ lẹyin to ṣeṣe nibi to ti lọ gba bọọlu.
Amọ ọmọ naa jade laye lẹyin ọjọ diẹ to fara ṣeṣe lori papa bọọlu.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe oju wọn ṣalaye pe awọn mọlebi rẹ gbe oku oloogbe naa sinu yara kan lorumọju ni ni ipalẹmọ fun isinku rẹ, amọ nigba ti yoo fi di ọjọ keji kayeefi ni nnkan ti wọn pada ba ninu yara ti oku rẹ wa.
Alaye lori bi wọn ṣe yọ oju ati ahọn Goodluck
Nigba ti yoo fi di ọjọ keji, awọn kan ti yọ oju rẹ lọ, wọn si tun ge ahọn ati ẹran kuro lara rẹ.
Awọn eeyan adugbo naa ti wọn ko fẹ fi orukọ wọn lede sọ pe ilẹ ti ṣu lasiko ti awọn mọlẹbi rẹ yoo fi gbe oku rẹ wa sile.
Wọn ni iyalẹnu nla lo jẹ fun awọn pe irufẹ nnkan bẹẹ le ṣẹlẹ lagbegbe awọn.
Awọn mii to ba awọn akọroyin sọrọ sọ pe oku ọmọ ọhun nikan lo wa ninu yara ti wọn gbe si lẹyin ti awọn mọlẹbi gba iya rẹ nimọran pe ko ma sun sinu yara kan naa pẹlu oku ọmọ rẹ.
Ta lo yọ oju ati ahọn Goodluck?
Wayi o, awọn eeyan adugbo ti iṣẹlẹ laabi naa ti waye ti sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ẹnikan to sunmọ mọlẹbi oloogbe naa lo ge ẹya ara rẹ lati fi joogun.
Iroyin ni wọn ti fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti leti fun iwadii ni kikun lori ọrọ ọhun.
Ṣugbọn titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ko tii sọ nnkankan nipa iṣẹlẹ ọhun.













