"Ìdí rèé tí mo fi da omi gbígbóná sára olólùfẹ́ mi tẹ́lẹ̀, kó ìfun rẹ síta"

Bankole Oginni

Oríṣun àwòrán, Ondo Police

Ọkunrin akọnimọgba, ẹni ọdun marundinlaadọta, Bankole Oginni ni ọwọ Ọlọpaa ipinlẹ Ondo tí tẹ fun ẹsun pe o ṣekupa ololufẹ rẹ tẹlẹ rí, lẹyin to pe wa si ile rẹ.

Afurasí ọhun ni ọpọ mọ gẹgẹ bii Honourable Kole, ni o ransẹ pe obìnrin naa wa si ile rẹ ni agbegbe Danjuma niluu Akure nipinlẹ Ondo.

Oginni ni igbagbọ wa pe o da omi igbona sara obìnrin naa ko to ṣekupa niluu Ile rẹ, to si ko ìfun rẹ sita.

Ẹsẹ ati apa obìnrin ọhun lo wa ni dìde.

"Ẹru lo ba mi, tí mo fi gbe awọn igbesẹ tí mo gbe"

Bankole Oginni, lasiko to ba Ileeṣẹ Ọlọpaa sọrọ ni ololufẹ oun tẹlẹ naa ni o pe oun fun iranlọwọ, ti oun si ni ko maa bọ wa si ile baba oun.

O ni bi o ṣe de si ile oun, ni oun lọ ra ẹlẹrindodo Coke fi ṣee lalejo.

"Mo ra meji, ko ti mu Coke naa to fi subu. Bi o ṣe subu ni ẹru bẹrẹ si ni ba mi."

Oginni tẹsiwaju pe ẹru lo ba oun ti oun fi gbe awọn igbesẹ kan tí oun gbe,eyi to nii se pẹlu dida omi gbona sì obinrin naa lara, dide lọwọ ati ẹsẹ ati yíyọ ìfun rẹ jade.

"Mo ro pe tí mo ba da omi gbona si lara pẹlu ireti pe yoo jí saye.

"Mo de ọwọ ati ẹsẹ lasiko ti ẹru n ba mi, ti n ko sì mọ nnkan ti mo n se mọ.

Mo ge awọn apa rẹ naa pẹlu erongba pe ma lọ sọ si ibi kan.

"Mo yọ ìfun obinrin naa lati ko si inu apo kan.

"Mo ṣe gbogbo nnkan yii nitori ẹru ba mi ni."

Kí ni ileeṣẹ Ọlọpaa sọ?

Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmi Odunlami fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si ni afurasi ọhun tí wa akata Ọlọpaa lẹyin tawọn ẹbi ọmọbìnrin oloogbe wa fi ọrọ naa to ileeṣẹ Ọlọpaa létí.

Odunlami ni ololufẹ tẹlẹ rí ati Afurasí naa, ni wọn ko gbe ni agbegbe kannaa kí Afurasí to pe wa si ile rẹ, to si ṣekupa

bi wọn ti n fi ọrọ wa lẹnu wo.

"Ọmọdebinrin kan lo mu ọrọ wa si eti ileeṣẹ Ọlọpaa pe ololufẹ ìya oun tẹlẹ lo ransẹ pe iya oun wa si ile rẹ ni Oke Aro niluu Akure.

"O salaye pe iya oun lọ Ile Oginni fun ọpọlọpọ wakati, tí ko si pada wa ati pe foonu rẹ ti wa ni pípa.

O ni oun si ni lati wa iya oun lọ ile naa sugbọn oku iya oun ni oun rí ní ilẹ nile Oginni.

"Ọmọ naa ni wọn de iya oun ni ọwọ ati ẹsẹ, ti wọn si ti ko ìfun iya oun jade.

"A gbera lọ si ibẹ, ti ọwọ si ti tẹ afurasí naa.

Afurasí wa ni akata wa, ti oku sì ti wa ni ile igbokusi."