Tinubu na ológun Niger tó dìtẹ̀ gbàjọba, ní pàṣán ìyà míì

Oríṣun àwòrán, ECOWAS
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu tun ti da bantẹ iya miran lati ro mọ awọn ologun to ditẹ gbajọba ni orilẹede Niger lara.
Lọtẹ yii, Tinubu ti pasẹ fun banki apapọ ilẹ wa, CBN lati se awọn ofin miran, ti yoo fun okun mọ ọrun awọn ologun naa atawọn orilẹede Afirika to n ti wọn lẹyin.
Oluranlọwọ pataki fun aarẹ lori eto iroyin, Ajuri Ngelale, lo sisọ loju ọrọ yii
fawọn akọroyin lasiko to n kopa lori eto kan.
Bakan naa lo salaye pe Bola Tinubu ti ni awọn adari ajọ ECOWAS lo fun ikọ ologun to gbajọba ni Niger ni gbedeke lati da ijọba tiwantiwa pada, kii ṣe orilẹede Naijiria.
Aarẹ Tinubu lo sọ eyi lẹyin ti igbiyanju wọn lati jiroro pẹlu ikọ ologun ni Niger jasi pabọ nitori wọn kọ lati gbalejo ajọ UN, UN ATI Ecowas ọhun.
Ajuri Ngelale tun salaye pe gbedeke ti ajọ Ecowas fun awọn ologun ni Niger ko wa lati orilẹede Naijiria, bio tilẹ jẹpe aarẹ Buhari ni adari ajọ ECOWAS.
O ni lori gbedeke ti Ecowas fun awọn ologun ni Niger lati da ijọba tiwantiwa pada si Niger, kii ṣe pẹlu orilẹede Naijiria, ti kii si ṣe awọn lo fun Niger ni gbedeke amọ ajọ iṣọkan ilẹ Afrika, ECOWAS.
‘’Kii ṣe aṣẹ aarẹ Buhari gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria, amọ aṣẹ Tinubu ni gẹgẹ bi alaga ajọ Ecowas’’
Oluranlọwọ pataki fun aarẹ naa ni o pọn dandan ki awọn araalu mọ iyatọ yii, ki wọn si ye gbe iroyin ofege pe Naijiria lo fẹ lo ikọ ọmọogun lati koju Niger.
O ni awọn iroyin lati abẹle ati lati ile okeere kan ti n fi lede bi ẹni pe ipo aarẹ Tinubu gẹgẹ bi adari orilẹede Naijiria jẹ nkankan naa pẹlu jija alaga ajọ Ecowas.
Ọ̀pọ̀ èèyàn sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Tinubu lórí ìgbésẹ̀ láti kó ológun lọ kojú Niger

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ngelale ni nitori eyi ni aarẹ Tinubu se ni o pọn dandan lati ṣalaye fun awọn araalu iyatọ to wa laarin aarẹ Tinubu gẹgẹ bi aarẹ Naijiria ati adari ajọ Ecowas.
Aarẹ Tinubu fikun un pe ijiroro ti bẹrẹ pẹlu awọn gomina to wa ni awọn ilu to sunmọ Niger ati fifi awọn eto aabo to danmọran sibẹ fun itẹsiwaju alaafia ni awọn agbegbe naa.
Bakan naa ni wọn ji ipade yoo waye ni ọla laarin awọn ajọ yii ati awọn alenulọrọ ki alaafia le jọba ni ẹkun naa.
Aarẹ Tinubu ni ijiroro tabi igbesẹ ajọ ECOWAS ko niise pẹlu ọrọ ẹya, ẹsin tabi awọn ohun miran.
Saaju ni ajọ ECOWAS ti fofin de eto ọrọ aje pẹlu Niger ati awọn to niiṣe pẹlu ijọba ologun to gbajọba nibẹ lọwọ aarẹ ti wọn dibo yan, Mohamed Bazoum.
Bẹẹ si ni wọn fun Niger ni gbedeke ọjọ meje lati da aarẹ Bazoum pada gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria tabi ki wọn koju ikọ ọmọogun ECOWAS.
Amọ ọpọlọpọ awọn eniyan lo ti tako igbesẹ lilo iwa ipa lati koju ikọ ọmọogun ni Niger, pẹlu amọran pe ki wọn gba ijiroro laaye pẹlu ikọ ọmọogun naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu ni ọpọ ọmọ Naijiria ti bu ẹnu atẹlu lori idunkooko lati fi ikọ ologun gba ìjọba pada lọwọ ikọ ologun orilẹede Niger.
Ileeṣẹ iroyin fi idi rẹ mulẹ pe pupọ awọn ọmọ ile ìgbìmọ asofin orilẹede Naijiria tako igbesẹ Aarẹ Tinubu lasiko ti wọn jiroro lori rẹ paapa bo ti lẹ jẹ pe ọmọ ẹgbẹ oselu kana pẹlu Aarẹ Tinubu lo pọ ju laarin wọn.
Eyi waye nitori pupọ awọn asofin yii lo wa lati awọn ipinlẹ to sunmọ orilẹede Niger sugbọn sibẹsibẹ pupọ awọn ọmọ Naijiria lo tako igbesẹ naa.
"Ana lati gba agbara lọwọ ijọba ologun ni Niger lo mu ki Tinubu yọ ina to n wa lati Naijiria silẹ"
Ajọ apapọ orilẹede adulawọ ECOWAS gbe ìgbìmọ kalẹ, ti wọn si fun ikọ ologun to ditẹ gbajọba ni gbedeke ojo méje lati da agbara pada tabi ki wọn gbe na woju ogun ECOWAS.
Asẹ lo wa lati ọwọ Aarẹ Tinubu gẹgẹ bii alaga ajọ ECOWAS, ti orilẹede sì jẹ ọkan gboogi nínu ọmọ ẹgbẹ ECOWAS.
Pẹlu bí ikọ ologun Niger ṣe kọ eti ikun sì gbedeke ọjọ meje ọhun, ECOWAS ko ti kede pe ki ogun bẹrẹ. Eyi lo ti tu ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria lọkan, eyi ti fẹ ki ijọba yanju ọrọ naa lai si rogbodiyan.
Ọpọlọpọ ibeere lo ti jẹyọ boya pe n jẹ ṣe gbedeke ọjọ meje ọhun le waye si imusẹ pẹlu bi o sese koko fun orilẹede Naijiria ati awọn orilẹede miiran lati kọkọ gba àṣẹ ile igbimọ aṣofin ki wọn to gbe awọn ọmọ ologun dide.
Bakan naa bi Aarẹ Tinubu ṣe yọ ina mọnamọna eyi to mu olu ilu Niger, Niamey ati awọn ilu mii wa ni okunkun.
Igbesẹ yii ni ọpọ rí gẹgẹ bii igbiyanju Aarẹ Tinubu lati gba agbara pada lọwọ ijọba ologun orilẹede Niger fun ìjọba alagbada, Aarẹ Mohamed Bazoum lai si ogun.
Gbogbo oju lo ti wa lara Tinubu nitori oun ni ohun rẹ ga ju lati igba ti iditẹ gbajọba naa ti waye
Naijiria ati Niger ni wọn ibasepọ to pọ gan, to si jẹ pe igbigbe ogun tí orilẹede naa le se akoba fun apa ariwa orilẹede Naijiria, nibi ti dunkoko àwọn agbébọn tí wọpọ tẹlẹ.
Ẹgbẹ Musulumi kan ni apa ariwa ti rọ Aarẹ Tinubu lati ma kanju bẹrẹ ogun pẹlu orilẹede Niger.
Bazoum jẹ ọkan lara alabasepọ pẹlu awọn orilẹede amunisin, to si fi aye gba orilẹede France ati US lati ni ibudo ologun lorilẹede naa lati se iranlọwọ gbogun ti awọn musulumi to n gbe ogun ja orilẹede naa.
Olori ologun ni Mali ati Burkina Faso tí bọ sita lati se igbe lẹyin ijọba ologun Niger, ti wọn si ti ransẹ ikilọ si ajọ ECOWAS lati ma ṣe lo ogun.
Gbogbo oju lo ti wa lara Tinubu nitori oun ni ohun rẹ ga ju lati igba ti ditẹgbajọba naa ti waye, to si sọ losu to kọja pe ajọ ECOWAS ko le ko awọn aja jọ.
"A ni lati duro digbi pẹlu ijọba awarawa. Ko si eto isejọba, ominira lia si ijọba awarawa. A ko le tẹwọgba ditẹgbajọba ni apa Afrika yii mọ,"
Tinubu sọ eyi lẹyin to gba ipo alaga ẹgbẹ ECOWAS.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
ECOWAS ati Aarẹ Tinubu ko lo ọna to yẹ tako iṣẹlẹ naa - Ọjọgbọn
Awọn ipinlẹ lorilẹede Naijiria ni Aarẹ Tinubu ko le ran awọn ìkọ ologun lai gba àṣẹ lọwọ ile igbimọ aṣofin agba ati kekere.
A ko ti le sọ boya Tinubu yoo ri atilẹyin gba pẹlu bí ọpọ ṣe tako
Ọjọgbọn Khalifa Dikwa lati fasiti Maiduguri to tun jẹ ọkan lara ọmọ ẹgbẹ awọn agbalagba ni apa ariwa Naijiria ni "ECOWAS ati Aarẹ Tinubu ko lo ọna to yẹ tako iṣẹlẹ naa."
Ninu atẹjade lẹyin ipade ọjọ Satide, Aarẹ Ile Igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio rọ ajọ ECOWAS lati wa ojutu si rogbodiyan Niger ni kiakia.
Aarẹ Tinubu ko da bi Aarẹ tẹlẹ, Muhammadu Buhari to ni imọ nípa ologun bakan naa pẹlu onimọran lori abo, Nuhu Ribadu, ẹni to jẹ Ọlọpaa tẹlẹ ni ko iriri nípa ogun
Àwọn olori ikọ ologun Ajọ ECOWAS sọ ninu atẹjade kan ti wọn gbe jade lọsẹ to kọja pe gbigbe ikọ ologun dide ni yoo jẹ ti awọn yoo se gbẹyin.
Awọn eeyan kan ni Aarẹ Tinubu ma ti n yara lori igbesẹ rẹ, tí wọn si nka sì bí o ṣe yọ owo iranwọ Bentiro lasiko to n ba awọn eeyan sọrọ fun igba akọkọ gẹgẹ bii Aarẹ, eyi to fa ọpọlọpọ awuyewuye
Ajọ Ecowas yoo se ipade nl olu ilu Naijiria, Abuja lati jiroro lori igbesẹ to kú
Bakan naa ni àwọn orilẹede kan ti ṣe ileri lati se atilẹyin fun igbogun dìde ECOWAS, sugbọn yoo nira diẹ lai si Orilẹede Naijiria ni bẹ pẹlu bí ile igbimọ aṣofin ṣe kọ lati buwọlu ipe Aarẹ Tinubu.
Kí ni ìgbésẹ̀ tó kàn fún ECOWAS ní báyìí tí ológun Niger kọ̀ láti gbé ìjọba sílẹ̀?
Awọn ologun to gbajọba ni Niger ti n duro de igbesẹ ti ajọ ECOWAS yoo gbe bayii lẹyin ti gbedeke ọjọ meje ti ECOWAS fun wọn dopin.
ECOWAS sọ ṣaaju pe ti awọn ologun naa ba kọ lati da ijọba pada fun Aarẹ Bazoum, ohun ti yoo gba ni oun yoo fun un.
Awọn onwoye ti n duro de ọrọ lati ọdọ ECOWAS bayii lori ohun to kan lẹyin ti awọn ologun naa kọ jalẹ lati da ijọba pada fun oloṣelu ti awọn araalu dibo yan.
ECOWAS ti maa n fi ologun ṣọwọ si awọn orilẹ-ede ni Afrika ṣaaju asiko yii, ti wọn ba wa ninu iṣoro.
Wayi o, Niger ti gbe oju ofurufu rẹ tipa, o si sọ pe ko si ẹnikẹni ti yoo wọ orilẹ-ede naa bayii tabi jade kuro nibẹ pẹlu ọkọ oju ofurufu.
Ni Naijiria to jẹ alamuleti Niger, awọn eeyan ko fẹ ki ogun naa waye, wọn si ti ke si ijọba lati wa ọna abayọ mii dipo ko lọ kogun ja Niger.
Ijọba Italy ati Germany ti ke si ECOWAS lati fun awọn aditẹgbajọba Niger ni akoko diẹ si lati da ijọba pada fun Aarẹ Bazoum.
Ẹwẹ, jọba ilẹ Gẹẹsi ni opin gbọdọ de ba iditẹgbajọba naa laipẹ.
Minisita fun ọrọ ilẹ adulawọ, Andrew Mitchel sọ fun BBC pe “ko tọ ki awọn kan ṣadede gba ijọba nitori ibọn wa lọwọ wọn boṣe waye ni Niger, idi ree ti opin fi gbọdọ de ba wọn ni kankan.”
“Gbogbo nnkan ti yoo ba gba lo yẹ ka ṣẹ lati pa ina iditẹgbajọba, ka si da ijọba pada ni Niger.”
Minisita fun ọrọ ilẹ okeere ni Italy sọ fun ileeṣẹ iroyin La Stampa pe “Ọna kan ṣoṣo ti a le fi yanju ọrọ yii ni ijiroro ati ifọrọwerọ.”
“Wọn gbọdọ wa ọna abayọ ni, nitori emi o gbagbọ pe ogun nikan ni ọna abayọ si rogbodiyan naa.”
Minisita ọrọ ilẹ okeere Germany naa sọ pe kii ṣe ogun lo maa yanju rogbodiyan ọhun.
Wayi o, iditẹgbajọba meje ni ECOWAS ti bu ẹnu lu ni iwọ oorun Afrika laarin ọdun mẹta sẹyin, awọn kan si gbagbọ pe akoko ti to fun ECOWAS lati gbe igbesẹ akin lori ọrọ naa.
Bi awọn ọmọ ogun Niger ṣe gbegi dina oju ofurufu ṣe ipalara fun awọn arinrinajo ilẹ Europe
Ọkọ ofurufu Air France ti wogile irinajo ofurufu lati Ouagadougou ni Burkina Faso si Bamako ni Mali titi di ọjọ kọkanla, oṣu Kẹjọ.
Ileeṣẹ iroyin AFP jabọ pe France gbe igbesẹ naa lẹyin ti Niger ti oju ofurufu rẹ pa lọjọ Aiku.
Igbesẹ ti Niger gbe yii ti mu ki awọn orilẹ-ede mii bii Libya ati Sudan naa ti oju ofurufu wọn pa.
Ni ida keji, Mali ati Burkina Faso ni oun yoo ran awọn aṣoju si Niger lati ṣatilẹyin fun awọn ologun to gbajọba nibẹ.
ọdun 2020 ni ologun gbajọba ni Mali, nigba ti awọn ologun gbajọba ni Burkina Faso lọdun 2022.














