Ta ni Orire Agbaje, akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Ibadan tí Tinubu yàn bí ọmọ ìgbìmọ̀ olùbádámọ́ràn rẹ̀?

Aarẹ Tinubu n bọ Orire Agbaje lọwọ

Oríṣun àwòrán, @bolatinubu

Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu ti yan akẹkọọ imọ ẹkọ eto ọrọ aje, Orire Agbaje to wa ni ipele 400 ni fasiti ilu Ibadan, lati darapọ mọ igbimọ to n gba aarẹ ni imọran lori eto ọrọ aje ati owo ori.

Olubadamọran fun aarẹ lori ọrọ ẹrọ ayelujara, Olusegun lo fi iroyin naa lede nibi ayẹyẹ iyansipo rẹ ni ile aarẹ ni ilu Abuja.

Olusegun ni aarẹ Tinubu ṣe alapade arabinrin Orire Agbaje to jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ lori imọ eto ọrọ aje.

Loju opo Twitter lo ti ni arabinrin naa lo ti darapọ mọ igbimọ to n risi ọrọ aje ni Naijiria.

Orire Agbaje

Oríṣun àwòrán, Chidera Chidomere/Facebook

Iru eeyan wo ni Orire Agbaje jẹ?

Ninu ifimufinlẹ BBC Yoruba lati mọ siwaju si nipa oloriire omidan yii, a ri pe ọmọ atapata dide ni, to si maa n sere rẹ lori ayelujara.

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn akẹkọọ akẹẹgbẹ rẹ ti slaye lori ayelujara, ni ọjọ melo sẹyin, Orire Agbaje ko mọ pe orire ti sun mọ itori oun.

Eyi si foju han pe orukọ rẹ lo ro o.

Koda, kii se ẹni ti awọn akọroyin n wa kiri nitori se lo maa n fi aworan ara rẹ sori ayelujara gẹgẹ bi awn ọdọ yoku ti n se.

Amọ lojiji lo di ilumọọka, ti ọpọ eeyan n wadi nipa rẹ pe ta ni ọmọbinrin ọdọ yii, to ri ọwọ mu ninu isejọba Bola Ahmed Tinubu?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter/Olusegun

Ohun pataki nipa Orire Agbaje

  • Yoruba ni ọmọ ti yoo ba jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹnu samusamu, Orire jẹ onimọ nipa owo ori, to si doke tente nidi imọ naa.
  • Gẹgẹ bii akẹkọ, ọdọbinrin yii ni aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọ fasiti to wa fun owo ori.
  • Bakan naa lo ti niwe ẹri tẹlẹ nipa eto isiro owo.
  • Orire tun jẹ ẹni to nifẹ pupọ si ilana owo ori gbigba, to si nimọ pupọ nipa rẹ.
  • Ọdọbinrin yii si tun jẹ ọkan lara awọn ẹtahoro ọdọ lorilẹede yii ti wn mu fun eto awọn ọdọ to jẹ ọmọwe lawọn ile ẹkọ giga.
  • Agbaje sọ loju opo ayelujara rẹ pe oun nifẹ si imọ isiro ni oun se gbero lati kọ ẹkọ nipa imọ isiro owo ati owo ori.
Àkọlé fídíò, Kàyèéfì! Ojú àti ahọ́n di àwátì lára okú Goodluck l'óru mọ́jú

‘’Lai si owo ori, ijọba ko lee mu eto igbayegbadun ba ọmọ Naijiria’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter/Olusegun

Lara awọn ohun ti wọn yoo maa jiroro lori ni ọna ati mu idagbasoke ba eto ọrọ aje ni Naijiria.

Bakan naa ni wọn yoo maa jiroro lori ọrọ owo ori ati ọna igbalode ti awọn eniyan yoo maa gba lati san owo ori.

‘’Lai si owo to n wọle ni abẹle ijọba ko lrr ti owo na lati pese awọn ohun igbayegbadun fun awọn araalu’’

‘’Ohun ti igbimọ naa yoo kọkọ ṣe ni lati ṣe agbekalẹ awọn ọna ti ayipada yoo fi ba sisan owo ori ni Naijiria. Awọn agbekalẹ yii yoo waye laarin Ọgbọnjọ.’’

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Bakan naa lo fikun un pe aarẹ Tinubu ni akọsilẹ to dara nipa sisan owo ori ati ọna igbalode lati san owo ori.

O ni aarẹ Tinubu gbe awọn igbeṣẹ yii lasiko to fi ikalẹ si ipinlẹ Eko laarin ogun ọdun.

Arakunrin Taiwo Oyedele to jẹ ọkan lara awọn adari ni ileeṣẹ PriceWaterCoopers ni adari ajọ naa.

Laipẹ yii ni aarẹ Tinubu gbe awọn igbeṣẹ lati ri pe atunṣe ba gbigba owo ori lọwọ awọn araalu.

Aarẹ Tinubu ni awọn ọlọja ati awọn onimọtọ yoo maa san owo ori wọn lọna igbalode, ti wọn yoo ni awọn nọmba idanimọ ti wọn yoo maa fi san owo.