Àkójọpọ̀ ìròyìn òfegè tó gbòde lẹyìn ìdìtẹ̀gbàjọ̀ba ní Niger

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Peter Mwai
- Role, BBC Verify,Nairobi
Lati igba ti awọn ologun ti gba ijọba ni Niger ni itosi Naijiria ni oriṣi iroyin ofege ti n gba ori afẹfẹ.
Eyi si ti n mu ki aya awọn eeyan maa ka soke nipa ibi ti ori n gbe ọrun ree pẹlu orileede naa.
A ṣe agbeyẹwo awọn irufẹ iroyin ayederu bẹẹ tawọ́n eeyan n pin kaakiri loju opo ayelujara.
Ayederu aworan to ṣafihan bawọn ọmọ ogun Wagner ti ṣe balẹ si Niger
Orileede Amẹrika ti sọ pe awọn ikọ ajagunta lati Russia iyẹn Wagner Group ti n ko ifa lara aawọ to n waye ni Niger amọ ko yi si ẹri kankan to ṣafihan pe wọn wa lorileede ọhun.
Lawọn orileede Africa mii bi Mali ati Central African Republic, awọn ikọ ajagunta yi fẹsẹ mulẹ daada.
Amọ fọnran fiio kan to ṣafihan bi ọkọ ofurufu ẹlikọpta kan ṣe n balẹ si papakọ ofurufu Niamey ti gbode kan.
Eyi mu ki awọn eeyan maa gbe iroyin kaakiri pe awọn ajagunta yi ti balẹ biba si Niger.
Baalu to wa ninu fọnran yo farajọ ọkọ ofurufu awọn ologun Russia IL76 amọ fidio yi ti pẹ.
Ẹka iwadii wa,BBC Verify tu iṣu de isalẹ koko lati wa fọnran yi loju opo Youtube.
A ri wi pe fọnran yi kọkọ lu sita ni 2006 ati pe ni olu ilu Sudan, Khartoum ni baalu yi balẹ si ninu fidio ọhun.

Awọn ile to wa ni fọnran yi jọ iru eyi to wa layika papa ofurufu Khartoum.
Fidio mii ti awọn eeyan ti wo ni iye igba to le ni 500,000 loju opo TikTok fi iroyin ofege sita pe oun ni ẹri akọkọ pe awọn ajagunta Wagner wa ni Niger.
Wọn mu fọnran yi lati inu iroyin ileeṣẹ amohunmaworan France 24 loṣu kini ọdun to kọja nibi ti wọn ti n sọrọ nipa awọn ajagunta Wagner to wa ni Mali dipo Niger tawọn ayederu iroyin n sọ.
Wọn ṣe atunto fidio naa lati yọ awọn ẹri to fi han pe Mali ni iṣẹlẹ naa ti waye ati ninu ọrọ ti o wa ninu iroyin ọhun nigba to jade.
Bẹẹ naa ni wọn tun ti ṣe alabapin aworan awọn ajagunta Wagner ni Ukraine ti wọn lo jẹ ẹri pe Wagner ṣetan lati fi ọmọ ogun ranṣẹ si Niger.
Amọ leyi to daju ni pe ileeṣẹ Wagner ko gbe ikede jade loju opo Telegram wọn to tọka si pe o fẹ fi ọmọ ogun kankan ranṣẹ si Niger
Iroyin ayederu nipa tita Uranium nilẹ okere
Iroyin ofege miran to gbode kan ni eleyi to sọ pe kete ti ologun gba ijọba ni wọn ti paṣẹ ki wọn ma ta alumọni ilẹ naa Uranium fun orileede France mọ.
Ilẹ Faranse lo ko Niger lẹru.Titi di isin France ko yọ eyin lọrun orileede ọhun toun ti pe wọn ti gba ominira.

Awọn iroyin bi eleyi to wa loke yi a tun maa kọ iye Uranium ti Niger n ta silẹ okere,Ilẹ Faranse ati ajọ EU amọ ko si ẹri to fihan pe Niger ko ta Uranium si ilẹ Faranse mọ lati igba ti ologun gba ijọba.
A ribi fidi ọrọ mulẹ pe ileeṣẹ to n wa Uranium ni Niger Orano Group sọ pe iṣẹ yi n lọ ni ibudo awọn to wa ni Arlit ati Akokan ati olu ileeṣẹ wọn ni Niamey lẹyin ti ologun gba ijọba
Ologun ko ni ki wọn da ara ilẹ mii to fẹ kuro ni Niger duro
Bayii ti awọn orileede Yuroopu kọọkan ti n gbe ọmọ ilẹ wọn kuro ni Niger, iroyin ti n gbode pe awọn ologun ti paṣẹ pe ki wọn ma jẹ ki wọn jade ni Niger.
Ohun ti iroyin ofege yi sọ ni pe wọn gbe igbesẹ yi kawọn orileede yi baa le ko ọmọ ogun wọn kuro ni Niger.
O fẹẹ jọ wi pe wọn fidi iroyin ofege yi mulẹ lori ipe kan ti ikọ M62 pe ki awọn ilẹ okere ko ọmọ ogun wọn kuro ni Niger.
Ikọ M62 yi lawọn faramọ ijọba ologun tawọn si ṣe atako ilẹ Faranse.
Amọ ṣa ikọ yi ko gbẹnusọ fawọn ologun to gbajọba rara.

Olori awọn ologun to gbajọba Ọgagun Abdourahamane Tchiani sọ lọsẹ to kọja pe ''ko si ifoya fawọn ọmọ orileede France ati pe ''wọn ko ni lati bẹru nkankan''
Lọwọlọwọ bayii awọn ikọ orileede America kan ati ti ilẹ Faranse ṣi wa ni Niger.
Algeria ko ṣe ileri atilẹyin fun ọmọ ogun
Ninu awọn iroyin ofege leleyi to tun sọ pe alamuleti Niger iyẹn Algeria lawọn ṣetan lati ṣe atilẹyin fawọn ologun ti wọn ba fi le doju ija kọ wọn lati ita.
Loju opo Twitter eeyan kan kọ sibẹ pe ''Algeria ko ni kawọ gbera tawọn kan ba kogun ja orileede alabagbe wa''
Onitọhun sọ pe awọn ileeṣẹ iroyin Algeria kan lo gbe ọrọ yi sita.
Ajọ Ecowas ti sọ pe awọn yoo doju ija kọ awọn ologun to gbajọba ti wọn ko ba da aarẹ ti wọn yọ kuro pada sori oye.
Amọ Mali ati Burkina Faso tawọn naa jẹ alamuleti Niger ati ọmọ ẹgbẹ Ecowas yi kannaa ti sọ pe awọn yoo gbe lẹyin Niger to ba dọrọ ogun.
Algeria ti sọ ni tiẹ pe awọn lodi si ki ọrọ di ija ologun amọ awọn ko ni gbe lẹyin awọn ologun to ditẹgbajọba ti ikọ ologun lati ilẹ mii ba doju ija kọ wọn.

Ninu awọn to n gbe iroyin yikaakiri lati ri awọn to sọ pe oju opo akanti kan Intel Kirby lawọn ti ri iroyin yi.
A wo akanti yi loju opo Twitter.
Lootọ lo kọ sibẹ lọgbọn ọjọ oṣu Keje pe ''Algeria ko ni joko tẹtẹrẹ maa woran bawọn kan ṣe n ko ogun ja alabagbe wa.''
Amọ ẹni naa kọ alaye tirẹ lori nkan to ṣeeṣe ko waye ti eleyi ko si jẹ ọrọ latẹnu aṣoju ijọba Algeria kankan.
Jake Horton ati Paul Brown naa pẹlu awọn to ṣe akojọpọ iroyin yi fun BBC.















