What is happening in Russia: Kí lóde tí Ààrẹ Putin ṣe fẹ́ dá ṣẹ̀ríà fún olórí ẹgbẹ̀ Wagner?

Oríṣun àwòrán, AFP
- Author, Paul Kirby
- Role, BBC News
Eyi ni asiko to ṣe pataki ju lati bii oṣu mẹrindinlogun ti orilẹede Russia bẹrẹ ogun pẹlu orilẹede Ukraine, to si n dunkoko mọ isejọba ati agbara Aarẹ Putin pẹlu.
Awọn olori Russia ti fẹsun kan olori ikọ Wagner, Yevgeny Prigozhin pe o fẹ fi ọbẹ ẹyin jẹ ijọba niṣu, to si tun gbe ogun ti awọn ikọ ologun.
Sugbọn Prigozhin, to jẹ ọkan lara eeyan pataki ni oun ko le waju ogun lati gba ijọba ṣugbọn lati gba idajọ ododo.
Kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní Russia?
Fun ọpọlọpọ oṣu bayii ni Prigozhin ti n kopa ribiribi fun ikọ ọmọ ologun Russia lati gbe ogun ti Ukraine, oun ni o gba ọpọlọpọ awọn eeyan sinu ikọ rẹ, Wagner paapa lati ọgba ẹwọn Russia.
O ti pẹ ti ede aiyede ti wa laarin oun ati awọn olori ikọ ologun to n dari ogun naa ṣugbọn ija naa ti bọ si ipele miiran bayii.
Ikọ Wagner ti sọda lati ila oorun si guusu orilẹede Russia ti Rostov-on-Don ati pe wọn ti gba isakoso awọn ikọ ologun ni agbegbe naa.
Aarẹ Putin ni isẹlẹ naa ṣoro ṣugbọn o ṣeleri lati ṣa agbara rẹ lati dabo bo orilẹede Russia.
Se ipinnu ati gba ijọba ree?
'Gbogbo ọrọ pe a fẹ gba ijọba ni ko ni ẹsẹ nilẹ rara ', eyi ni ọrọ Progozhin.
Ṣugbọn o ni nnkan to ṣẹlẹ ni pe oun ko le faramọ bi ikọ ologun ṣe kuna lati pese ohun ija to yẹ fun oun, to si tun na ọwọ abuku si awọn olori ogun meji, Sergei Shoigu ati ẹnikeji rẹ Valery Gerasimov.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ni igba to jẹ pe eyi ko ni nnkan ṣe pẹlu gbigba ijọba pẹlu tipatipa ṣugbọn to jẹ lati mu ikọ ologun Russia walẹ naa lo jẹ mọ titako ofin ati asẹ aarẹ.
Gbogbo agbegbe Moscow lo ti taraji, ti wọn si ti wọgile awọn ayẹyẹ kan to yẹ ko waye.
"A ni ọmọ ologun toto ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn, gbogbo eeyan lo fẹ darapọ mọ wa" iyẹn gan ti to lati dẹruba Aarẹ ati adari ikọ ọmọ ologun.
Iroyin ni o ko awọn ọmọ ologun rẹ kuro ni ibode lọ si Rostovl, ti wọn si ti yika ibudo awọn ọmọ ologun nibi ti ogun ti waye, to si ṣe ikilọ pe ki awọn adari ikọ ologun mejeeji maa salọ.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?
Prigozhin jẹ eeyan timọtimọ Aarẹ Putin, to si lamilaka labẹ rẹ, lakọkọ gẹgẹ olokowo, to si jẹ olori ọmọ ologun.
Awọn ọmọ ologun Wagner rẹ ni ye lo ti padanu ẹmi wọn nibi ogun to waye ni Bakhmut ni ila oorun Russia, to waye fun ọpọlọpọ oṣu lai ri ohun gidi kan dimu. Progozhin bu ẹnu atẹ lu awọn adari ọmọ ologun mejeeji, pẹlu fọnran to gbe sita lori ayelujara, o ṣafihan kudiẹ kudiẹ ikọ ọmọ ologun Russia lorilẹede Ukraine.
Ko sọ pato pe oun binu si Aarẹ ṣugbọn pẹlu bi o ṣe ṣapaejuwe Aarẹ gẹgẹ bi Baba-baba tinu rẹ dun ni ọpọ gba pe o fi ọrọ sọko si Aarẹ Putin.

Oríṣun àwòrán, Concord Press Service
Tani Prigozhin?
O di ọkan lara eeyan pataki to lewaju ogun si orilẹede Ukraine, to si lewaju ikọ ọmọ ologun to jẹ ti aladani, ti orukọ wọn n jẹ Ẹgbẹ Wagner.
Ọmọ ilu kan naa ni oun ati Aarẹ Vladimir Putin ni St Petersburg.
Lẹyin to lo ọpọlọpọ ọdun ni ọgba ẹwọn fun ẹsun ole jija. Progozhin bẹrẹ si ni maa ta ounjẹ ni Petersburg. Karakata bẹre si ni gboro, laarin ọdun diẹ, o ṣi ile ounjẹ to wọn ju lọ ni agbegbe naa.
Lẹyin naa ni wọn kesi Ileeṣẹ rẹ pe ko maa gbe ounjẹ wa si Kremlin, ti ọpọ si bẹrẹ si maa pe e ni 'Alase Putin'.
Lẹyin ọpọlọpọ ọdun to fi ni pe ko si nnkan to jọ pe oun da Wagner silẹ, lọdun to kọja ni iwadi fihan pe o n ja fun ila oorun Ukraine.
Progozhin bẹrẹ si gbe awọn fọnran sori ayelujara ti o ya ni apa ibi kan orilẹede Ukaraine nibi to ti gbe ikọ rẹ Wagner larugẹ.












