Báwo ni ìdìtẹ̀gbàjọ̀ba ní Niger ṣe jẹ́ òdinwọ̀n ìfìdímúlẹ̀ ìṣèjọba tiwantiwa ní Afrika

Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu to jẹ adari ajọ awọn orilẹede lẹkun iwọ oorun Afrika, ECOWAS ti sapejuwe iditẹgbajọba to waye ni Niger gẹgẹ bi idanwo nla fun isejọba tiwantiwa ni ilẹ Afrika.
Lẹyin ti Tinubu gba ipo alaga Ecowas ni ọsẹ mẹta sẹyin ni iditẹgbajọba ologun waye ni Niger.
Niger jẹ orilẹede to n ṣiṣẹ pọ pẹlu Naijiria lati gbogun ti awọn agbesunmọmi ti wọn n fi ẹmi eniyan ṣofo ni iha iwọ oorun ilẹ Afrika.
Saaju akoko yii, Aarẹ Tinubu ti ke gbajare lori iditẹgbajọba to waye ni Burkina Faso, Mali ati Guinea, to si jẹ awọn nkan to sọrọ nipa rẹ nipa rẹ nigba ti wọn burawọle fun un.
Ohun to sọ nigba naa ni pe Ajọ Ecowas gbọdọ ṣiṣẹ papọ lati ri pe awọn orilẹede to wa ninu ajọ naa ko ri ohun to jọ bii iditẹgbajọba mọ, ki wọn si doju ija kọ awọn ikọ agbesunmọmi lagbegbe naa.
Nitorinaa iyalẹnu lo jẹ fun aarẹ Tinubu nigba ti awọn ologun yẹ aga iṣejọba mọ aarẹ orilẹede Niger ni idi; to si pe ipade ajọ naa ni kiakia si Ile Aarẹ ni ilu Abuja.
Ajọ Ecowas gbe igbesẹ lati fi iya jẹ awọn to gbe ijọba Ologun kalẹ ni Niger.
Lara igbesẹ wọn si ni gige okun ina mọnamọna to lọ si ilu Niamey tii ṣe olu ilu orilẹede Niger atawọn ilu miran nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa ni Ecowas fun awọn Ologun ni Niger ni gbedeke lati da ijọba tiwantiwa pada laarin oṣẹ kan, bi ko se bẹẹ awọn yoo fi ijiya to tọ jẹ wọn.
Onimọ nipa eto aabọ ni ileeṣẹ Institute for Security Studies ni ipenija nla ni iditẹgbajọba naa jẹ fun Tinubu gẹgẹ bi adari ajọ Ecowas.
Bakan naa ni orilẹede Niger se pataki si Naijiria nitori igbogunti igbesunmọmi to n waye ni iha ariwa orilẹede Naijiria, nibi ti ikọ Boko Haram ti n ṣọṣẹ.
Awọn ikọ ọmọ ogun ilẹ okeere bii ilẹ Gẹẹsi, Amẹrika ati Faranse pẹlu wa ninu awọn to n koju igbesunmọmi naa, ti wọn si ni awọn ibudo ọwọ Ologun lorilẹede Niger.
Orileede Niger ni ida mẹrin ohun alumọni Uranium lagbaye lọdun 2023 ti jade wa, oun si tun lo wa ni ipo Keje laarin awọn orilẹede to n pese ohun amuṣagbara Uranium-ore.
Bakan naa ni ajọ Ecowas ati awọn alatilẹyin rẹ lagbaye ko ni fẹ ki obitibiti ohun amuṣagbara yii bọ sọwọ awọn kọlọransi lagbaye nibi ti ikọ Boko Haram ti n ṣọṣẹ, ti Russia ati ikọ Ọmọogun ajagunta Wagner ti n lo agbarawọn.
Lẹyin ti iditẹgbajọba waye ni Mali ati Burkina Faso ni awọn eniyan n fi atilẹyin wọn han fun Russia ti awọn ikọ ọmọogun to gbajọba ni Niger si dabi ẹni pe awọn naa fẹ gbe igbesẹ bẹẹ.
Adari orilẹede Chad , Mahamat Deby ti lọ si orilẹede Niger ni Ọjọ Aiku lati lọ parọwa si awọn soja naa lati gbe agbara silẹ, amọ ti awọn ikọ ọmọogun naa si kọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images












