Bode George kọ lẹ́tà sí Tinubu, ó ní kó jáwọ́ nínú ogun tó fẹ́ kó ja Niger

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, @teemax91

Igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ, Oloye Bode George, ti ke si Aarẹ Bola Tinubu pe ko tu ero rẹ pa ko to lọ ko ogun ja orilẹ-ede Niger.

George lo fi ikilọ naa lede ninu lẹta kan to kọ ranṣẹ si Tinubu, nibi to ti sọ pe o san ko ba awọn ologun to ditẹgbajọba nibẹ jiroro ju ko lọ ko ogun ba wọn lọ.

Eekan ẹgbẹ oṣelu PDP naa tun sọ siwaju si pe ti ijọba Naijiria ba ko ogun lọ Niger, igbesẹ naa yoo da eto ọrọ ajẹ iha iwọ oorun ilẹ Afrik ru.

Bode George ni Naijiria ni awọn isọro gbankọgbi to n dojukọ lọwọ, ko tun yẹ ki Tinubu fi ogun Niger kun iṣoro Naijiria.

“Ebi ń pa àwọn ọmọ Naijiria o sì fẹ́ lọ kógun ja Niger”

Bode George sọ ninu lẹta naa pe “O yẹ ka ro o daadaa ki a to ko ogun wọ orilẹ-ede mii o, ko yẹ ki eeyan bẹrẹ nnkan ti ko ni le yọri rẹ.”

“Niger jẹ ọkan lara awọn orilẹ-ede ti ilẹ wọn fẹ julọ lagbaye, o tun jẹ ọkan lara awọn orilẹ-ede ti oṣi ta julọ, ki wa ni ere wa ti a ba lọ kogun ja Niger?”

“Ṣe ki awọn eeyan le maa gboriyin fun wa pe a daabo bo eto ijọba awara ni nigba ti ọpalanba iya si n jẹ awọn eeyan wa nile?”

“Ajagunfẹyinti ni mi, nitori naa mo mọ pe ogun ko rọrun rara.”

“Jọwọ, ma ko Naijiria sinu ogun ti a ko ni mọ opin rẹ.”

Gẹgẹ bii ohun to sọ, Tinubu gbọdọ ṣọra fun awọn orilẹ-ede to n tii pe ko lọ kogun ja Niger.

O ni “ni Naijiria lonii, ko si ounjẹ, ko si agbara lati ra epo bẹntiro, ko si ina, ko si owo, inu inira ni ọpọ araalu wa, ki wa ni ere wa ti a ba lọ soju ogun pẹlu Niger?”

O pari ọrọ rẹ pe lilọ soju ogun naa ko ni ọna abayọ, nitori naa ki Aarẹ Tinubu wa ọna mii lati yanju ọrọ ọhun dipo ogun.