Ṣé lóòótọ́ ni ìyá arúgbó kan yípadà di ológbò nípínlẹ̀ Ondo?

Oríṣun àwòrán, theprecisionng
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrin oṣu keje ọdun yi ni ariwo gbode nilu Akure to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo pe ologbo kan parada di eniyan.
Awọn olugbe agbegbe St. Luke ni Idi Aagba tuntun nilu Akure lo figbe ta pe wọn gbọ pe ologbo kan parada di iya arugbo kan ni afẹmọju ọjọ naa.
Oniruru iroyin lo ti jade nipa iṣẹlẹ yii, ti ọpọ si n beere oniruuru ibeere pẹlu
Bawo ni iroyin nipa iṣẹlẹ yii ṣe bẹrẹ?
Arakunrin kan to pe orukọ ara ni Adetayo to jẹ ontaja ladugbo naa wipe iwaju ile itaja oun ni awọn eeyan ti ri ologbo naa nigba to parada.
Ọkunrin naa ni “ile ni mo wa ti wọn fi waa pe mi pe ki n waa wo ohun to n ṣẹlẹ niwaju ibutaja mi, amọ awọn ara ile iya naa ti gbe wọle ki n to debi”.
Ọkunrin kan ti ko fẹẹ darukọ ara rẹ pẹlu wi pe “mo kọja lagbegbe naa ni nkan bii aago mejila oru. Bi mo ṣe n kọja lọ ni ori i mi n dide.
“Mo waa wo ayika, ti mo si ri iya arugbo kan ninu gọta leyi to mu mi sare kọja. Bi ilẹ ṣe mọ ni mo gbọ wipe iya naa parada di ologbo”.
Ọdọmọbirin kan naa wi pe “mo ri awọn ọdọmọkunrin mẹrin kan nibi ti wọn sọ fun mi pe wọn ri ologbo kan lọna to kọ lati yago fun wọn, leyi to mu ki wọn lẹẹ loko to si parada di iya agba kan”.
‘Ẹnikẹni to ba ri iya agba nigba to di ologbo ko mu ẹri jade’
Bi gbogbo awọn ahesọ̀ yii ṣe n jade ti olukuluku n sọ ohun to wo pe o jẹ otitọ, awọn ayalegbe ile ti iya arugbo naa wa ti tutọ soke foju gbaa.
Wọn ni ẹnikẹni to ba ri iya naa nigba to di ologbo, ko mu ẹri jade faye ri.
Ọkan lara wọn ni “a ba wọn nita ti wọn pariwo pe iya di ologbo amọ iya la ri. Nigba ti wọn fẹẹ maa naa ti wọn si fẹẹ lagi mọọ ni a gbe iya wọle”.
Iya agba naa funra rẹ to jẹ arugbo to si fara jọ ẹni to nilo ọpọ itọju wi pe “ahesọ patapata ni ohun ti wọn n sọ. Ori i mi o ni jẹ ki n di ologbo laye ti mo wa”.
Lẹyin ọpọ awuyewuye ni awọn agbofinro gbe iya naa kuro lagbegbe naa lati le daabo bo ẹmi rẹ.
Alukoro ajọ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya wi fun BBC News Yoruba pe ni tootọ lawọn ọlọpaa gbe iya naa kuro ladugbo naa nitori aabo rẹ ati pe awọn yoo ṣe iwadi ni kikun nipa ohun to ṣẹlẹ gan.
Ìrọ́ ni wọ́n pa mọ́ mọlẹbi wa, ẹbi iya ti wọn fi ẹsun kan sọrọ sita
Awọn mọlẹbi obirin ti wọn fi ẹsun kan pẹlu ti sọrọ lori iṣẹlẹ naa.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita, wọn ni ahesọ rọ lasan ni.
Ayobade John to buwọ lu atẹjade naa ṣalaye pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadi, gbogbo ẹri titi di akoko yii si fi han pe leyi to ti ko idaamu to pọ ba obirin naa ati mọlẹbi rẹ.
“A bẹbẹ pe ki awọn araalu o fi arabirin naa lọrun silẹ, ki wọn si jẹ ki awọn agbofinro o ṣe iṣẹ wọn.”
Ki lo han nipa iṣẹlẹ naa titi di asiko yii?
Akọroyin BBC News Yoruba ninu iwadii rẹ lagbegbe ọhun fihan pe ko si ẹnikan pato to le jade fọwọ sọya pe oun ri iya naa nigba to di ologbo abi bo ṣe parada di eniyan.
Gbogbo awọn to sọrọ lo n wi pe awọn gbọ lẹnu ẹnikan ni amọ ẹni to sọ bẹẹ fun wọn ko si ni itosi mọ.
Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ araalu lo tan ọrọ naa kalẹ lori ẹrọ ayeluja, ko si ẹri kan pato to fidi mulẹ pe ni tootọ ni iya naa di ologbo.












